JẸNẸSISI 1:1-4

JẸNẸSISI 1:1-4 YCE

Ní ìbẹ̀rẹ̀, nígbà tí Ọlọrun dá ọ̀run ati ayé, ayé rí júujùu, ó sì ṣófo. Ibú omi bo gbogbo ayé, gbogbo rẹ̀ ṣókùnkùn biribiri, ẹ̀mí Ọlọrun sì ń rábàbà lójú omi. Ọlọrun pàṣẹ pé kí ìmọ́lẹ̀ wà, ìmọ́lẹ̀ sì wà. Ọlọrun wò ó, ó rí i pé ìmọ́lẹ̀ náà dára, ó sì yà á kúrò lára òkùnkùn.