DANIẸLI 4
4
Àlá Keji tí Nebukadinesari Lá
1Ọba Babiloni ranṣẹ sí gbogbo àwọn eniyan, ati gbogbo orílẹ̀-èdè ati ẹ̀yà ní gbogbo ayé, pé:
“Kí alaafia wà pẹlu yín! 2Ó tọ́ lójú mi láti fi àmì ati iṣẹ́ ìyanu, tí Ọlọrun tí ó ga jùlọ ṣe fún mi, hàn.
3“Iṣẹ́ rẹ̀ tóbi gan-an!
Iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ sì lágbára lọpọlọpọ!
Títí ayérayé ni ìjọba rẹ̀,
àtìrandíran rẹ̀ ni yóo sì máa jọba.
4“Èmi, Nebukadinesari wà ninu ìdẹ̀ra ní ààfin mi, nǹkan sì ń dára fún mi. 5Mo lá àlá kan tí ó bà mí lẹ́rù. Èrò ọkàn mi ati ìran tí mo rí lórí ibùsùn mi kó ìdààmú bá mi. 6Nítorí náà, mo pàṣẹ pé kí wọ́n kó gbogbo àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n Babiloni wá sọ́dọ̀ mi, kí wọ́n wá túmọ̀ àlá náà fún mi. 7Gbogbo àwọn pidánpidán, ati àwọn aláfọ̀ṣẹ, àwọn ará Kalidea, ati àwọn awòràwọ̀ bá péjọ siwaju mi; mo rọ́ àlá náà fún wọn, ṣugbọn wọn kò lè túmọ̀ rẹ̀ fún mi. 8Lẹ́yìn gbogbo wọn patapata ni Daniẹli dé, tí a sọ ní Beteṣasari, orúkọ oriṣa mi, Daniẹli yìí ní ẹ̀mí Ọlọrun ninu. Mo rọ́ àlá mi fún un, mo ní: 9Beteṣasari, olórí gbogbo àwọn pidánpidán, mo mọ̀ pé ẹ̀mí Ọlọrun mímọ́ wà ninu rẹ, ati pé o mọ gbogbo àṣírí. Gbọ́ àlá mi kí o sì sọ ìtumọ̀ rẹ̀ fún mi.
10“Nígbà tí mo sùn, mo rí igi kan láàrin ayé, lójú ìran, igi náà ga lọpọlọpọ. 11Igi náà bẹ̀rẹ̀ sí tóbi, ó sì lágbára; orí rẹ̀ kan ojú ọ̀run, kò sí ibi tí wọn kò ti lè rí i ní gbogbo ayé. 12Ewé rẹ̀ lẹ́wà, ó so jìnwìnnì, oúnjẹ wà lórí rẹ̀ fún gbogbo eniyan, abẹ́ rẹ̀ ni àwọn ẹranko ń gbé, orí àwọn ẹ̀ka rẹ̀ sì ni àwọn ẹyẹ ń sùn. Èso rẹ̀ ni gbogbo ẹ̀dá alààyè ń jẹ.
13“Ní ojúran, lórí ibùsùn mi, mo rí olùṣọ́ kan, Ẹni Mímọ́, 14ó kígbe sókè pé, ‘Gé igi náà lulẹ̀, gé àwọn ẹ̀ka rẹ̀ kúrò, gbọn gbogbo ewé ati èso rẹ̀ dànù; kí àwọn ẹranko sá kúrò lábẹ́ rẹ̀, kí àwọn ẹyẹ sì fò kúrò lórí ẹ̀ka rẹ̀. 15Ṣugbọn fi kùkùté, ati gbòǹgbò rẹ̀ sílẹ̀ ninu ìdè irin ati ti idẹ ninu pápá.
“ ‘Jẹ́ kí ìrì sẹ̀ sí i lára, kí ó máa bá àwọn ẹranko jẹ koríko; 16kí ọkàn rẹ̀ sì yipada kúrò ní ọkàn eniyan sí ti ẹranko fún ọdún meje. 17Láti ọ̀dọ̀ àwọn olùṣọ́ ni ìdájọ́ yìí ti wá, ìpinnu náà jẹ́ ti àwọn Ẹni Mímọ́; kí gbogbo àwọn ẹ̀dá alààyè lè mọ̀ pé Ẹni Gíga Jùlọ ní àṣẹ lórí ìjọba eniyan, ẹnikẹ́ni tí ó bá sì wù ú níí máa gbé ìjọba lé lọ́wọ́, pàápàá láàrin àwọn ẹni tí ó rẹlẹ̀ jùlọ.’
18“Ìran tí èmi Nebukadinesari rí nìyí. Ìwọ Beteṣasari, sọ ìtumọ̀ rẹ̀, nítorí gbogbo àwọn ọlọ́gbọ́n ìjọba mi kò lè túmọ̀ rẹ̀ fún mi. Ṣugbọn o lè ṣe é, nítorí pé ẹ̀mí Ọlọrun mímọ́ wà ninu rẹ.”
Daniẹli Túmọ̀ Àlá náà
19Ọkàn Daniẹli, tí wọn ń pè ní Beteṣasari, pòrúúruù fún ìgbà díẹ̀, ẹ̀rù sì bà á. Ọba bá sọ fún un pé: “Má jẹ́ kí àlá yìí ati ìtumọ̀ rẹ̀ bà ọ́ lẹ́rù.”
Beteṣasari dáhùn pé, “olúwa mi, kí àlá yìí ṣẹ mọ́ àwọn tí wọ́n kórìíra rẹ lára, kí ìtumọ̀ rẹ̀ sì dà lé àwọn ọ̀tá rẹ lórí. 20Igi tí o rí, tí ó dàgbà, tí ó lágbára, tí orí rẹ̀ sì kan ọ̀run dé ibi pé gbogbo eniyan lè rí i, 21tí ewé rẹ̀ lẹ́wà, tí ó so jìnwìnnì, tí èso rẹ̀ jẹ́ oúnjẹ fún gbogbo ẹ̀dá, tí gbogbo àwọn ẹranko ń gbé abẹ́ rẹ̀, tí àwọn ẹyẹ sì ń sùn lórí àwọn ẹ̀ka rẹ̀.
22“Ìwọ ọba ni igi yìí, ìwọ ni o dàgbà, tí o di igi ńlá, tí o sì lágbára. Òkìkí rẹ kàn dé ọ̀run, ìjọba rẹ sì kárí gbogbo ayé. 23Olùṣọ́, Ẹni Mímọ́ tí ọba rí tí ó sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run, tí ó ń wí pé, ‘Gé igi náà lulẹ̀ kí o sì pa á run, ṣugbọn kí ó ku kùkùté ati gbòǹgbò rẹ̀ ninu ilẹ̀, kí ó wà ninu ìdè irin ati ti idẹ, ninu pápá oko tútù, kí ìrì sẹ̀ sí i lára, kí ó máa bá àwọn ẹranko jẹ káàkiri fún ọdún meje.’
24“Kabiyesi, ìtumọ̀ rẹ̀ nìyí: Àṣẹ tí Ẹni Gíga Jùlọ pa nípa oluwa mi, ọba ni. 25A óo lé ọ jáde kúrò láàrin àwọn eniyan, o óo sì máa bá àwọn ẹranko inú igbó gbé; o óo máa jẹ koríko bíi mààlúù, ìrì yóo sì sẹ̀ sí ọ lára fún ọdún meje, títí tí o óo fi mọ̀ pé Ẹni Gíga Jùlọ ní àṣẹ lórí ìjọba eniyan, ẹni tí ó bá wù ú níí sì í gbé e lé lọ́wọ́. 26Olùṣọ́ náà pàṣẹ pé kí á fi gbòǹgbò igi náà sílẹ̀ ninu ilẹ̀; ìtumọ̀ rẹ̀ ni pé, dájúdájú, o óo tún pada wá jọba, nígbà tí o bá gbà pé Ọlọrun ni ọba gbogbo ayé. 27Nítorí náà, kabiyesi, gba ìmọ̀ràn tí n óo fún ọ yìí; jáwọ́ ninu ẹ̀ṣẹ̀, sì máa ṣe òdodo, jáwọ́ ninu ìwà ìkà, máa ṣàánú fún àwọn tí a ni lára, bóyá èyí lè mú kí àkókò alaafia rẹ gùn sí i.”#Tob 12:9; Sir 3:30
28Gbogbo nǹkan wọnyi sì ṣẹ mọ́ Nebukadinesari ọba lára. 29Ní ìparí oṣù kejila, bí ó ti ń rìn lórí òrùlé ààfin Babiloni, 30ó ní, “Ẹ wo bí Babiloni ti tóbi tó, ìlú tí mo fi ipá ati agbára mi kọ́, tí mo sọ di olú-ìlú fún ògo ati ọlá ńlá mi.”
31Kí ó tó wí bẹ́ẹ̀ tán, ẹnìkan fọhùn láti ọ̀run, ó ní, “Nebukadinesari ọba, gbọ́ ohun tí a ti pinnu nípa rẹ: a ti gba ìjọba kúrò lọ́wọ́ rẹ, 32a óo lé ọ kúrò láàrin àwọn eniyan, o óo máa bá àwọn ẹranko gbé, o óo sì máa jẹ koríko bíi mààlúù fún ọdún meje, títí tí o óo fi mọ̀ pé, Ẹni Gíga Jùlọ ní àṣẹ lórí ìjọba eniyan, ati pé ẹni tí ó bá wù ú ní í máa gbé e lé lọ́wọ́.”
33Lẹsẹkẹsẹ ni ọ̀rọ̀ náà ṣẹ mọ́ Nebukadinesari lára. Wọ́n lé e kúrò láàrin àwọn eniyan, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí jẹ koríko bíi mààlúù. Ìrì sẹ̀ sí i lára títí tí irun orí rẹ̀ fi gùn bí ìyẹ́ idì, èékánná rẹ̀ sì dàbí ti ẹyẹ.
Nebukadinesari Yin Ọlọrun Lógo
34Nebukadinesari ní, “Lẹ́yìn ọdún meje náà, èmi, Nebukadinesari, gbé ojú sí òkè ọ̀run, iyè mi pada bọ̀ sípò. Mo yin Ẹni Gíga Jùlọ, mo fi ọlá ati ògo fún Ẹni Ayérayé.#Sir 18:1
“Ìjọba ayérayé ni ìjọba rẹ̀
láti ìrandíran ni ìjọba rẹ̀,
àní, láti ìrandíran ni ìjọba rẹ̀.
35Gbogbo aráyé kò jámọ́ nǹkankan lójú rẹ̀;
a sì máa ṣe bí ó ti wù ú láàrin àwọn aráyé
ati láàrin àwọn ogun ọ̀run.
Kò sí ẹni tí ó lè ká a lọ́wọ́ kò,
tabi tí ó lè yẹ̀ ẹ́ lọ́wọ́ wò.
36“Ní àkókò gan-an tí iyè mi pada bọ̀ sípò, ògo, ọlá, ati iyì ìjọba mi náà sì tún pada sọ́dọ̀ mi. Àwọn ìgbìmọ̀ ati àwọn ìjòyè mi wá mi kàn, wọ́n gbà mí tọwọ́ tẹsẹ̀, ìjọba mi tún fi ìdí múlẹ̀, mo sì níyì ju ti àtẹ̀yìnwá lọ ní gbogbo ọ̀nà.
37“Ẹ gbọ́, èmi Nebukadinesari, fi ìyìn, ògo, ati ọlá fún ọba ọ̀run. Nítorí pé gbogbo iṣẹ́ rẹ̀ pé, ọ̀nà rẹ̀ tọ́, ó sì lè rẹ àwọn agbéraga sílẹ̀.”
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
DANIẸLI 4: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010