ÌWÉ ONÍWÀÁSÙ 11
11
Nǹkan Tí Ọlọ́gbọ́n Eniyan Ń Ṣe
1Gbin nǹkan ọ̀gbìn káàkiri lọpọlọpọ, o óo sì kórè ọpọlọpọ èso nígbà tó bá yá. 2Gbin àwọn kan síhìn-ín, gbin àwọn kan sọ́hùn-ún, gbìn ín káàkiri oko nítorí o kò mọ ohun tí ó lè ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ọ̀la.
3Nígbà tí òjò bá ṣú dẹ̀dẹ̀, orí ilẹ̀ ni yóo rọ̀ sí, níbi tí igi bá wó sí, níbẹ̀ náà ni yóo wà.
4Ẹni tí ń wo ojú afẹ́fẹ́ kò ní fún irúgbìn kankan,
ẹni tí ó bá sì ń wo ṣúṣú òjò kò ní kórè.
5Gẹ́gẹ́ bí o kò ti mọ bí ẹ̀mí ṣe ń wọ inú ọmọ ninu aboyún, bẹ́ẹ̀ ni o kò mọ̀ bí Ọlọrun ṣe dá ohun gbogbo. 6Fún irúgbìn ní àárọ̀, má sì ṣe dáwọ́ dúró ní ìrọ̀lẹ́, nítorí o kò mọ èyí tí yóo dàgbà, bóyá ti òwúrọ̀ ni tabi ti ìrọ̀lẹ́, tabi àwọn mejeeji.
7Ìmọ́lẹ̀ dára, oòrùn sì dùn-ún wò. 8Bí eniyan ti wù kí ó pẹ́ láyé tó, kí ó máa yọ̀ ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀, ṣugbọn kí ó ranti pé ọjọ́ tí òun yóo lò ninu ibojì yóo pọ̀ ju èyí tí òun yóo lò láyé lọ. Asán ni ìgbẹ̀yìn gbogbo ohun tí ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀.
Ìmọ̀ràn fún Àwọn Ọ̀dọ́
9Ìwọ ọdọmọkunrin, máa yọ̀ ní ìgbà èwe rẹ, kí inú rẹ máa dùn; máa ṣe bí ọkàn rẹ ti ń fẹ́, ati bí ó ti tọ́ lójú rẹ. Ṣugbọn ranti pé, Ọlọrun yóo ṣe ìdájọ́ gbogbo ohun tí o bá ṣe.
10Gbé ìbànújẹ́ kúrò lọ́kàn rẹ, má sì gba ìrora láàyè lára rẹ, nítorí asán ni ìgbà èwe ati ìgbà ọmọde.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
ÌWÉ ONÍWÀÁSÙ 11: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010

: