AISAYA 20

20
Àmì Wolii tó Wà Níhòhò
1Ní ọdún tí Sagoni, ọba Asiria, rán olórí ogun rẹ̀ pé kí ó lọ bá ìlú Aṣidodu jagun, tí ó gbógun ti ìlú náà, tí ó sì gbà á, 2OLUWA sọ fún Aisaya ọmọ Amosi pé, “Dìde, bọ́ aṣọ ọ̀fọ̀ tí o lọ́ mọ́ra, sì bọ́ bàtà tí o wọ̀ sí ẹsẹ̀.” Aisaya bá ṣe bí OLUWA ti wí: ó bọ́ aṣọ ọ̀fọ̀ lára, ó sì bọ́ bàtà kúrò lẹ́sẹ̀. Ó bá bẹ̀rẹ̀ sí rìn kiri ní ìhòòhò, láìwọ bàtà. 3Lẹ́yìn ọdún mẹta, OLUWA dáhùn pé, “Bí Aisaya, iranṣẹ mi, ti rìn ní ìhòòhò tí kò sì wọ bàtà fún ọdún mẹta yìí, jẹ́ àmì ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ sí ilẹ̀ Ijipti ati ilẹ̀ Kuṣi: 4Bẹ́ẹ̀ ni ọba Asiria yóo ṣe kó àwọn ará Ijipti ati àwọn ará Kuṣi lẹ́rú, ati ọmọde ati àgbàlagbà wọn, ní ìhòòhò, láì wọ bàtà. A óo bọ́ aṣọ kúrò lára wọn, kí ojú ó lè ti Ijipti. 5Ìbẹ̀rù-bojo yóo dé ba yín, ojú yóo sì tì yín; nítorí Kuṣi ati Ijipti tí ẹ gbójú lé. 6Àwọn tí ń gbé etí òkun ilẹ̀ yìí yóo wí ní ọjọ́ náà pé, ‘Ẹ wo ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí àwọn tí a gbójú lé, àwọn tí à ń sá tọ̀ lọ pé kí wọ́n ràn wá lọ́wọ́, kí wọ́n gbà wá lọ́wọ́ ọba Asiria. Báwo ní àwa óo ṣe wá là báyìí?’ ”

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

AISAYA 20: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀