JẸNẸSISI 22
22
Ọlọrun Pàṣẹ fún Abrahamu pé Kí Ó fi Isaaki Rúbọ
1Lẹ́yìn nǹkan wọnyi, Ọlọrun dán Abrahamu wò, ó ní, “Abrahamu!” Abrahamu dáhùn pé, “Èmi nìyí.”
2Ọlọrun ní, “Mú Isaaki ọmọ rẹ kan ṣoṣo tí o fẹ́ràn, kí o lọ sí ilẹ̀ Moraya, kí o sì fi ọmọ náà rú ẹbọ sísun lórí ọ̀kan ninu àwọn òkè tí n óo júwe fún ọ.” #2Kron 3:1
3Abrahamu bá dìde ní òwúrọ̀ kutukutu ọjọ́ keji, ó di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ ní gàárì, ó mú meji ninu àwọn ọdọmọkunrin ilé rẹ̀, ati Isaaki ọmọ rẹ̀ lọ́wọ́. Ó gé igi fún ẹbọ sísun, lẹ́yìn náà wọ́n gbéra, wọ́n lọ sí ibi tí Ọlọrun ti júwe fún Abrahamu. 4Ní ọjọ́ kẹta, bí Abrahamu ti wo ọ̀kánkán, ó rí ibi tí Ọlọrun júwe fún un ní òkèèrè. 5Abrahamu bá sọ fún àwọn ọdọmọkunrin tí wọ́n tẹ̀lé e, ó ní, “Ẹ dúró ti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ níhìn-ín, èmi ati ọmọ yìí yóo rìn siwaju díẹ̀, láti lọ sin Ọlọ́run, a óo sì pada wá bá yín.”
6Abrahamu gbé igi ẹbọ sísun náà lé Isaaki, ọmọ rẹ̀ lórí, ó mú ọ̀bẹ ati iná lọ́wọ́. Àwọn mejeeji jọ ń lọ. 7Isaaki bá pe Abrahamu, baba rẹ̀, ó ní, “Baba mi.” Baba rẹ̀ dá a lóhùn pé, “Kí ni, ọmọ mi?” Isaaki ní, “Wò ó, a rí iná ati igi, àgbò tí a óo fi rú ẹbọ sísun dà?”
8Abrahamu dá a lóhùn pé, “Ọmọ mi, Ọlọrun fúnrarẹ̀ ni yóo pèsè, àgbò tí a óo fi rú ẹbọ sísun náà.” Àwọn mejeeji tún ń bá ìrìn àjò wọn lọ.
9Nígbà tí wọ́n dé ibi tí Ọlọrun júwe fún Abrahamu, ó tẹ́ pẹpẹ kan níbẹ̀, ó to igi sórí pẹpẹ náà, ó di Isaaki ọmọ rẹ̀ tọwọ́ tẹsẹ̀, ó bá gbé e ka orí igi lórí pẹpẹ tí ó tẹ́. #Jak 2:21 10Abrahamu nawọ́ mú ọ̀bẹ láti pa ọmọ rẹ̀. 11Ṣugbọn angẹli OLUWA pè é láti òkè ọ̀run, ó ní, “Abrahamu! Abrahamu!” Abrahamu dáhùn, ó ní, “Èmi nìyí.”
12Angẹli náà wí fún un pé, “Má ṣe pa ọmọ náà rárá, má sì ṣe é ní ohunkohun, nítorí pé nisinsinyii mo mọ̀ dájú pé o bẹ̀rù Ọlọrun, nígbà tí o kò kọ̀ láti fi ọmọ rẹ kan ṣoṣo tí o bí rúbọ sí èmi Ọlọrun.”
13Bí Abrahamu ti gbé orí sókè, tí ó wo ẹ̀yìn rẹ̀, ó rí àgbò kan tí ó fi ìwo kọ́ pàǹtí. Ó lọ mú àgbò náà, ó sì fi rú ẹbọ sísun dípò ọmọ rẹ̀. #Ọgb 10:5; Sir 44:20; Heb 11:17-19. 14Nítorí náà ni Abrahamu ṣe sọ ibẹ̀ ní “OLUWA yóo pèsè,” bí wọ́n ti ń wí títí di òní, pé, “Ní orí òkè OLUWA ni yóo ti pèsè.”
15Angẹli OLUWA tún pe Abrahamu láti òkè ọ̀run ní ìgbà keji, 16ó ní, “Mo fi ara mi búra pé nítorí ohun tí o ṣe yìí, tí o kò kọ̀ láti fún mi ní ọmọ rẹ kan ṣoṣo, 17n óo bukun ọ lọpọlọpọ, n óo sọ àwọn ọmọ ọmọ rẹ di pupọ bí ìràwọ̀ ojú ọ̀run, ati bíi yanrìn etí òkun. Àwọn ọmọ ọmọ rẹ yóo máa ṣẹgun àwọn ọ̀tá wọn ní gbogbo ìgbà. #Heb 6:13-14 #Heb 11:12 18Nípasẹ̀ àwọn ọmọ rẹ ni n óo ti bukun gbogbo orílẹ̀-èdè ayé, nítorí pé o gbọ́ràn sí mi lẹ́nu.” #A. Apo 3:25. 19Abrahamu bá pada tọ àwọn ọdọmọkunrin rẹ̀ lọ, wọ́n bá jọ gbéra, wọ́n pada lọ sí Beeriṣeba, Abrahamu sì ń gbé ibẹ̀.
Àwọn Ìran Nahori
20Lẹ́yìn náà, wọ́n wá sọ fún Abrahamu pé Milika ti bímọ fún Nahori arakunrin rẹ̀. 21Usi ni àkọ́bí, Busi ni wọ́n bí tẹ̀lé e, lẹ́yìn náà Kemueli tíí ṣe baba Aramu. 22Lẹ́yìn rẹ̀ ni wọ́n bí Kesedi, Haso, Pilidaṣi, Jidilafi ati Betueli. 23Betueli ni baba Rebeka. Àwọn mẹjẹẹjọ yìí ni Milika bí fún Nahori, arakunrin Abrahamu. 24Nahori tún ní obinrin mìíràn tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Reuma, òun ni ó bí Teba, Gahamu, Tahaṣi, ati Mahaka fún Nahori.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
JẸNẸSISI 22: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010