DANIẸLI 10

10
Ìran tí Daniẹli Rí ní Odò Tigirisi
1Ní ọdún kẹta tí Kirusi jọba ní Pasia, Daniẹli, (tí à ń pè ní Beteṣasari) rí ìran kan. Òtítọ́ ni ìran náà, ó ṣòro láti túmọ̀, ṣugbọn a la ìran náà ati ìtumọ̀ rẹ̀ yé Daniẹli.
2Ní àkókò náà, èmi Daniẹli ń ṣọ̀fọ̀ fún ọ̀sẹ̀ mẹta. 3N kò jẹ oúnjẹ aládùn, n kò jẹran, n kò mu ọtí, n kò sì fi òróró para ní odidi ọ̀sẹ̀ mẹtẹẹta náà.
4Ní ọjọ́ kẹrinlelogun oṣù kinni ọdún tí à ń wí yìí, mo dúró létí odò Tigirisi. 5Bí mo ti gbójú sókè, mo rí ọkunrin kan tí ó wọ aṣọ funfun, ó fi àmùrè wúrà ṣe ìgbànú. 6Ara rẹ̀ ń dán bí òkúta olówó iyebíye tí à ń pè ní bẹrili. Ojú rẹ̀ ń kọ mànà bíi mànàmáná, ẹyinjú rẹ̀ sì ń tàn bí iná. Ọwọ́ ati ẹsẹ̀ rẹ̀ dàbí idẹ dídán, ohùn rẹ̀ sì dàbí ohùn ọpọlọpọ eniyan.#Ifi 1:13-15; 2:18; 19:12
7Èmi nìkan ni mo rí ìran yìí, àwọn tí wọ́n wà pẹlu mi kò rí i, ṣugbọn ẹ̀rù bà wọ́n, wọ́n sì sápamọ́. 8Èmi nìkan ni mo kù tí mo sì rí ìran ńlá yìí. Kò sí agbára kankan fún mi mọ́; ojú mi sì yipada, ó wá rẹ̀ mí dẹẹ. 9Mo bá gbọ́ tí ó sọ̀rọ̀, nígbà tí mo gbọ́ ohùn rẹ̀, mo dojúbolẹ̀, oorun sì gbé mi lọ.
10Ọwọ́ kan bá dì mí mú, ó gbé mi nílẹ̀, mo da ọwọ́ ati orúnkún mi délẹ̀. Mo sì bẹ̀rẹ̀ sí gbọ̀n fún ìbẹ̀rù.
11Ẹni náà pè mí, ó ní, “Daniẹli, ẹni tí Ọlọrun fẹ́ràn! Dìde nàró kí o gbọ́ ohun tí n óo sọ fún ọ, nítorí ìwọ ni a rán mi sí.” Bí ó ti ń bá mi sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, mo dìde nàró, ṣugbọn mo ṣì tún ń gbọ̀n.
12Ó bá dá mi lọ́kàn le, ó ní, “Má bẹ̀rù, Daniẹli, nítorí láti ọjọ́ tí o ti pinnu láti mòye, tí o sì rẹ ara rẹ sílẹ̀ níwájú Ọlọrun rẹ, gbogbo ohun tí ò ń bèèrè ni a ti gbọ́, adura rẹ ni mo sì wá dáhùn. 13Angẹli, aláṣẹ ìjọba Pasia dè mí lọ́nà fún ọjọ́ mọkanlelogun; ṣugbọn Mikaeli, ọ̀kan ninu àwọn olórí aláṣẹ, ni ó wá ràn mí lọ́wọ́; nítorí wọ́n dá mi dúró sọ́dọ̀ aláṣẹ ìjọba Pasia.#Ifi 12:7 14Kí o lè mọ ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ sí àwọn eniyan rẹ lẹ́yìn ọ̀la ni mo ṣe wá, nítorí ìran ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ iwájú ni ìran tí o rí.”
15Nígbà tí ó bá mi sọ̀rọ̀ tán, mo dojúbolẹ̀, mo sì ya odi. 16Ẹnìkan tí ó dàbí eniyan wá, ó fi ọwọ́ kàn mí ní ètè; ẹnu mi bá yà, mo sì sọ̀rọ̀. Mo sọ fún ẹni tí ó dúró tì mí pé, “Olúwa mi, gbogbo ara ni ó wó mi, nítorí ìran tí mo rí, ó sì ti rẹ̀ mí patapata. 17N kò ní agbára kankan mọ́, kò sì sí èémí kankan ninu mi, báwo ni èmi iranṣẹ rẹ ti ṣe lè bá ìwọ oluwa mi sọ̀rọ̀?”
18Ẹni tí ó dàbí eniyan bá tún fi ọwọ́ kàn mí, ó sì fún mi ní okun. 19Ó ní, “Ìwọ tí Ọlọrun fẹ́ràn, má bẹ̀rù, alaafia ni, dá ara yá, kí o sì ṣe ọkàn gírí.”
Nígbà tí ó bá mi sọ̀rọ̀ tán, mo tún lágbára sí i; mo bá dáhùn pé, “olúwa mi, máa sọ ọ̀rọ̀ rẹ lọ, nítorí ìwọ ni ó fún mi lágbára sí i.”
20Ó bi mí pé, “Ǹjẹ́ o mọ ìdí tí mo fi tọ̀ ọ́ wá? Nisinsinyii n óo pada lọ bá aláṣẹ ìjọba Pasia jà, tí mo bá bá a jà tán, aláṣẹ ìjọba Giriki yóo wá. 21Kò sí ẹni tí yóo gbèjà mi ninu nǹkan wọnyi àfi Mikaeli, olùṣọ́ Israẹli; Ṣugbọn n óo sọ ohun tí ó wà ninu Ìwé Òtítọ́ fún ọ.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

DANIẸLI 10: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀