ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 9
9
Saulu di Onigbagbọ
(A. Apo 22:6-16; 26:12-18)
1Ní gbogbo àkókò yìí, Saulu ń fi ikú dẹ́rùba àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Oluwa. Ó lọ sọ́dọ̀ Olórí Alufaa, 2ó gba ìwé lọ́dọ̀ rẹ̀ láti lọ sí àwọn ilé ìpàdé tí ó wà ní Damasku. Ìwé yìí fún un ní àṣẹ pé bí ó bá rí àwọn tí ń tẹ̀lé ọ̀nà ẹ̀sìn yìí, ìbáà ṣe ọkunrin ìbáà ṣe obinrin, kí ó dè wọ́n, kí ó sì fà wọ́n wá sí Jerusalẹmu.
3Bí ó ti ń lọ lọ́nà, tí ó súnmọ́ Damasku, iná kan mọ́lẹ̀ yí i ká lójijì; 4ó bá ṣubú lulẹ̀. Ó wá gbọ́ ohùn ẹnìkan tí ó bi í pé, “Saulu! Saulu! Kí ló dé tí o fi ń ṣe inúnibíni sí mi?”
5Saulu bèèrè pé, “Ta ni ọ́, Oluwa?”
Ẹni náà bá dáhùn pé, “Èmi ni Jesu, ẹni tí ò ń ṣe inúnibíni sí. 6Dìde nisinsinyii, kí o wọ inú ìlú lọ. A óo sọ ohun tí o níláti ṣe fún ọ.”
7Àwọn ọkunrin tí ó ń bá a rìn dúró. Wọn kò sọ ohunkohun. Wọ́n ń gbọ́ ohùn eniyan, ṣugbọn wọn kò rí ẹnìkankan. 8Saulu bá dìde nílẹ̀, ó la ojú sílẹ̀ ṣugbọn kò ríran. Wọ́n bá fà á lọ́wọ́ lọ sí Damasku. 9Fún ọjọ́ mẹta, kò ríran, kò jẹ, bẹ́ẹ̀ ni kò mu.
10Ọmọ-ẹ̀yìn Jesu kan wà ní Damasku tí ń jẹ́ Anania. Oluwa pè é ní ojú ìran, ó ní, “Anania!”
Anania bá dáhùn pé, “Èmi nìyí, Oluwa.”
11Oluwa bá sọ fún un pé, “Dìde. Lọ sí títì tí à ń pè ní ‘Títì títọ́,’ ní ilé Judasi kí o bèèrè ẹni tí ó ń jẹ́ Saulu, ará Tasu. O óo bá a ní ibi tí ó gbé ń gbadura. 12Ní ojú ìran, ó rí ọkunrin kan tí ń jẹ́ Anania, tí ó wọlé tọ̀ ọ́ lọ, tí ó fi ọwọ́ bà á lójú kí ó lè tún ríran.”
13Anania dáhùn pé, “Oluwa, mo ti gbọ́ ọ̀rọ̀ ọkunrin yìí lẹ́nu ọpọlọpọ eniyan: oríṣìíríṣìí ibi ni ó ti ṣe sí àwọn eniyan mímọ́ rẹ ní Jerusalẹmu. 14Wíwá tí ó tún wá síhìn-ín, ó wá pẹlu àṣẹ láti ọ̀dọ̀ àwọn olórí alufaa láti de gbogbo àwọn tí ó ń pe orúkọ rẹ ni.”
15Oluwa sọ fún un pé, “Lọ sọ́dọ̀ rẹ̀, nítorí mo ti yàn án láti mú orúkọ mi lọ siwaju àwọn orílẹ̀-èdè yòókù ati àwọn ọba wọn ati àwọn ọmọ Israẹli. 16N óo fi oríṣìíríṣìí ìyà tí ó níláti jẹ nítorí orúkọ mi hàn án.”
17Anania bá lọ, ó wọ inú ilé náà, ó fi ọwọ́ kan Saulu. Ó ní, “Saulu arakunrin mi, Oluwa ni ó rán mi sí ọ. Jesu tí ó farahàn ọ́ ní ojú ọ̀nà tí o gbà wá, ni ó rán mi wá, kí o lè tún ríran, kí o sì kún fún Ẹ̀mí Mímọ́.” 18Lẹsẹkẹsẹ nǹkankan bọ́ sílẹ̀ lójú rẹ̀ bí ìpẹ́pẹ́, ó sì tún ríran. Ó dìde, ó bá gba ìrìbọmi.#Tob 11:13-15 19Ó bá jẹun, ara rẹ̀ bá tún mókun. Ó wà pẹlu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu tí ó wà ní Damasku fún ọjọ́ díẹ̀. 20Láì jáfara ó bẹ̀rẹ̀ sí waasu ninu ilé ìpàdé àwọn Juu pé Jesu ni Ọmọ Ọlọrun.
21Ẹnu ya gbogbo àwọn tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀. Wọ́n ní “Ará ibí yìí kọ́ ni ó ń pa àwọn tí ó ń pe orúkọ yìí ní Jerusalẹmu, tí ó tún wá síhìn-ín láti fi ẹ̀wọ̀n dè wọ́n, tí ó fẹ́ fà wọ́n lọ sọ́dọ̀ àwọn olórí alufaa?”
22Ṣugbọn ńṣe ni Saulu túbọ̀ ń lágbára sí i. Àwọn Juu tí ó ń gbé Damasku kò mọ ohun tí wọ́n le wí mọ́, nítorí ó fi ẹ̀rí hàn pé Jesu ni Mesaya.
Saulu Bọ́ lọ́wọ́ Àwọn Juu
23Bí ọjọ́ tí ń gorí ọjọ́ àwọn Juu gbèrò pọ̀ bí wọn yóo ti ṣe pa á.#2 Kọr 11:32-33 24Ṣugbọn Saulu gbọ́ nípa ète wọn. Wọ́n ń ṣọ́ àwọn ẹnu odi ìlú tọ̀sán-tòru kí wọ́n baà lè pa á. 25Ṣugbọn ní alẹ́ ọjọ́ kan, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ gbé e sinu apẹ̀rẹ̀, wọ́n sì sọ̀ ọ́ kalẹ̀ láti orí odi ìlú.
Saulu Pada Dé Jerusalẹmu
26Nígbà tí Saulu dé Jerusalẹmu, ó fẹ́ darapọ̀ mọ́ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu. Ṣugbọn ẹ̀rù rẹ̀ ń bà wọ́n; wọn kò gbàgbọ́ pé ó ti di ọmọ-ẹ̀yìn Jesu. 27Ṣugbọn Banaba mú un lọ sọ́dọ̀ àwọn aposteli, ó ròyìn fún wọn bí ó ti rí Oluwa lọ́nà, bí Oluwa ti bá a sọ̀rọ̀, ati bí ó ti fi ìgboyà waasu lórúkọ Jesu ní Damasku. 28Ó bá ń bá wọn gbé ní Jerusalẹmu, ó ń wọlé, ó ń jáde, ó ń fi ìgboyà waasu lórúkọ Oluwa, 29ó ń bá àwọn Juu tí ó ń sọ èdè Giriki jiyàn. Ṣugbọn wọ́n gbèrò láti pa á. 30Nígbà tí àwọn onigbagbọ mọ̀, wọ́n sìn ín lọ sí Kesaria, wọ́n fi ranṣẹ sí Tasu.
31Gbogbo ìjọ ní Judia, ati Galili, ati Samaria wà ní alaafia, wọ́n sì fìdí múlẹ̀. Wọ́n ń gbé ìgbé-ayé wọn pẹlu ìbẹ̀rù Oluwa, wọ́n sì ń pọ̀ sí i nípa ìrànlọ́wọ́ Ẹ̀mí Mímọ́.
Peteru Mú Iniasi Láradá
32Bí Peteru tí ń lọ káàkiri láti ibìkan dé ibi keji, ó dé ọ̀dọ̀ àwọn eniyan Ọlọrun tí wọn ń gbé ìlú Lida. 33Ó rí ọkunrin kan níbẹ̀ tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Iniasi tí ó ti wà ní ìdùbúlẹ̀ àìsàn fún ọdún mẹjọ; kò lè dá ara gbé nílẹ̀. 34Peteru bá sọ fún un pé, “Iniasi, Jesu Kristi wò ọ́ sàn. Dìde, kà ẹní rẹ.” Lẹsẹkẹsẹ, ó bá dìde. 35Gbogbo àwọn tí ó ń gbé Lida ati Ṣaroni rí i, wọ́n bá yipada, wọ́n di onigbagbọ.
Peteru Jí Dọkasi Dìde
36Ọmọ-ẹ̀yìn kan wà ní Jọpa, tí ó jẹ́ obinrin, orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Tabita, tabi Dọkasi ní èdè Giriki. (Ìtumọ̀ rẹ̀ ni èkùlù.) Obinrin yìí jẹ́ ẹnìkan tíí máa ṣe ọpọlọpọ iṣẹ́ rere, ó sì láàánú pupọ. 37Ní àkókò yìí ó wá ṣàìsàn, ó sì kú. Wọ́n bá wẹ̀ ẹ́, wọ́n tẹ́ ẹ sí yàrá lókè ní ilé pẹ̀tẹ́ẹ̀sì kan. 38Lida kò jìnnà sí Jọpa, nítorí náà àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu ní Jọpa ti gbọ́ pé Peteru wà ní Lida. Wọ́n bá rán ọkunrin meji lọ sibẹ, kí wọ́n lọ bẹ̀ ẹ́ pé kí ó má jáfara kí ó yára wá sọ́dọ̀ wọn. 39Peteru bá gbéra, ó tẹ̀lé wọn. Nígbà tí ó dé Jọpa, ó lọ sí iyàrá lókè. Gbogbo àwọn opó bá yí i ká, wọ́n ń sunkún, wọ́n ń fi àwọn ẹ̀wù ati aṣọ tí Dọkasi máa ń rán fún wọn nígbà tí ó wà láàyè han Peteru. 40Peteru bá ti gbogbo wọn jáde, ó kúnlẹ̀, ó gbadura. Ó bá kọjú sí òkú náà, ó ní, “Tabita, dìde.” Ni Tabita bá lajú, ó rí Peteru, ó bá dìde jókòó. 41Peteru bá fà á lọ́wọ́ dìde. Ó pe àwọn eniyan Ọlọrun ati àwọn opó, ó bá fa Dọkasi lé wọn lọ́wọ́ láàyè. 42Ìròyìn yìí tàn ká gbogbo Jọpa, ọpọlọpọ sì gba Oluwa gbọ́. 43Peteru dúró fún ọjọ́ pupọ ní Jọpa, ní ọ̀dọ̀ Simoni, tí ń ṣe òwò awọ.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 9: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010