KOLOSE 2
2
1Nítorí mo fẹ́ kí ẹ mọ bí mo ti ń ṣe akitiyan tó nítorí yín ati nítorí àwọn tí ó wà ní Laodikia ati nítorí àwọn tí kò mọ̀ mí sójú. 2Ìdí akitiyan mi ni pé kí Ọlọrun lè mu yín ní ọkàn le, kí ó so yín pọ̀ ninu ìfẹ́ ati ọrọ̀ òye tí ó dájú, kí ẹ sì ní ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ àṣírí Ọlọrun, tíí ṣe Kristi fúnrarẹ̀. 3Ninu Kristi ni Ọlọrun fi gbogbo ìṣúra ọgbọ́n ati ìmọ̀ pamọ́ sí.
4Mò ń sọ èyí kí ẹnikẹ́ni má baà fi ọ̀rọ̀ dídùn tàn yín jẹ. 5Nítorí bí n kò tilẹ̀ sí lọ́dọ̀ yín nípa ti ara, sibẹ mo wà pẹlu yín ninu ẹ̀mí. Mo láyọ̀ nígbà tí mo rí ètò tí ó wà láàrin yín ati bí igbagbọ yín ti dúró ninu Kristi.
Ìgbé-Ayé Lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ ninu Kristi
6Nítorí náà, gẹ́gẹ́ bí ẹ ti gba Kristi Jesu bí Oluwa, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ máa gbé ìgbé-ayé yín ni ìrẹ́pọ̀ pẹlu rẹ̀. 7Kí ẹ fẹsẹ̀ múlẹ̀, kí ẹ máa dàgbà ninu rẹ̀, kí ẹ sì jẹ́ kí igbagbọ yín dúró ṣinṣin bí ẹ ti kọ́ láti ṣe, kí ẹ máa dúpẹ́ nígbà gbogbo.
8Ẹ ṣọ́ra kí ẹnikẹ́ni má ṣe fi ọ̀rọ̀ ọgbọ́n ayé ati ìtànjẹ lásán sọ yín di ẹrú gẹ́gẹ́ bí àṣà eniyan, ati ìlànà àwọn ẹ̀mí tí a kò fi ojú rí, tí ó yàtọ̀ sí ètò ti Kristi. 9Nítorí pé ninu Kristi tí ó jẹ́ eniyan ni ohun tí Ọlọrun fúnrarẹ̀ jẹ́, ń gbé lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́. 10Ó sì ti ṣe yín ní pípé ninu rẹ̀. Òun níí ṣe orí fún gbogbo àwọn ẹ̀mí ojú ọ̀run, ìbáà ṣe ìjọba tabi àwọn aláṣẹ.
11Ninu Kristi yìí ni a ti kọ yín nílà, kì í ṣe ilà tí a fi ọwọ́ kọ nípa gígé ẹran-ara kúrò, ṣugbọn ilà ti Kristi; 12nígbà tí a sin yín ninu omi ìrìbọmi, tí ẹ tún jinde nípa igbagbọ pẹlu agbára Ọlọrun tí ó jí Kristi dìde ninu òkú.#Rom 6:4 13Ẹ̀yin tí ẹ ti di òkú nípa ẹ̀ṣẹ̀ yín, tí ẹ jẹ́ aláìkọlà nípa ti ara, ni Ọlọrun ti sọ di alààyè pẹlu Kristi. Ọlọrun ti dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá.#Efe 2:15 14Ó ti pa àkọsílẹ̀ tí ó lòdì sí wa rẹ́, ó mú un kúrò, ó kàn án mọ́ agbelebu. 15Ó gba agbára lọ́wọ́ àwọn ẹ̀mí ojú ọ̀run: ati ìjọba ni, ati àwọn alágbára wọ̀n-ọn-nì; ó bọ́ wọn síhòòhò, ó fi wọ́n ṣẹ̀sín ní gbangba, nígbà tí ó ti ṣẹgun wọn lórí agbelebu.
16Nítorí náà ẹ má gbà fún ẹnikẹ́ni kí ó máa darí yín nípa nǹkan jíjẹ tabi nǹkan mímu, tabi nípa ọ̀rọ̀ àjọ̀dún tabi ti oṣù titun tabi ti Ọjọ́ Ìsinmi.#Rom 14:1-6 17Àwọn nǹkan wọnyi jẹ́ àwòjíìjí ohun tí ó ń bọ̀, ṣugbọn nǹkan ti Kristi ni ó ṣe pataki. 18Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni da yín lẹ́bi, kí ó sọ fun yín pé kí ẹ máa fi ìyà jẹ ara yín, kí ẹ máa sin àwọn angẹli. Irú ẹni bẹ́ẹ̀ ń ṣe ìgbéraga nípa ìran tí ó ti rí, ó ń gbéraga lásán nípa nǹkan ti ara rẹ̀; 19kò dì mọ́ ẹni tíí ṣe orí, tí ó mú kí gbogbo ara, ati iṣan, ati ẹran-ara wà pọ̀, tí ó ń mú un dàgbà bí Ọlọrun ti fẹ́.#Efe 4:16
Ìgbé-Ayé Titun ninu Kristi
20Bí ẹ bá ti kú pẹlu Kristi sí àwọn ìlànà ti ẹ̀mí tí a kò rí, kí ló dé tí ẹ fi tún ń pa oríṣìíríṣìí èèwọ̀ mọ́? 21“Má fọwọ́ kan èyí,” “Má jẹ tọ̀hún,” “Má ṣegbá, má ṣàwo?” 22Gbogbo àwọn nǹkan wọnyi yóo ṣègbé bí ẹ bá ti lò wọ́n tán. Ìlànà ati ẹ̀kọ́ eniyan ni wọ́n. 23Ó lè dàbí ẹni pé ọgbọ́n wà ninu àwọn nǹkan wọnyi fún ìsìn ti òde ara ati fún ìjẹra-ẹni-níyà ati fún ìkóra-ẹni-níjàánu. Ṣugbọn wọn kò ṣe anfaani rárá láti jẹ́ kí eniyan borí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ti ara.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
KOLOSE 2: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010