Isa 33:15-16

Isa 33:15-16 YBCV

Ẹniti nrìn li ododo, ti o si nsọ̀rọ titọ́; ẹniti o gàn ère ininilara, ti o gbọ̀n ọwọ́ rẹ̀ kuro ni gbigbà abẹtẹlẹ, ti o di eti rẹ ni gbigbọ́ ti ẹ̀jẹ, ti o si di oju rẹ̀ ni riri ibi. On na yio gbe ibi giga: ile apáta yio ṣe ibi ãbo rẹ̀: a o fi onjẹ fun u; omi rẹ̀ yio si daju.