Isa 33:15-16
Isa 33:15-16 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ẹniti nrìn li ododo, ti o si nsọ̀rọ titọ́; ẹniti o gàn ère ininilara, ti o gbọ̀n ọwọ́ rẹ̀ kuro ni gbigbà abẹtẹlẹ, ti o di eti rẹ ni gbigbọ́ ti ẹ̀jẹ, ti o si di oju rẹ̀ ni riri ibi. On na yio gbe ibi giga: ile apáta yio ṣe ibi ãbo rẹ̀: a o fi onjẹ fun u; omi rẹ̀ yio si daju.
Isa 33:15-16 Yoruba Bible (YCE)
Ẹni tí ọ̀nà rẹ̀ bá tọ́, tí ó sì ń sọ ọ̀rọ̀ òtítọ́, ẹni tí ó kórìíra èrè àjẹjù, tí ó kọ̀, tí kò gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀, tí ó di etí sí ọ̀rọ̀ àwọn tí ń gbèrò ati paniyan, tí ó sì di ojú rẹ̀ kí ó má baà rí nǹkan ibi. Ibi ààbò ni yóo máa gbé, àpáta ńlá ni yóo jẹ́ ibi ààbò rẹ̀. Yóo máa rí oúnjẹ jẹ déédé, yóo sì máa rí omi mu lásìkò, lásìkò.
Isa 33:15-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ẹni tí ó ń rìn lódodo tí ó ń sọ ohun tí ó tọ́, tí ó kọ èrè tí ó ti ibi ìlọ́nilọ́wọ́gbà wá, tí ó sì pa ọwọ́ rẹ̀ mọ́ kúrò nínú gbígba àbẹ̀tẹ́lẹ̀, tí ó di etí rẹ̀ sí ọ̀tẹ̀ láti pànìyàn tí ó sì di ojú rẹ̀ sí à ti pète ibi Òun náà yóò gbé ní ibi gíga, ibi ààbò rẹ̀ yóò jẹ́ òkè ńlá olódi. A ó mú oúnjẹ fún un, omi rẹ̀ yóò sì dájú.