AISAYA 31
31
Ọlọrun Yóo Dáàbò Bo Jerusalẹmu
1Àwọn tí ó ń lọ sí Ijipti fún ìrànlọ́wọ́ gbé!
Àwọn tí wọ́n gbójú lé ẹṣin;
tí wọ́n gbẹ́kẹ̀lé kẹ̀kẹ́ ogun nítorí pé wọ́n pọ̀,
tí wọ́n gbójú lé ẹṣin
nítorí pé wọ́n lágbára!
Wọn kò gbójú lé Ẹni Mímọ́ Israẹli,
wọn kò sì wádìí ọ̀rọ̀ lọ́dọ̀ OLUWA.
2Bẹ́ẹ̀ ni ó gbọ́n,
ó sì mọ ọ̀nà tí ó fi lè mú kí àjálù dé bá eniyan,
kì í sọ̀rọ̀ tán, kó yí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pada.
Ṣugbọn yóo dìde sí ìdílé àwọn aṣebi,
ati àwọn tí ń ti àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ lẹ́yìn.
3Eniyan sá ni àwọn ará Ijipti,
wọn kìí ṣe Ọlọrun.
Ẹranko lásán sì ni ẹṣin wọn
wọn kì í ṣe àǹjọ̀nnú.
Bí OLUWA bá na ọwọ́, tí ó bá gbá wọn mú,
ẹni tí ń ranni lọ́wọ́ yóo fẹsẹ̀ kọ,
ẹni tí à ń ràn lọ́wọ́ yóo ṣubú;
gbogbo wọn yóo sì jọ ṣègbé pọ̀.
4Nítorí OLUWA sọ fún mi pé,
“Bí kinniun tabi ọmọ kinniun
ti máa ń kùn lórí ẹran tí ó bá pa,
tí kìí bìkítà fún igbe àwọn olùṣọ́ aguntan,
tí wọ́n pera wọn jọ, tí wọn ń bọ̀,
tí ẹ̀rù ariwo wọn kìí sìí bà á;
bẹ́ẹ̀ ni OLUWA àwọn ọmọ ogun yóo sọ̀kalẹ̀,
yóo wá jà lórí òkè Sioni ati àwọn òkè tí ó yí Sioni ká.
5Bí àwọn ẹyẹ tií da ìyẹ́ bo ìtẹ́ wọn,
bẹ́ẹ̀ ni OLUWA àwọn ọmọ ogun
yóo dáàbò bo Jerusalẹmu,
yóo dáàbò bò ó, yóo sì gbà á sílẹ̀
yóo dá a sí, yóo sì yọ ọ́ kúrò ninu ewu.”
6Ẹ̀yin ọmọ Israẹli,
ẹ pada sọ́dọ̀ ẹni tí ẹ ti ṣàìgbọràn sí lọpọlọpọ.
7Nítorí pé ní ọjọ́ náà, olukuluku yóo gbé àwọn ère fadaka
ati ère wúrà tí ó fi ọwọ́ rẹ̀ ṣe sọnù,
àwọn ère tí ó mú wọn dẹ́ṣẹ̀.
8Idà ni yóo pa Asiria, ṣugbọn kì í ṣe láti ọwọ́ eniyan;
idà tí kò ní ọwọ́ eniyan ninu ni yóo pa á run.
Yóo sá lójú ogun,
a óo sì kó àwọn ọmọkunrin rẹ̀ lọ máa ṣiṣẹ́ tipátipá.
9Ẹ̀rù yóo ba ọba Asiria, yóo sálọ.
Ìpayà yóo mú kí àwọn ọ̀gágun rẹ̀ ju àsíá sílẹ̀.
OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀,
OLUWA tí iná rẹ̀ wà ní Sioni,
tí ojú ààrò rẹ̀ wà ní Jerusalẹmu.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
AISAYA 31: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010