ẸSIRA Ọ̀rọ̀ Iṣaaju

Ọ̀rọ̀ Iṣaaju
Ìtàn inú Ìwé Ẹsira fara pẹ́ ìtàn inú àwọn Ìwé Kronika . Ìwé yìí sọ ìtàn àwọn Juu tí wọ́n pada sí Israẹli láti oko ẹrú ní Babiloni, ati bí ìgbà ti tún yipada sí rere tí àwọn eniyan sì ń jọ́sìn ní Jerusalẹmu. Àgbékalẹ̀ àwọn ìtàn náà lọ báyìí: (1) Kirusi olórí àwọn Pasia ló dá àwọn ikọ̀ kinni sílẹ̀ ní oko ẹrú Babiloni. (2) Wọ́n tún Tẹmpili kọ́, wọ́n sì yà á sí mímọ́ fún Ọlọrun, wọ́n sì tún bẹ̀rẹ̀ sí sin Ọlọrun ní Jerusalẹmu. (3) Lẹ́yìn ọpọlọpọ ọdún, Ẹsira kó àwọn ikọ̀ mìíràn ninu àwọn Juu wá sí Jerusalẹmu. Ẹsira jẹ́ amòfin ní ti ẹ̀sìn Ọlọrun, a máa ran àwọn Juu lọ́wọ́ nípa títọ́ wọn sọ́nà ẹ̀sìn ati ti ìgbésí ayé wọn, láti lè rí i pé ẹ̀mí mímọ́ tí àwọn Israẹli jogún kò fi wọ́n sílẹ̀.
Àwọn Ohun tí ó wà ninu Ìwé yìí ní Ìsọ̀rí-ìsọ̀rí
Ikọ̀ kinni tí ó kọ́kọ́ ti oko ẹrú dé 1:1–2:70
Wọ́n tún Tẹmpili kọ́, wọ́n sì yà á sí mímọ́ 3:1–6:22
Ẹsira kó àwọn ikọ̀ ẹrú mìíràn dé 7:1–10:44

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

ẸSIRA Ọ̀rọ̀ Iṣaaju: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀