AISAYA 33:15-16

AISAYA 33:15-16 YCE

Ẹni tí ọ̀nà rẹ̀ bá tọ́, tí ó sì ń sọ ọ̀rọ̀ òtítọ́, ẹni tí ó kórìíra èrè àjẹjù, tí ó kọ̀, tí kò gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀, tí ó di etí sí ọ̀rọ̀ àwọn tí ń gbèrò ati paniyan, tí ó sì di ojú rẹ̀ kí ó má baà rí nǹkan ibi. Ibi ààbò ni yóo máa gbé, àpáta ńlá ni yóo jẹ́ ibi ààbò rẹ̀. Yóo máa rí oúnjẹ jẹ déédé, yóo sì máa rí omi mu lásìkò, lásìkò.