ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 8
8
1Saulu bá wọn lọ́wọ́ sí ikú rẹ̀.
Saulu Ṣe Inúnibíni Sí Ìjọ Kristi
Láti ọjọ́ náà ni inúnibíni ńlá ti bẹ̀rẹ̀ sí ìjọ tí ó wà ní Jerusalẹmu. Gbogbo àwọn onigbagbọ bá túká lọ sí gbogbo agbègbè Judia ati Samaria. Àwọn aposteli nìkan ni kò kúrò ní ìlú. 2Àwọn olùfọkànsìn sin òkú Stefanu, wọ́n sì ṣọ̀fọ̀ pupọ lórí rẹ̀.
3Ṣugbọn Saulu bẹ̀rẹ̀ sí da ìjọ rú. Ó ń wọ ojúlé kiri, ó ń fa tọkunrin tobinrin jáde, lọ sẹ́wọ̀n.#A. Apo 22:4-5, 26:9-11
A Waasu Ìyìn Rere ní Samaria
4Àwọn tí wọ́n túká bá ń lọ káàkiri, wọ́n ń waasu ọ̀rọ̀ náà. 5Filipi lọ sí ìlú Samaria kan, ó waasu fún wọn nípa Kristi. 6Àwọn eniyan ṣù bo Filipi kí wọ́n lè gbọ́ ọ̀rọ̀ tí ó ń sọ, wọ́n sì ń rí iṣẹ́ abàmì tí ó ń ṣe. 7Nítorí àwọn ẹ̀mí burúkú ń lọgun bí wọ́n ti ń jáde kúrò ninu ọpọlọpọ eniyan. Bẹ́ẹ̀ ni a mú ọpọlọpọ àwọn arọ ati àwọn tí wọ́n ní àbùkù ara lára dá. 8Inú àwọn eniyan dùn pupọ ní ìlú náà.#Ais 53:7-8
9Ọkunrin kán wà tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Simoni, tí ó ti máa ń pidán ní ìlú náà. Èyí jẹ́ ìyanu fún àwọn ará Samaria, wọ́n ní ẹni ńlá ni ọkunrin náà. 10Gbogbo eniyan ló kà á kún; ati àwọn eniyan yẹpẹrẹ ati àwọn eniyan pataki wọn. Wọ́n ní, “Eléyìí ní agbára Ọlọrun tí à ń pè ní ‘Agbára ńlá.’ ” 11Tẹ́lẹ̀ rí òun ni àwọn eniyan kà kún, tí idán tí ó ń pa ń yà wọ́n lẹ́nu. 12Ṣugbọn nígbà tí wọ́n gba ìyìn rere tí Filipi waasu nípa ìjọba Ọlọrun ati orúkọ Jesu Kristi gbọ́, tọkunrin tobinrin wọn ṣe ìrìbọmi. 13Simoni náà gbàgbọ́, ó ṣe ìrìbọmi, ni ó bá fara mọ́ Filipi. Nígbà tí ó rí iṣẹ́ abàmì ati iṣẹ́ ìyanu ńlá tí ó ń ṣe, ẹnu yà á.
14Àwọn aposteli tí ó wà ní Jerusalẹmu gbọ́ bí àwọn ará Samaria ti gba ọ̀rọ̀ Ọlọrun. Wọ́n bá rán Peteru ati Johanu sí wọn. 15Nígbà tí wọ́n dé, wọ́n gbadura fún wọn kí wọ́n lè gba Ẹ̀mí Mímọ́, 16nítorí Ẹ̀mí Mímọ́ kò ì tíì bà lé ẹnikẹ́ni ninu wọn. Ìrìbọmi ní orúkọ Oluwa Jesu nìkan ni wọ́n ṣe. 17Lẹ́yìn tí Peteru ati Johanu ti gbé ọwọ́ lé wọn, wọ́n bá gba Ẹ̀mí Mímọ́.
18Nígbà tí Simoni rí i pé ọwọ́ tí àwọn aposteli gbé lé wọn ni ó mú kí wọ́n rí Ẹ̀mí gbà, ó fi owó lọ̀ wọ́n. 19Ó ní, “Ẹ fún mi ní irú àṣẹ yìí kí ẹni tí mo bá gbé ọwọ́ lé, lè gba Ẹ̀mí Mímọ́.”
20Ṣugbọn Peteru sọ fún un pé, “Ìwọ ati owó rẹ yóo ṣègbé! O rò pé o lè fi owó ra ẹ̀bùn Ọlọrun. 21O kò ní ipa tabi ìpín ninu ọ̀rọ̀ yìí, nítorí ọkàn rẹ kò tọ́ níwájú Ọlọrun. 22Nítorí náà, ronupiwada kúrò ninu ohun burúkú yìí, kí o tún bẹ Oluwa kí ó dárí èrò ọkàn rẹ yìí jì ọ́. 23Nítorí mo wòye pé ẹ̀tanú ti gbà ọ́ lọ́kàn, àtipé aiṣododo ti dè ọ́ lẹ́wọ̀n.”
24Simoni dá Peteru lóhùn pé, “Ẹ gbadura sí Oluwa fún mi kí ohunkohun tí ẹ wí má ṣẹlẹ̀ sí mi.”
25Lẹ́yìn tí Peteru ati Johanu ti jẹ́rìí tí wọ́n ti sọ ọ̀rọ̀ Oluwa tán, wọ́n pada sí Jerusalẹmu. Wọ́n ń waasu ìyìn rere ní ọpọlọpọ àwọn abúlé ilẹ̀ Samaria bí wọ́n ti ń pada lọ.
Filipi ati Ìwẹ̀fà Ará Etiopia
26Angẹli Oluwa sọ fún Filipi pé, “Dìde kí o lọ sí apá gúsù, ní ọ̀nà tí ó lọ láti Jerusalẹmu sí Gasa.” (Aṣálẹ̀ ni ọ̀nà yìí gbà lọ.) 27Ni Filipi bá dìde lọ. Ó bá rí ọkunrin ará Etiopia kan. Ó jẹ́ ìwẹ̀fà onípò gíga kan lábẹ́ Kandake, ọbabinrin Etiopia. Òun ni akápò ìjọba. Ó ti lọ ṣe ìsìn ní Jerusalẹmu, 28ó wá ń pada lọ sílé. Ó jókòó ninu ọkọ̀ ẹlẹ́ṣin rẹ̀, ó ń ka ìwé wolii Aisaya. 29Ẹ̀mí sọ fún Filipi pé, “Lọ síbi ọkọ nnì kí o súnmọ́ ọn.” 30Nígbà tí Filipi sáré, tí ó súnmọ́ ọn, ó gbọ́ tí ó ń ka ìwé wolii Aisaya. Ó bi í pé, “Ǹjẹ́ ohun tí ò ń kà yé ọ?”
31Ó dáhùn pé, “Ó ṣe lè yé mi láìjẹ́ pé ẹnìkan bá ṣe àlàyé rẹ̀ fún mi?” Ó bá bẹ Filipi pé kí ó gòkè wọ inú ọkọ̀, kí ó jókòó ti òun. 32Apá ibi tí ó ń kà nìyí:
“Bí aguntan tí a mú lọ sí ilé ìpẹran,
tí à ń fà níwájú àwọn tí ń rẹ́ irun rẹ̀,
kò fọhùn, bẹ́ẹ̀ ni kò ya ẹnu rẹ̀.
33A rẹ̀ ẹ́ sílẹ̀. A kò ṣe ẹ̀tọ́ nípa ọ̀ràn rẹ̀.
Ẹnikẹ́ni kò ní lè sọ nípa ìran rẹ̀.
Nítorí a pa á run kúrò lórí ilẹ̀ alààyè.”
34Ìwẹ̀fà náà sọ fún Filipi pé, “Mo bẹ̀ ọ́, ọ̀rọ̀ ta ni wolii Ọlọrun yìí ń sọ, ọ̀rọ̀ ara rẹ̀ ni tabi ọ̀rọ̀ ẹlòmíràn?” 35Filipi bá tẹnu bọ ọ̀rọ̀. Ó bẹ̀rẹ̀ láti ibi àkọsílẹ̀ yìí, ó waasu ìyìn rere Jesu fún un. 36Bí wọn tí ń lọ lọ́nà, wọ́n dé odò kan. Ìwẹ̀fà náà sọ pé, “Wo omi. Kí ló dé tí o ò fi kúkú rì mí bọmi?” [ 37Filipi sọ fún un pé, “Bí o bá gbàgbọ́ tọkàntọkàn, ẹ̀tọ́ ni.” Ó dáhùn pé, “Mo gbàgbọ́ pé Ọmọ Ọlọrun ni Jesu Kristi.”]
38Ìwẹ̀fà náà bá pàṣẹ pé kí ọkọ̀ dúró. Òun ati Filipi bá sọ̀kalẹ̀, wọ́n lọ sinu odò, Filipi bá rì í bọmi. 39Nígbà tí wọ́n jáde kúrò ninu odò. Ẹ̀mí Oluwa gbé Filipi lọ, ìwẹ̀fà náà kò sì rí i mọ́. Ó bá ń bá ọ̀nà rẹ̀ lọ pẹlu ayọ̀. 40Ní Asotu ni a tún ti rí Filipi. Ó ń waasu ní gbogbo àwọn ìlú tí ó gbà kọjá títí ó fi dé Kesaria.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 8: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010