EFESU 4:13-14

EFESU 4:13-14 YCE

Báyìí ni gbogbo wa yóo fi dé ìṣọ̀kan ninu igbagbọ ati ìmọ̀ Ọmọ Ọlọrun, tí a óo fi di géńdé, tí a óo fi dàgbà bí Kristi ti dàgbà. A kì í tún ṣe ọmọ-ọwọ́ mọ́, tí ìgbì yóo máa bì sọ́tùn-ún, sósì, tabi tí afẹ́fẹ́ oríṣìíríṣìí ẹ̀kọ́ àrékérekè àwọn tí wọn ń lo ọgbọ́n-ẹ̀wẹ́ láti fi tan eniyan jẹ yóo máa fẹ́ káàkiri.