DANIẸLI 2:20-22

DANIẸLI 2:20-22 YCE

Ó ní, “Ẹni ìyìn ni Ọlọrun títí ayérayé, ẹni tí ó ní ọgbọ́n ati agbára. Òun ní ń yí ìgbà ati àkókò pada; òun níí mú ọba kan kúrò lórí ìtẹ́, tíí sì í fi òmíràn jẹ. Òun níí fi ọgbọ́n fún ọlọ́gbọ́n tíí sì í fi ìmọ̀ fún àwọn ọ̀mọ̀ràn. Òun níí fi àṣírí ati ohun ìjìnlẹ̀ hàn; ó mọ ohun tí ó wà ninu òkùnkùn, ìmọ́lẹ̀ sì ń bá a gbé.