DANIẸLI 6
6
Daniẹli ninu Ihò Kinniun
1Dariusi ṣètò láti yan ọgọfa (120) gomina láti ṣe àkóso ìjọba rẹ̀. 2Ó yan àwọn mẹta láti máa ṣe àbojútó gbogbo wọn, Daniẹli sì jẹ́ ọ̀kan ninu wọn. Àwọn mẹta wọnyi ni àwọn ọgọfa (120) gomina náà yóo máa jábọ̀ fún. 3Ṣugbọn Daniẹli tún ta gbogbo àwọn alámòójútó ati gomina náà yọ nítorí ẹ̀mí tí kò lẹ́gbẹ́ tí ó wà ninu rẹ̀. Ọba sì ń gbèrò láti fi gbogbo ọ̀rọ̀ ìjọba lé e lọ́wọ́. 4Nítorí náà, àwọn alabojuto ati àwọn gomina wọnyi ń wá ẹ̀sùn sí Daniẹli lẹ́sẹ̀ nípa ọ̀rọ̀ ìjọba, ṣugbọn wọn kò rí ẹ̀sùn kankan tí wọ́n lè kà sí i lẹ́sẹ̀. Wọn kò ká ohunkohun mọ́ ọn lọ́wọ́ nítorí olóòótọ́ eniyan ni. Wọn kò bá àṣìṣe kankan lọ́wọ́ rẹ̀. 5Wọ́n sọ fún ara wọn pé, “A kò ní rí ẹ̀sùn kà sí Daniẹli lẹ́sẹ̀, àfi ohun tí ó bá jẹmọ́ òfin Ọlọrun rẹ̀.”
6Nítorí náà, àwọn alabojuto ati àwọn gomina gbìmọ̀ pọ̀, wọ́n kó ara wọn jọ sọ́dọ̀ ọba, wọ́n wí fún un pé “Dariusi ọba, kí ọba pẹ́, 7gbogbo àwọn alabojuto, àwọn olórí, àwọn ìgbìmọ̀, ati àwọn gomina kó ara wọn jọ, wọ́n sì fi ohùn ṣọ̀kan pé kí ọba ṣe òfin kan pé, ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ bèèrè ohunkohun lọ́wọ́ oriṣa kankan tabi eniyan kankan fún ọgbọ̀n ọjọ́, bíkòṣe lọ́wọ́ òun ọba. Ẹni tí ó bá ṣe bẹ́ẹ̀, kabiyesi, kí wọ́n jù ú sinu ihò kinniun. 8Nisinsinyii, kabiyesi, ẹ fi ọwọ́ sí òfin yìí, kí ó lè fi ìdí múlẹ̀, gẹ́gẹ́ bí òfin Mede ati Pasia tí kò gbọdọ̀ yipada.” 9Nítorí náà, Dariusi ọba fi ọwọ́ sí òfin náà, ó sì fi òǹtẹ̀ tẹ̀ ẹ́. 10Nígbà tí Daniẹli gbọ́ pé wọ́n ti fi ọwọ́ sí òfin náà, ó lọ sí ilé rẹ̀, ó wọ yàrá òkè lọ, ó ṣí fèrèsé ilé rẹ̀ sílẹ̀, sí apá Jerusalẹmu. Ó kúnlẹ̀, ó ń gbadura, ó sì ń yin Ọlọrun, nígbà mẹta lojoojumọ.
11Àwọn ọkunrin wọnyi bá kó ara wọn jọ. Wọ́n wá wo Daniẹli níbi tí ó ti ń gbadura, tí ó sì ń bẹ̀bẹ̀ níwájú Ọlọrun rẹ̀. 12Wọ́n wá siwaju ọba, wọ́n sọ nípa àṣẹ tí ó pa pé ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ bèèrè ohunkohun lọ́wọ́ oriṣa kankan tabi eniyan kankan fún ọgbọ̀n ọjọ́, bíkòṣe lọ́wọ́ rẹ̀, ati pé ẹnikẹ́ni tí ó bá rú òfin yìí, a óo jù ú sinu ihò kinniun.
Ọba dáhùn, ó ní: “Dájúdájú, òfin Mede ati Pasia ni, tí a kò lè yipada.”
13Wọ́n bá sọ fún ọba pé, “Daniẹli, ọ̀kan ninu àwọn ìgbèkùn Juda kò kà ọ́ sí, kò sì pa òfin rẹ mọ́. Ṣugbọn ìgbà mẹta lóòjọ́ níí máa gbadura.”
14Nígbà tí ọba gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, ọkàn rẹ̀ dàrú lọpọlọpọ, ó sa gbogbo ipá rẹ̀ títí ilẹ̀ fi ṣú láti gba Daniẹli sílẹ̀. 15Àwọn ọkunrin wọnyi gbìmọ̀, wọ́n sọ fún ọba pé, “Kabiyesi, o mọ̀ pé òfin Mede ati ti Pasia ni pé òfin tí ọba bá ṣe kò gbọdọ̀ yipada.”
16Ọba bá pàṣẹ pé kí wọ́n lọ mú Daniẹli, kí wọ́n sì jù ú sinu ihò kinniun. Ṣugbọn ó sọ fún Daniẹli pé, “Ọlọrun rẹ tí ò ń sìn láìsinmi yóo gbà ọ́.”#Bẹl 31-42 17Wọ́n yí òkúta dí ẹnu ihò kinniun náà. Ọba ati àwọn ìjòyè rẹ̀ sì fi òǹtẹ̀ òrùka wọn tẹ ọ̀dà tí wọ́n yọ́ lé e, kí ẹnikẹ́ni má lè gba Daniẹli sílẹ̀. 18Ọba bá lọ sí ààfin rẹ̀, ó fi gbogbo òru náà gbààwẹ̀. Kò jẹ́ kí àwọn eléré ṣe eré níwájú rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò sì lè sùn.
19Bí ilẹ̀ ti mọ́, ọba dìde, ó sáré lọ sí ibi ihò kinniun náà. 20Nígbà tí ó dé ẹ̀bá ibẹ̀, ó kígbe pẹlu ohùn arò, ó ní, “Daniẹli, iranṣẹ Ọlọrun Alààyè, ǹjẹ́ Ọlọrun tí ò ń sìn láìsinmi gbà ọ́ lọ́wọ́ àwọn kinniun?”
21Daniẹli dáhùn pé, “Kabiyesi, kí ọba pẹ́, 22Ọlọrun mi ti rán angẹli rẹ̀, ó ti dí àwọn kinniun lẹ́nu, wọn kò sì pa mí lára. Nítorí pé n kò jẹ̀bi níwájú rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni n kò sì ṣe nǹkan burúkú sí ìwọ ọba.”#Tob 4:17; 12:14-15
23Inú ọba dùn pupọ, ó sì pàṣẹ pé kí wọ́n yọ Daniẹli jáde. Wọ́n bá yọ Daniẹli jáde kúrò ninu ihò kinniun, àwọn kinniun kò sì pa á lára rárá, nítorí pé ó gbẹ́kẹ̀lé Ọlọrun rẹ̀. 24Ọba bá pàṣẹ pé kí wọ́n lọ mú gbogbo àwọn tí wọ́n fi ẹ̀sùn kan Daniẹli, ati àwọn ọmọ wọn, ati àwọn aya wọn, wọ́n bá dà wọ́n sinu ihò kinniun. Kí wọn tó dé ìsàlẹ̀, àwọn kinniun ti bò wọ́n mọ́lẹ̀, wọ́n sì fọ́ egungun wọn túútúú.
25Dariusi ọba bá kọ ìwé sí gbogbo eniyan ní gbogbo orílẹ̀-èdè ati gbogbo ẹ̀yà tí ó wà ní orí ilẹ̀ ayé ó ní, “Kí alaafia wà pẹlu yín, 26mo pàṣẹ pé ní gbogbo ìjọba mi, kí gbogbo eniyan máa wárìrì níwájú Ọlọrun Daniẹli, kí wọ́n sì máa bẹ̀rù rẹ̀.
“Nítorí òun ni Ọlọrun Alààyè
tí ó wà títí ayérayé.
Ìjọba rẹ̀ kò lè parun lae,
àṣẹ rẹ̀ yóo sì máa wà títí dé òpin.
27Ó ń gbani là,
ó ń dáni nídè.
Ó ń ṣiṣẹ́ àánú tí ó yani lẹ́nu ní ọ̀run ati ní ayé.
Òun ni ó gba Daniẹli lọ́wọ́ agbára kinniun.”
28Nǹkan sì ń dára fún Daniẹli ní àkókò Dariusi ati Kirusi, àwọn ọba Pasia.
DANIẸLI ṢÀLÀYÉ ÀWỌN ÀLÁ RẸ̀
(7:1–12:13)
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
DANIẸLI 6: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010