ÌWÉ ONÍWÀÁSÙ 8
8
1Ta ló dàbí ọlọ́gbọ́n? Ta ló sì mọ ìtumọ̀ nǹkan? Ọgbọ́n ní ń mú kí ojú ọlọ́gbọ́n máa dán, á mú kí ó tújúká kí ó gbàgbé ìṣòro.
Gbọ́ràn Sọ́ba Lẹ́nu
2Pa òfin ọba mọ́, má sì fi ìwàǹwára jẹ́jẹ̀ẹ́ níwájú Ọlọrun. 3Tètè kúrò níwájú ọba, má sì pẹ́ lọ́dọ̀ rẹ̀ nígbà tí ọ̀rọ̀ bá ń di ibinu, nítorí pé ohun tí ó bá wù ú ló lè ṣe. 4Nítorí pé ohun tí ọba bá sọ ni abẹ gé. Bí ọba bá ṣe nǹkan, ta ló tó yẹ̀ ẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ wò? 5Ẹni tí ó bá ń pa òfin mọ́ kò ní rí ibi; ọlọ́gbọ́n mọ àkókò ati ọ̀nà tí ó yẹ láti gbà ṣe nǹkan. 6Gbogbo nǹkan ló ní àkókò ati ìgbà tirẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wahala wọ ẹ̀dá lọ́rùn. 7Ẹnikẹ́ni kò mọ ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ọ̀la; ta ló lè sọ fún eniyan bí yóo ṣe ṣẹlẹ̀? 8Kò sí ẹni tí ó lágbára láti dá ẹ̀mí dúró, tabi láti yí ọjọ́ ikú pada, gbèsè ni ikú, kò sí ẹni tí kò ní san án; ìwà ibi àwọn tí ń ṣe ibi kò sì le gbà wọ́n sílẹ̀.
Ẹni Ibi ati Olódodo
9Nígbà tí mo fi tọkàntọkàn pinnu láti ṣàkíyèsí ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀ nílé ayé, mo rí i pé ọpọlọpọ eniyan ní ń lo agbára wọn lórí àwọn ẹlòmíràn sí ìpalára ara wọn. 10Mo rí àwọn ẹni ibi tí a sin sí ibojì. Nígbà ayé wọn, wọn a ti máa ṣe wọlé-wọ̀de ní ibi mímọ́, àwọn eniyan a sì máa yìn wọ́n, ní ìlú tí wọn tí ń ṣe ibi. Asán ni èyí pẹlu.
11Nítorí pé wọn kì í tètè dá ẹjọ́ àwọn ẹni ibi, ni ọkàn ọmọ eniyan fi kún fún ìwà ibi. 12Bí ẹlẹ́ṣẹ̀ tilẹ̀ ṣe ibi ní ọpọlọpọ ìgbà tí ọjọ́ rẹ̀ sì gùn, sibẹsibẹ mo mọ̀ pé yóo dára fún àwọn tí ó bẹ̀rù Ọlọrun. 13Ṣugbọn kò ní dára fún ẹni ibi, bẹ́ẹ̀ sì ni ọjọ́ rẹ̀ kò ní gùn bí òjìji, nítorí kò bẹ̀rù Ọlọrun. 14Ohun asán kan tún wà tí ń ṣẹlẹ̀ nílé ayé yìí, a rí àwọn olódodo tí wọn ń jẹ ìyà àwọn eniyan burúkú, tí eniyan burúkú sì ń gba èrè olódodo, asán ni èyí pẹlu.
15Ìmọ̀ràn mi ni pé, kí eniyan máa gbádùn, nítorí kò sí ire kan tí ọmọ eniyan tún ń ṣe láyé ju pé kí ó jẹ, kí ó mu, kí ó sì gbádùn lọ; nítorí èyí ni yóo máa bá a lọ ní gbogbo ọjọ́ tí Ọlọrun fún un láyé.
16Nígbà tí mo fi tọkàntọkàn pinnu láti wá ọgbọ́n ati láti wo iṣẹ́ tí wọn ń ṣe ní ayé, bí eniyan kì í tíí fi ojú ba oorun tọ̀sán-tòru, 17mo wá rí gbogbo iṣẹ́ Ọlọrun pé, kò sí ẹni tí ó lè rí ìdí iṣẹ́ tí ó ń ṣe láyé. Kò sí bí eniyan ti lè ṣe làálàá tó, kò lè rí ìdí rẹ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n ń sọ pé àwọn mọ iṣẹ́ OLUWA, sibẹsibẹ wọn kò lè rí ìdí rẹ̀.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
ÌWÉ ONÍWÀÁSÙ 8: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010