JẸNẸSISI 38
38
Juda ati Tamari
1Kò pẹ́ pupọ lẹ́yìn náà ni Juda bá fi àwọn arakunrin rẹ̀ sílẹ̀, ó kó lọ sí ọ̀dọ̀ ará Adulamu kan tí wọn ń pè ní Hira. 2Níbẹ̀ ni Juda ti rí ọmọbinrin ará Kenaani kan, tí baba rẹ̀ ń jẹ́ Ṣua, ó gbé e níyàwó, ó sì bá a lòpọ̀. 3Ó lóyún, ó bí ọmọkunrin kan, Juda sọ ọmọ náà ní Eri. 4Ó tún lóyún, ó bí ọmọkunrin keji, ó sọ ọ́ ní Onani. 5Ó tún lóyún mìíràn, ó tún bí ọkunrin bákan náà, ó bá sọ ọmọ náà ní Ṣela. Ìlú Kẹsibu ni ó wà nígbà tí ó bí ọmọ náà.
6Juda fẹ́ aya fún Eri, àkọ́bí rẹ̀. Orúkọ obinrin náà ni Tamari. 7Ìwà Eri burú tóbẹ́ẹ̀ tí Ọlọrun fi pa á. 8Juda bá pe Onani, ó ní, “Ṣú iyawo arakunrin rẹ lópó kí o sì bá a lòpọ̀, kí ó lè bímọ fún arakunrin rẹ.” 9Ṣugbọn Onani mọ̀ pé ọmọ tí opó náà bá bí kò ní jẹ́ ti òun, nítorí náà, nígbàkúùgbà tí ó bá ń bá opó yìí lòpọ̀, yóo sì da nǹkan ọkunrin rẹ̀ sílẹ̀, kí ó má baà bí ọmọ tí yóo rọ́pò arakunrin rẹ̀. 10Ohun tí Onani ń ṣe yìí kò dùn mọ́ Ọlọrun ninu, Ọlọrun bá pa òun náà. 11Juda bá sọ fún Tamari opó ọmọ rẹ̀ pé, “Wá pada sí ilé baba rẹ kí o lọ máa ṣe opó níbẹ̀ títí tí Ṣela, ọmọ mi yóo fi dàgbà.” Ṣugbọn ọ̀rọ̀ tí Juda sọ yìí kò dé inú rẹ̀ nítorí ẹ̀rù ń bà á pé kí Ṣela náà má kú bí àwọn arakunrin rẹ̀, Tamari bá pada lọ sí ilé baba rẹ̀.
12Lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, aya Juda, tíí ṣe ọmọ Ṣua kú. Nígbà tí Juda ṣọ̀fọ̀ rẹ̀ parí, òun ati Hira ará Adulamu, ọ̀rẹ́ rẹ̀ bá múra, wọ́n lọ sí Timna lọ́dọ̀ àwọn tí wọn ń rẹ́ irun aguntan Juda. 13Àwọn kan lọ sọ fún Tamari pé baba ọkọ rẹ̀ ń lọ sí Timna láti rẹ́ irun aguntan rẹ̀. 14Tamari bá bọ́ aṣọ ọ̀fọ̀ kúrò lára, ó fi ìbòjú bo ojú rẹ̀, ó wọ aṣọ tí ó dára, ó bá jókòó lẹ́nu bodè Enaimu tí ó wà lọ́nà Timna; nítorí ó mọ̀ pé Ṣela ti dàgbà, wọn kò sì ṣú òun lópó fún un.
15Nígbà tí Juda rí Tamari tí ó fi aṣọ bojú, ó rò pé aṣẹ́wó ni. 16Ó tọ̀ ọ́ lọ níbi tí ó jókòó sí lẹ́bàá ọ̀nà, ó ní, “Wá, jẹ́ kí n bá ọ lòpọ̀,” kò mọ̀ pé opó ọmọ òun ni. Tamari dá a lóhùn, ó ní: “Kí ni o óo fún mi tí mo bá gbà fún ọ?”
17Juda dáhùn, ó ní, “N óo fi àwọ́nsìn ewúrẹ́ kan ranṣẹ sí ọ láti inú agbo ẹran mi.” Tamari ní, “O níláti fi nǹkankan dógò títí tí o óo fi fi ọmọ ewúrẹ́ náà ranṣẹ.”
18Juda bá bèèrè pé kí ni ó fẹ́ kí òun fi dógò.
Ó dá a lóhùn, ó ní, “Èdìdì rẹ pẹlu okùn rẹ, ati ọ̀pá tí ó wà ní ọwọ́ rẹ.” Juda bá kó wọn fún un, ó sì bá a lòpọ̀, Tamari sì lóyún. 19Ó dìde, ó bá tirẹ̀ lọ, ó ṣí ìbòjú rẹ̀ kúrò, ó sì tún wọ aṣọ ọ̀fọ̀ rẹ̀.
20Juda fi àwọ́nsìn ewúrẹ́ náà rán ọ̀rẹ́ rẹ̀, ará Adulamu, sí Tamari, kí ó le bá a gba àwọn ohun tí ó fi dógò lọ́wọ́ rẹ̀, ṣugbọn kò bá a níbẹ̀ mọ́. 21Ó bi àwọn ọkunrin kan, ará ìlú náà pé, “Níbo ni obinrin aṣẹ́wó tí ó máa ń jókòó ní gbangba lẹ́bàá ọ̀nà Enaimu yìí wà?”
Wọ́n dáhùn pé, “Kò fi ìgbà kan sí aṣẹ́wó kankan ní àdúgbò yìí.”
22Ọ̀rẹ́ Juda bá pada tọ̀ ọ́ lọ, ó ní òun kò rí i, ati pé àwọn ọkunrin tí wọ́n wà níbẹ̀ sọ pé kò fi ìgbà kan sí aṣẹ́wó kankan níbẹ̀.
23Juda dá a lóhùn, ó ní, “Má wulẹ̀ wá a kiri mọ́, kí àwọn eniyan má baà máa fi wá ṣe yẹ̀yẹ́. Jẹ́ kí ó ṣe àwọn nǹkan ọwọ́ rẹ̀ bí ó bá ti fẹ́, mo ṣá fi àwọ́nsìn ewúrẹ́ tí mo ṣèlérí ranṣẹ, o kò rí i ni.”
24Lẹ́yìn bí oṣù mẹta sí i, ẹnìkan wá sọ fún Juda pé, “Wò ó! Iṣẹ́ aṣẹ́wó ni Tamari, opó ọmọ rẹ ń ṣe, ó sì ti lóyún.”
Juda bá dáhùn, ó ní, “Ẹ lọ mú un wá kí wọ́n dáná sun ún.”
25Nígbà tí wọ́n mú un dé, ó ranṣẹ sí baba ọkọ rẹ̀, ó ní, “Ẹni tí ó ni àwọn nǹkan wọnyi ni ó fún mi lóyún. Jọ̀wọ́ yẹ̀ wọ́n wò, kí o mọ ẹni tí ó ni èdìdì yìí pẹlu okùn rẹ̀, ati ọ̀pá yìí.”
26Juda yẹ̀ wọ́n wò, ó sì mọ̀ wọ́n, ó ní, “O ṣe olóòótọ́ jù mí lọ, èmi ni mo jẹ̀bi nítorí pé n kò ṣú ọ lópó fún Ṣela, ọmọ mi.” Kò sì bá a lòpọ̀ mọ́.
27Nígbà tí ọjọ́ ìkúnlẹ̀ rẹ̀ pé, wọ́n rí i pé ìbejì ni ó wà ninu rẹ̀. 28Bí ó ti ń rọbí, ọ̀kan ninu àwọn ọmọ náà yọ ọwọ́ jáde, ẹni tí ń bá a gbẹ̀bí bá so òwú pupa mọ́ ọn lọ́wọ́, ó ní “Èyí tí ó kọ́ jáde nìyí.” 29Ṣugbọn bí ọmọ náà ti fa ọwọ́ rẹ̀ pada, arakunrin rẹ̀ bá jáde. Agbẹ̀bí náà bá wí pé, “Ṣé bí o ti fẹ́ rìn nìyí, ó hàn lára rẹ.” Ó bá sọ orúkọ rẹ̀ ní Peresi. 30Láìpẹ́ arakunrin rẹ̀ náà wálẹ̀, pẹlu òwú pupa tí wọ́n so mọ́ ọn lọ́wọ́, wọ́n bá sọ ọ́ ní Sera.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
JẸNẸSISI 38: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010