AISAYA 39

39
Ọba Babiloni kọ ìwé kí Hesekaya
1Ní àkókò náà Merodaki Baladani ọmọ Baladani, ọba Babiloni, fi ìwé ati ẹ̀bùn rán àwọn ikọ̀ kan sí Hesekaya, nítorí ó gbọ́ pé ara rẹ̀ kò ti dá tẹ́lẹ̀ ṣugbọn ara rẹ̀ ti wá le. 2Hesekaya gbà wọ́n lálejò, ó sì fi àwọn nǹkan tí ó wà ninu ilé ìṣúra rẹ̀ hàn wọ́n, fadaka ati wúrà, àwọn nǹkan olóòórùn dídùn ati òróró olówó iyebíye, ilé ìkó nǹkan ìjà ogun sí, ati gbogbo nǹkan tí ó wà ninu ilé ìṣúra. Kò sí nǹkan tí ó wà ní ìpamọ́ ní ààfin Hesekaya ní ilé rẹ̀ tí kò fihàn wọ́n. 3Lẹ́yìn náà Aisaya wolii tọ Hesekaya ọba lọ, ó bi í pé, “Kí ni àwọn ọkunrin wọnyi wí, láti ibo ni wọ́n sì ti wá sọ́dọ̀ rẹ?” Hesekaya dáhùn, ó ní, “Láti ilẹ̀ òkèèrè, ní Babiloni ni wọ́n ti wá.”
4Aisaya tún bi í pé, “Kí ni wọ́n rí láàfin rẹ?” Hesekaya dáhùn, ó ní, “Gbogbo ohun tó wà láàfin ni wọ́n rí. Kò sí ohun tí ó wà ní ilé ìṣúra mi tí n kò fihàn wọ́n.”
5Aisaya bá sọ fún Hesekaya, pé, “Gbọ́ ohun tí OLUWA àwọn ọmọ ogun wí: 6Ó ní, ‘Ọjọ́ ń bọ̀ tí a óo ru gbogbo ohun tí ó wà láàfin rẹ lọ sí Babiloni, ati gbogbo ìṣúra tí àwọn baba ńlá rẹ ti kó jọ títí di òní. Kò ní ku nǹkankan.’ OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀. 7‘A óo kó ninu àwọn ọmọ bíbí inú rẹ lọ, a óo sì fi wọ́n ṣe ìwẹ̀fà láàfin ọba Babiloni.’ ” 8Hesekaya dá Aisaya lóhùn, ó ní, “Ohun rere ni OLUWA sọ.” Ó sọ bẹ́ẹ̀ nítorí ó rò pé alaafia ati ìfọ̀kànbalẹ̀ yóo wà ní àkókò tòun.#Dan 1:1-7; 2A. Ọba 24:10-16; 2Kron 36:10

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

AISAYA 39: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀