ẸSITA 9
9
Àwọn Juu Pa Àwọn Ọ̀tá Wọn Run
1Ní ọjọ́ kẹtala oṣù Adari tíí ṣe oṣù kejila, nígbà tí wọ́n ń múra láti ṣe ohun tí òfin ọba wí, ní ọjọ́ tí àwọn ọ̀tá rò pé ọwọ́ wọn yóo tẹ àwọn Juu, ṣugbọn, tí ó jẹ́ ọjọ́ tí àwọn Juu ṣẹgun àwọn ọ̀tá wọn; 2àwọn Juu péjọ ninu àwọn ìlú wọn ní àwọn ìgbèríko ilẹ̀ Ahasu-erusi ọba, wọ́n múra láti bá àwọn tí wọ́n fẹ́ pa wọ́n run jà. Kò sí ẹni tí ó lè kò wọ́n lójú nítorí pé gbogbo àwọn eniyan ni wọ́n ń bẹ̀rù wọn. 3Gbogbo àwọn olórí àwọn agbègbè, àwọn baálẹ̀, àwọn gomina ati àwọn aláṣẹ ọba ran àwọn Juu lọ́wọ́, nítorí pé ẹ̀rù Modekai ń bà wọ́n. 4Modekai di eniyan pataki ní ààfin; òkìkí rẹ̀ kàn dé gbogbo agbègbè, agbára rẹ̀ sì ń pọ̀ sí i. 5Àwọn Juu fi idà pa àwọn ọ̀tá wọn, wọ́n pa wọ́n run. Ohun tí ó wù wọ́n ni wọ́n ṣe sí àwọn tí wọ́n kórìíra wọn.
6Ní ìlú Susa nìkan, àwọn Juu pa ẹẹdẹgbẹta (500) eniyan. 7Wọ́n sì pa Paṣandata, Dalifoni, Asipata, 8Porata, Adalia, Aridata, 9Pamaṣita, Arisai, Aridai ati Faisata. 10Àwọn mẹ́wẹ̀ẹ̀wá jẹ́ ọmọ Hamani, ọmọ Hamedata, ọ̀tá àwọn Juu, ṣugbọn wọn kò fọwọ́ kan àwọn ẹrù wọn.
11Ní ọjọ́ náà, wọ́n mú ìròyìn iye àwọn tí wọ́n pa ní Susa wá fún ọba. 12Ọba sọ fún Ẹsita Ayaba pé, “Àwọn Juu ti pa ẹẹdẹgbẹta (500) ọkunrin ati àwọn ọmọ Hamani mẹ́wẹ̀ẹ̀wá ní Susa. Kí ni àwọn Juu tí wọ́n wà ní àwọn agbègbè ṣe? Nisinsinyii, kí ni ìbéèrè rẹ? A óo sì ṣe é fún ọ.”
13Ẹsita dáhùn pé, “Bí ó bá tẹ́ ọba lọ́rùn, jẹ́ kí á fún àwọn Juu tí wọ́n wà ní Susa ní àṣẹ láti ṣe gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ṣe ní òní sí àwọn ọ̀tá wọn ní ọ̀la, kí á sì so àwọn ọmọ Hamani mẹ́wẹ̀ẹ̀wá rọ̀ sí orí igi.” 14Ọba pàṣẹ pé kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀. Àṣẹ bá jáde láti Susa, wọ́n sì so àwọn ọmọ Hamani rọ̀ sí orí igi. 15Ní ọjọ́ kẹrinla oṣù Adari àwọn Juu tí wọ́n wà ní Susa tún parapọ̀, wọ́n sì pa ọọdunrun (300) ọkunrin sí i. Ṣugbọn wọn kò fi ọwọ́ kan ẹrù wọn.
16Àwọn Juu tí wọ́n wà ní àwọn agbègbè kó ara wọn jọ láti gba ara wọn sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wọn. Wọ́n pa ẹgbaa mejidinlogoji ó dín ẹgbẹrun (75,000) ninu àwọn tí wọ́n kórìíra wọn, ṣugbọn wọn kò fi ọwọ́ kan ẹrù wọn. 17Ní ọjọ́ kẹtala oṣù Adari ni èyí ṣẹlẹ̀. Ní ọjọ́ kẹrinla, wọ́n sinmi; ọjọ́ náà sì jẹ́ ọjọ́ àsè ati ayọ̀. 18Ní Susa, ọjọ́ kẹẹdogun oṣù ni wọ́n tó ṣe ayẹyẹ tiwọn. Ọjọ́ kẹtala ati ọjọ́ kẹrinla ni àwọn Juu tí wọ́n wà ní Susa pa àwọn ọ̀tá wọn, ní ọjọ́ kẹẹdogun, wọ́n sinmi, ó sì jẹ́ ọjọ́ àsè ati ayọ̀ fún wọn. 19Ìdí nìyí tí àwọn Juu tí wọn ń gbé àwọn agbègbè fi ya ọjọ́ kẹrinla oṣù Adari sọ́tọ̀ fún ọjọ́ àsè, tí wọn yóo máa gbé oúnjẹ fún ara wọn.
Ọjọ́ Àjọ̀dún Purimu
20Modekai kọ gbogbo nǹkan wọnyi sílẹ̀, Ó sì fi ranṣẹ sí àwọn Juu tí wọ́n wà ní gbogbo ilẹ̀ ìjọba Ahasu-erusi ọba, ati àwọn tí wọ́n wà nítòsí ati àwọn tí wọ́n wà ní òkèèrè, 21pé kí wọ́n ya ọjọ́ kẹrinla ati ọjọ́ kẹẹdogun oṣù Adari sọ́tọ̀, 22gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ tí àwọn Juu gba ara wọn sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wọn, tí ìbànújẹ́ ati ẹ̀rù wọn di ayọ̀, tí ọjọ́ ọ̀fọ̀ wọn sì di ọjọ́ àjọ̀dún. Ó pàṣẹ pé kí wọ́n ṣe ọjọ́ náà ní ọjọ́ àjọ̀dún ati ayọ̀, tí wọn yóo máa gbé oúnjẹ fún ara wọn, tí wọn yóo máa fún àwọn talaka ní ẹ̀bùn. 23Àwọn Juu gbà láti máa ṣe bí wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ati bí àṣẹ Modekai.
24Nítorí Hamani, ọmọ Hamedata, láti ìran Agagi, ọ̀tá àwọn Juu ti pète láti pa àwọn Juu run. Ó ti ṣẹ́ gègé, tí wọn ń pè ní Purimu, láti mọ ọjọ́ tí yóo pa àwọn Juu run patapata.#Ẹst 3:7 25Ṣugbọn nígbà tí Ẹsita lọ sọ́dọ̀ ọba, ọba kọ̀wé àṣẹ tí ó mú kí ìpinnu burúkú tí Hamani ní sí àwọn Juu pada sí orí òun tìkararẹ̀, a sì so òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ rọ̀ sórí igi. 26Ìdí nìyí tí wọ́n fi ń pe ọjọ́ náà ní Purimu gẹ́gẹ́ bí orúkọ Purimu, gègé tí Hamani ṣẹ́. Nítorí ìwé tí Modekai kọ ati gbogbo ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí wọn, 27ni àwọn Juu fi sọ ọ́ di òfin fún ara wọn, ati fún arọmọdọmọ wọn, ati fún àwọn tí wọ́n bá di Juu, pé ní àkókò rẹ̀, ní ọdọọdún, ọjọ́ mejeeji yìí gbọdọ̀ jẹ́ ọjọ́ àsè, gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Modekai, 28ati pé kí wọ́n máa ranti àwọn ọjọ́ wọnyi, kí wọ́n sì máa pa wọ́n mọ́ láti ìrandíran, ní gbogbo ìdílé, ní gbogbo agbègbè ati ìlú. Àwọn ọjọ́ Purimu wọnyi kò gbọdọ̀ yẹ̀ láàrin àwọn Juu, bẹ́ẹ̀ ni ìrántí wọn kò gbọdọ̀ parun láàrin arọmọdọmọ wọn.
29Ẹsita Ayaba, ọmọbinrin Abihaili, ati Modekai, tíí ṣe Juu kọ ìwé láti fi ìdí ìwé keji nípa Purimu múlẹ̀. 30Wọ́n kọ ìwé sí gbogbo àwọn Juu ní gbogbo agbègbè mẹtẹẹtadinlaadoje (127) tí ó wà ninu ìjọba Ahasu-erusi. Ìwé náà kún fún ọ̀rọ̀ alaafia ati òtítọ́, 31pé wọn kò gbọdọ̀ gbàgbé láti máa pa àwọn ọjọ́ Purimu mọ́ ní àkókò wọn, gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí Modekai ati Ẹsita Ayaba pa fún àwọn Juu, ati irú ìlànà tí wọ́n là sílẹ̀ fún ara wọn ati arọmọdọmọ wọn, nípa ààwẹ̀ ati ẹkún wọn. 32Àṣẹ tí Ẹsita pa fi ìdí àjọ̀dún Purimu múlẹ̀, wọ́n sì kọ ọ́ sílẹ̀.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
ẸSITA 9: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010