AISAYA 28
28
Ìkìlọ̀ fún Ilẹ̀ Israẹli
1Adé ìgbéraga àwọn ọ̀mùtí Efuraimu gbé!
Ẹwà ògo rẹ̀ tí ń ṣá bí ìtànná náà gbé!
Ìlú tí ó wà ní òkè àfonífojì dáradára,
ohun àmúyangàn fún àwọn tí ó mutí yó.
2Wò ó! OLUWA ní ẹnìkan,
tí ó lágbára bí ẹ̀fúùfù líle, ati bí ìjì apanirun,
bí afẹ́fẹ́ òjò tí ó lágbára
tí àgbàrá rẹ̀ ṣàn kọjá bèbè;
ẹni náà yóo bì wọ́n lulẹ̀.
3Ẹsẹ̀ ni yóo fi tẹ adé ìgbéraga
àwọn ọ̀mùtí ilẹ̀ Efuraimu.
4Ògo rẹ̀ tí ń ṣá bí òdòdó
tí ó wà ní òkè àfonífojì dáradára,
yóo dàbí àkọ́so èso ọ̀pọ̀tọ́,
tí ó pọ́n ṣáájú ìgbà ìkórè.
Ẹni tó bá rí i yóo sáré sí i,
yóo ká a, yóo sì jẹ ẹ́.
5Ní ọjọ́ náà,
OLUWA àwọn ọmọ ogun yóo jẹ́ adé ògo ati adé ẹwà,
fún àwọn tí ó kù ninu àwọn eniyan rẹ̀.
6Yóo jẹ́ ẹ̀mí ìdájọ́ ẹ̀tọ́
fún adájọ́ tí ó jókòó lórí ìtẹ́ ìdájọ́,
yóo jẹ́ agbára fún àwọn tí ó ń lé ogun sẹ́yìn lẹ́nu ibodè.
Aisaya ati Àwọn Ọ̀mùtí Wolii Ilẹ̀ Juda.
7Ọtí waini ń ti àwọn wọnyi,
ọtí líle ń mú wọn ta gbọ̀n-ọ́n-gbọ̀n-ọ́n.
Ọtí líle ń ti alufaa ati wolii,
ọtí waini kò jẹ́ kí wọ́n mọ ohun tí wọ́n ń ṣe mọ́.
Ọtí líle ń mú wọn ta gbọ̀n-ọ́n-gbọ̀n-ọ́n;
wọ́n ń ríran èké, wọ́n ń dájọ́ irọ́.
8Nítorí èébì kún orí gbogbo tabili oúnjẹ,
gbogbo ilẹ̀ sì kún fún ìdọ̀tí
9Wọ́n ń sọ pé, “Ta ni yóo kọ́ lọ́gbọ́n?
Ta sì ni yóo jíṣẹ́ náà fún?
Ṣé àwọn tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ gbọyàn lẹ́nu wọn,
àbí àwọn tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ já lẹ́nu ọmú?
10Nítorí pé gbogbo rẹ̀ tòfin-tòfin ni,
èyí òfin, tọ̀hún ìlànà.
Díẹ̀ níhìn-ín, díẹ̀ lọ́hùn-ún.”
11Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, àwọn àjèjì tí èdè wọn yàtọ̀ ni OLUWA yóo lò
láti bá àwọn eniyan wọnyi sọ̀rọ̀.
12Àwọn tí ó ti wí fún pé:#1 Kọr 14:21
Ìsinmi nìyí,
ẹ fún àwọn tí àárẹ̀ mú ní ìsinmi;
ìtura nìyí.
Sibẹsibẹ wọ́n kọ̀, wọn kò gbọ́.
13Nítorí náà ọ̀rọ̀ OLUWA sí wọn yóo jẹ́ tòfin-tòfin,
èyí òfin tọ̀hún ìlànà.
Díẹ̀ níhìn-ín, díẹ̀ lọ́hùn-ún,
kí wọ́n baà lè lọ ṣubú sẹ́yìn
kí wọ́n sì fọ́ wẹ́wẹ́;
kí á lè dẹ tàkúté sílẹ̀ fún wọn,
kí ọwọ́ lè tẹ̀ wọ́n.
Òkúta Igun Ilé fún Sioni
14Nítorí náà, ẹ gbọ́ ohun tí OLUWA wí,
ẹ̀yin oníyẹ̀yẹ́ eniyan,
tí ẹ̀ ń ṣe àkóso àwọn eniyan wọnyi ní Jerusalẹmu.
15Nítorí ẹ wí pé:#Ọgb 1:16; Sir 14:12
“A ti bá ikú dá majẹmu,
a sì ti bá ibojì ṣe àdéhùn.
Nígbà tí jamba bá ń bọ̀,
kò ní dé ọ̀dọ̀ wa;
nítorí a ti fi irọ́ ṣe ibi ìsádi wa,
a sì ti fi èké ṣe ibi ààbò.”
16Nítorí náà OLUWA Ọlọrun sọ pé,#O. Daf 118 22-23; Rom 9:33; 10:11; 1 Pet 2:6
“Wò ó! Èmi yóo ri òkúta ìpìlẹ̀ ilé kan mọ́lẹ̀ ní Sioni,
yóo jẹ́ òkúta tí ó lágbára,
òkúta igun ilé iyebíye, tí ó ní ìpìlẹ̀ tí ó dájú:
Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbà á gbọ́, ojú kò níí kán an.
17Ìdájọ́ ẹ̀tọ́ ni n óo fi ṣe okùn ìwọnlẹ̀,
òdodo ni n óo fi ṣe ìwọ̀n ògiri.”
Òjò àdàpọ̀ mọ́ yìnyín yóo gbá ibi ààbò irọ́ dànù,
omi yóo sì bo ibi tí wọ́n sápamọ́ sí.
18Majẹmu tí ẹ bá ikú dá yóo wá di òfo,
àdéhùn yín pẹlu ibojì yóo sì di asán.
Nígbà tí jamba bá ń ṣẹlẹ̀ káàkiri,
yóo máa dé ba yín.
19Gbogbo ìgbà tí ó bá ti ń ṣẹlẹ̀
ni yóo máa ba yín tí yóo máa gba yín lọ.
Yóo máa ṣẹlẹ̀ láàárọ̀,
yóo sì máa ṣẹlẹ̀ tọ̀sán-tòru.
Ẹ̀rù yóo ba eniyan,
tí eniyan bá mọ ìtumọ̀ ìkìlọ̀ náà.
20Ibùsùn kò ní na eniyan tán.
Bẹ́ẹ̀ ni aṣọ ìbora kò ní fẹ̀ tó eniyan bora.
21Nítorí pé OLUWA yóo dìde#a 2Sam 5:20 1Kron 14:11 b Joṣ 10:10-12
bí ó ti ṣe ní òkè Firasi,
yóo bínú bí ó ti bínú ní àfonífojì Gibeoni.
Yóo ṣe ohun tí ó níí ṣe,
ohun tí yóo ṣe yóo jọni lójú;
yóo ṣe iṣẹ́ rẹ̀
iṣẹ́ rẹ̀ yóo ṣe àjèjì.
22Nítorí náà ẹ má ṣe yẹ̀yẹ́,
kí á má baà so ẹ̀wọ̀n yín le.
Nítorí mo ti gbọ́ ìkéde ìparun,
tí OLUWA àwọn ọmọ ogun pinnu láti mú wá sórí ilẹ̀ ayé.
Ọgbọ́n Ọlọrun
23Ẹ fetí sílẹ̀ kí ẹ gbọ́ ohùn mi,
ẹ tẹ́tí sílẹ̀ kí ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ mi,
24ṣé ẹni tí ń kọ ilẹ̀ tí ó fẹ́ gbin ohun ọ̀gbìn
lè máa kọ ọ́ lọ láì dáwọ́ dúró?
Àbí ó lè máa kọ ebè lọ láì ní ààlà?
25Ṣugbọn bí ó bá ti tọ́jú oko rẹ̀ tán,
ṣé kò ní fọ́n èso dili ati èso Kumini sinu rẹ̀,
kí ó gbin alikama lẹ́sẹẹsẹ;
kí ó gbin ọkà baali sí ibi tí ó yẹ,
kí ó sì gbin oríṣìí ọkà mìíràn sí ààlà oko rẹ̀?
26Yóo ṣe iṣẹ́ rẹ̀ létòlétò bí ó ti yẹ,
nítorí pé Ọlọrun rẹ̀ ní ń kọ́ ọ.
27Àgbẹ̀ kì í fi òkúta ńlá ṣẹ́ ẹ̀gúsí,
bẹ́ẹ̀ ni kò ní fi kùmọ̀, lu kumini.
Ọ̀pá ni wọ́n fí ń lu ẹ̀gúsí;
igi lásán ni wọ́n fí ń lu kumini.
28Ǹjẹ́ eniyan a máa fi kùmọ̀ lọ ọkà alikama tí wọ́n fi ń ṣe burẹdi?
Rárá, ẹnìkan kì í máa pa ọkà títí kí ó má dáwọ́ dúró.
Bó ti wù kí eniyan fi ẹṣin yí ẹ̀rọ ìpakà lórí ọkà alikama tó,
ẹ̀rọ ìpakà kò lè lọ ọkà kúnná.
29Ọ̀dọ̀ OLUWA àwọn ọmọ ogun ni ìmọ̀ yìí ti ń wá pẹlu,
ìmọ̀ràn rẹ̀ yani lẹ́nu;
ọgbọ́n rẹ̀ ni ó sì ga jùlọ.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
AISAYA 28: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010