ÌWÉ ONÍWÀÁSÙ 10

10
1Bí òkú eṣinṣin ṣe lè ba òórùn turari jẹ́;
bẹ́ẹ̀ ni ìwà òmùgọ̀ kékeré lè ba ọgbọ́n ńlá ati iyì jẹ́.
2Ọkàn ọlọ́gbọ́n eniyan a máa darí rẹ̀ sí ọ̀nà rere,
ṣugbọn ọ̀nà burúkú ni ọkàn òmùgọ̀ ń darí rẹ̀ sí.
3Ìrìn ẹsẹ̀ òmùgọ̀ láàrin ìgboro ń fihàn pé kò gbọ́n,
a sì máa fihan gbogbo eniyan bí ó ti gọ̀ tó.
4Bí aláṣẹ bá ń bínú sí ọ,
má ṣe torí rẹ̀ kúrò ní ìdí iṣẹ́ rẹ,
ìtẹríba lè mú kí wọn dárí ẹ̀ṣẹ̀ tí ó bá tóbi jini.
5Nǹkan burúkú tí mo tún rí láyé ni, irú àṣìṣe tí àwọn aláṣẹ pàápàá ń ṣe: 6Wọ́n fi àwọn òmùgọ̀ sí ipò gíga, nígbà tí àwọn ọlọ́rọ̀ wà ní ipò tí ó rẹlẹ̀. 7Mo rí i tí àwọn ẹrú ń gun ẹṣin, nígbà tí àwọn ọmọ-aládé ń fẹsẹ̀ rìn bí ẹrú.
8Ẹni tí ó gbẹ́ kòtò ni yóo jìn sinu rẹ̀,
ẹni tí ó bá já ọgbà wọlé ni ejò yóo bùjẹ.#O. Daf 7:15; Owe 26:27; Sir 27:26-27
9Ẹni tí ó bá ń fọ́ òkúta, ni òkúta í pa lára;
ẹni tí ó bá ń la igi, ni igi í ṣe ní jamba.
10Ẹni tí kò bá pọ́n àáké rẹ̀ kí ó mú,
yóo lo agbára pupọ bí ó bá fẹ́ lò ó,
ṣugbọn ọgbọ́n a máa ranni lọ́wọ́ láti ṣe àṣeyọrí.
11Lẹ́yìn tí ejò bá ti buni jẹ tán,
kò ṣàǹfààní mọ́ kí á máa pọfọ̀ sí ejò.
12Ọ̀rọ̀ ẹnu ọlọ́gbọ́n a máa bu iyì kún un,
ṣugbọn ẹnu òmùgọ̀ ni yóo pa á.
13Agọ̀ ni ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀,
wèrè sì ni ìparí rẹ̀.
14Òmùgọ̀ ń sọ̀rọ̀ láìdákẹ́,
kò sí ẹni tí ó mọ ohun tí ń bọ̀ lẹ́yìn ọ̀la,
ta ni lè sọ ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn rẹ̀ fún un.
15Làálàá ọ̀lẹ ń kó àárẹ̀ bá a,
tóbẹ́ẹ̀ tí kò mọ ọ̀nà ìlú mọ́.
16Ilẹ̀ tí ọba rẹ̀ jẹ́ ọmọde gbé!
Tí àwọn olórí rẹ̀ ń ṣe àríyá láàárọ̀.
17Ilẹ̀ tí ọba rẹ̀ kì í bá ṣe ọmọ ẹrú ṣoríire!
Tí àwọn olórí rẹ̀ ń ṣe àríyá ní àsìkò tí ó tọ́;
tí wọn ń jẹ tí wọn ń mu kí wọn lè lágbára,
ṣugbọn tí kì í ṣe fún ìmutípara.
18Ọ̀lẹ a máa jẹ́ kí ilé ẹni wó,
ìmẹ́lẹ́ a máa jẹ́ kí ilé ẹni jò.
19Oúnjẹ a máa múni rẹ́rìn-ín,
waini a sì máa mú inú ẹni dùn,
ṣugbọn owó ni ìdáhùn ohun gbogbo.
20Má bú ọba, kì báà jẹ́ ninu ọkàn rẹ,
má sì gbé ọlọ́rọ̀ ṣépè, kì báà jẹ́ ninu yàrá rẹ,
nítorí atẹ́gùn lè gbé ọ̀rọ̀ rẹ lọ,
tabi kí àwọn ẹyẹ kan lọ ṣòfófó rẹ.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

ÌWÉ ONÍWÀÁSÙ 10: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀