ẸKISODU 23
23
Òdodo ati Ìṣòtítọ́
1“O kò gbọdọ̀ lọ́wọ́ sí àhesọ tí kò ní òtítọ́ ninu. O kò gbọdọ̀ bá eniyan burúkú pa ìmọ̀ pọ̀ láti jẹ́rìí èké.#Eks 20:16; Lef 19:11-12; Diut 5:20. 2O kò gbọdọ̀ bá ọ̀pọ̀ eniyan kẹ́gbẹ́ láti ṣe ibi, tabi kí o tẹ̀lé ọ̀pọ̀ eniyan láti jẹ́rìí èké tí ó lè yí ìdájọ́ po. 3O kò gbọdọ̀ ṣe ojuṣaaju sí talaka lórí ẹjọ́ rẹ̀.#Lef 19:15.
4“Bí o bá pàdé akọ mààlúù ọ̀tá rẹ tabi kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ tí ń ṣìnà lọ, o níláti fà á pada wá fún un. 5Bí o bá rí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ẹni tí ó kórìíra rẹ, tí ẹrù wó kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà mọ́lẹ̀, tí kò lè lọ mọ́, o kò gbọdọ̀ gbójú kúrò kí o fi sílẹ̀ níbẹ̀, o níláti bá a sọ ẹrù náà kalẹ̀.#Diut 22:1-4;
6“O kò gbọdọ̀ yí ìdájọ́ òdodo tí ó tọ́ sí talaka po nígbà tí ó bá ní ẹjọ́. 7O kò gbọdọ̀ fi ẹ̀sùn èké kan ẹnikẹ́ni, o kò sì gbọdọ̀ pa aláìṣẹ̀ tabi olódodo nítorí pé, èmi, OLUWA kò ní dá eniyan burúkú láre. 8O kò gbọdọ̀ gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀, nítorí pé àbẹ̀tẹ́lẹ̀ a máa fọ́ àwọn aláṣẹ lójú, kì í jẹ́ kí wọn rí ẹ̀tọ́, a sì máa mú kí wọn sọ ẹjọ́ aláre di ẹ̀bi.#Lef 19:15; Diut 16:19.
9“O kò gbọdọ̀ pọ́n àlejò lójú, ẹ mọ̀ bí ọkàn àlejò ti rí, nítorí ẹ̀yin pàápàá jẹ́ àlejò rí ní ilẹ̀ Ijipti.#Eks 22:21; Lef 19:33-34; Diut 24:17-18; 27:19.
Ọdún Keje ati Ọjọ́ Keje
10“Ọdún mẹfa ni kí o fi máa fúnrúgbìn sórí ilẹ̀ rẹ kí o sì fi máa kórè àwọn ohun ọ̀gbìn inú rẹ̀. 11Ṣugbọn ní ọdún keje, o gbọdọ̀ fi oko náà sílẹ̀ kí ó sinmi, kí àwọn talaka ninu yín náà lè rí oúnjẹ jẹ, kí àwọn ẹranko sì jẹ ninu èyí tí àwọn talaka bá jẹ kù. Bẹ́ẹ̀ ni o gbọdọ̀ ṣe ọgbà àjàrà rẹ, ati ọgbà olifi rẹ pẹlu.#Lef 25:1-7.
12“Ọjọ́ mẹfa ni kí o fi ṣe iṣẹ́, ṣugbọn ní ọjọ́ keje, kí o sinmi; àtìwọ ati akọ mààlúù rẹ, ati kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ; kí ara lè tu ọmọ iranṣẹbinrin rẹ ati àlejò rẹ.#Eks 20:9-11; 31:15; 34:21; 35:2; Lef 23:3; Diut 5:13-14.
13“Máa ṣe akiyesi gbogbo ohun tí mo ti sọ fún ọ, má sì ṣe bọ oriṣa kankan, má tilẹ̀ jẹ́ kí n gbọ́ orúkọ wọn lẹ́nu rẹ.
Àjọ ńlá mẹ́ta
(Eks 34:18-26; Diut 16:1-17)
14“Ìgbà mẹta ni o níláti máa ṣe àjọ̀dún fún mi ní ọdọọdún. 15O níláti máa ṣe àjọ̀dún àìwúkàrà; gẹ́gẹ́ bí mo ti pa á láṣẹ fún ọ; ọjọ́ meje ni o gbọdọ̀ fi jẹ burẹdi tí kò ní ìwúkàrà ninu, ní àkókò tí mo yà sọ́tọ̀ ninu oṣù Abibu, nítorí pé ninu oṣù náà ni o jáde ní ilẹ̀ Ijipti. Ẹnikẹ́ni kò sì gbọdọ̀ wá sí iwájú mi ní ọwọ́ òfo.#Eks 12:14-20; Lef 23:6-8; Nọm 28:17-25.
16“O gbọdọ̀ ṣe àjọ̀dún ìkórè nígbà tí o bá kórè àkọ́so àwọn ohun tí o gbìn sinu oko rẹ.#(a) Lef 23:15-21; Nọm 28:26-31 (b) Lef 23:39-43.
“Ní òpin ọdún, nígbà tí o bá parí ìkórè gbogbo èso oko rẹ, o gbọdọ̀ ṣe àjọ̀dún ìkórè. 17Ẹẹmẹta ní ọdọọdún ni gbogbo ọkunrin yín níláti wá siwaju èmi OLUWA Ọlọrun yín.
18“Nígbà tí o bá fi ohun ẹlẹ́mìí rúbọ sí mi, burẹdi tí o bá fi rúbọ pẹlu rẹ̀ gbọdọ̀ jẹ́ èyí tí kò ní ìwúkàrà ninu, ọ̀rá ẹran tí o bá fi rúbọ sí mi kò sì gbọdọ̀ kù di ọjọ́ keji.
19“Ohunkohun tí o bá kọ́ kórè ninu oko rẹ, ilé OLUWA Ọlọrun rẹ ni o gbọdọ̀ mú un wá.
“O kò gbọdọ̀ bọ ọmọ ẹran ninu omi wàrà ìyá rẹ̀.#Diut 26:2; Eks 34:26; Diut 14:21.
Ìlérí ati Ìlànà
20“Wò ó, mo rán angẹli kan ṣiwaju rẹ láti pa ọ́ mọ́ ní ọ̀nà rẹ, ati láti mú ọ wá sí ibi tí mo ti tọ́jú fún ọ. 21Máa fetí sí ohun tí angẹli náà bá sọ fún ọ, kí o sì gbọ́ràn sí i lẹ́nu, má ṣe fi agídí ṣe ìfẹ́ inú rẹ lọ́dọ̀ rẹ̀, nítorí pé èmi ni mo rán an, kò sì ní dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́. 22Ṣugbọn bí o bá gbọ́ tirẹ̀, tí o sì ṣe bí mo ti wí, nígbà náà ni n óo gbógun ti àwọn tí ó bá gbógun tì ọ́, n óo sì dojú ìjà kọ àwọn ọ̀tá rẹ. 23Nígbà tí angẹli mi bá ń lọ níwájú rẹ, tí ó bá mú ọ dé ilẹ̀ àwọn ará Amori, ati ti àwọn ará Hiti, ati ti àwọn ará Perisi, ati ti àwọn ará Kenaani, ati ti àwọn ará Hifi, ati ti àwọn ará Jebusi, tí mo bá sì pa wọ́n run, 24o kò gbọdọ̀ foríbalẹ̀ fún àwọn oriṣa wọn, o kò sì gbọdọ̀ bọ wọ́n, tabi kí o hu irú ìwà ìbọ̀rìṣà tí àwọn ará ibẹ̀ ń hù. Wíwó ni kí o wó àwọn ilé oriṣa wọn lulẹ̀, kí o sì fọ́ gbogbo àwọn òpó wọn túútúú. 25Èmi OLUWA Ọlọrun yín ni kí ẹ máa sìn. N óo pèsè ọpọlọpọ nǹkan jíjẹ ati nǹkan mímu fún yín, n óo sì mú àìsàn kúrò láàrin yín. 26Ẹyọ oyún kan kò ní bàjẹ́ lára àwọn obinrin yín, bẹ́ẹ̀ ni ẹyọ obinrin kan kò ní yàgàn ninu gbogbo ilẹ̀ yín. N óo jẹ́ kí ẹ gbó, kí ẹ sì tọ́.
27“N óo da jìnnìjìnnì bo gbogbo àwọn tí ẹ̀ ń lọ dojú ìjà kọ, rúdurùdu yóo sì bẹ́ sí ààrin wọn, gbogbo àwọn ọ̀tá yín ni yóo máa sálọ, nígbàkúùgbà tí wọ́n bá gbúròó yín. 28N óo rán àwọn agbọ́n ńlá ṣáájú yín, tí yóo lé àwọn ará Hifi ati àwọn ará Kenaani ati àwọn ará Hiti jáde fún yín. 29N kò ní tíì lé wọn jáde fún ọdún kan, kí ilẹ̀ náà má baà di aṣálẹ̀, kí àwọn ẹranko sì pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí wọn yóo gba gbogbo ilẹ̀ náà mọ́ yín lọ́wọ́. 30Díẹ̀díẹ̀ ni n óo máa lé wọn jáde fún yín, títí tí ẹ óo fi di pupọ tí ẹ óo sì gba gbogbo ilẹ̀ náà. 31Ilẹ̀ yín yóo lọ títí kan Òkun Pupa, ati títí lọ kan òkun àwọn ará Filistia, láti aṣálẹ̀ títí lọ kan odò Yufurate, nítorí pé n óo fi àwọn tí wọn ń gbé ilẹ̀ náà le yín lọ́wọ́, ẹ óo sì lé wọn jáde. 32Ẹ kò gbọdọ̀ bá àwọn tabi àwọn oriṣa wọn dá majẹmu. 33Wọn kò gbọdọ̀ gbé orí ilẹ̀ yín, kí wọ́n má baà mú yín ṣẹ èmi OLUWA; nítorí pé bí ẹ bá bọ oriṣa wọn, ọrùn ara yín ni ẹ tì bọ tàkúté.”
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
ẸKISODU 23: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010