ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 8:29-31

ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 8:29-31 YCE

Ẹ̀mí sọ fún Filipi pé, “Lọ síbi ọkọ nnì kí o súnmọ́ ọn.” Nígbà tí Filipi sáré, tí ó súnmọ́ ọn, ó gbọ́ tí ó ń ka ìwé wolii Aisaya. Ó bi í pé, “Ǹjẹ́ ohun tí ò ń kà yé ọ?” Ó dáhùn pé, “Ó ṣe lè yé mi láìjẹ́ pé ẹnìkan bá ṣe àlàyé rẹ̀ fún mi?” Ó bá bẹ Filipi pé kí ó gòkè wọ inú ọkọ̀, kí ó jókòó ti òun.