AISAYA 41
41
Ọlọrun fún Israẹli ní Ìdánilójú
1“Ẹ dákẹ́ jẹ́ẹ́, kí ẹ sì gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, ẹ̀yin erékùṣù,
kí àwọn eniyan gba agbára kún agbára wọn,
kí wọ́n súnmọ́ ìtòsí, kí wọ́n sọ tẹnu wọn,
ẹ jẹ́ kí á pàdé ní ilé ẹjọ́.
2“Ta ló gbé ẹnìkan dìde ní ìhà ìlà oòrùn?
Tí ó ń ṣẹgun ní ibikíbi tí ó bá fẹsẹ̀ tẹ̀?
Ta ló fi àwọn orílẹ̀-èdè lé e lọ́wọ́
tí ó fi lè tẹ àwọn ọba mọ́lẹ̀?
Idà rẹ̀ gé wọn bí eruku,
ọfà rẹ̀ sì tú wọn ká bí àgékù koríko.
3A máa lépa wọn, a sì máa kọjá wọn láìléwu,
ní ọ̀nà tí ẹsẹ̀ rẹ̀ kò tẹ̀ rí.
4Ta ló ṣe èyí?
Iṣẹ́ ọwọ́ ta sì ni?
Tí ó pe ìran dé ìran láti ìbẹ̀rẹ̀?
Èmi OLUWA ni, ẹni àkọ́kọ́ ati ẹni ìkẹyìn.
5“Àwọn erékùṣù rí i, ẹ̀rù bà wọ́n,
gbogbo òpin ayé gbọ̀n rìrì wọ́n ti súnmọ́ tòsí, wọ́n ti dé.
6Olukuluku ń ran ẹnìkejì rẹ̀ lọ́wọ́,
ó ń sọ fún arakunrin rẹ̀ pé, ‘Ṣara gírí.’
7Agbẹ́gilére ń gba alágbẹ̀dẹ wúrà níyànjú
ẹni tí ń fi òòlù lu irin ń kí ẹni tí ń dán irin tí wọ́n ti rọ,
Ó ń wí pé: ‘Òjé tí a fi jó o dára.’
Wọ́n kàn án ní ìṣó,
ó le dáradára, kò le mì.
8“Ìwọ ní tìrẹ, Israẹli iranṣẹ mi,#2Kron 20:7; Jak 2:23
Jakọbu, ìwọ tí mo ti yàn,
ọmọ bíbí inú Abrahamu, ọ̀rẹ́ mi.
9Ìwọ tí mo mú wá láti òpin ayé,
tí mo pè láti ìkangun ayé tí ó jìnnà jùlọ,
mo wí fún ọ pé, ‘Iranṣẹ mi ni ọ́,
mo ti yàn ọ́, n kò ní ta ọ́ nù.’
10Má bẹ̀rù, nítorí mo wà pẹlu rẹ,
má fòyà, nítorí èmi ni Ọlọrun rẹ.
N óo fún ọ ní agbára, n óo sì ràn ọ́ lọ́wọ́;
ọwọ́ ọ̀tún mi, ọwọ́ ìṣẹ́gun, ni n óo fi gbé ọ ró.
11“Gbogbo àwọn tí wọ́n fẹ́ pa ọ́ run
ni n óo dójú tì, wọn óo sì dààmú.
Àwọn tí ń bá ọ jà yóo di asán,
wọn óo sì ṣègbé.
12O óo wá àwọn tí ń bá ọ jà tì,
o kò ní rí wọn.
Àwọn tí ó gbógun tì ọ́
yóo di òfo patapata.
13Nítorí èmi OLUWA Ọlọrun rẹ,
ti di ọwọ́ ọ̀tún rẹ mú,
èmi ni mo sọ fún ọ pé
kí o má bẹ̀rù, n óo ràn ọ́ lọ́wọ́.”
14Ẹ má bẹ̀rù, ẹ̀yin ọmọ Jakọbu,
bí ẹ tilẹ̀ dàbí kòkòrò lásán,
ẹ̀yin ọmọ Israẹli,
OLUWA ní òun óo ràn yín lọ́wọ́.
Ẹni Mímọ́ Israẹli ni Olùràpadà yín.
15Ó ní, “N óo ṣe yín bí ohun èlò ìpakà titun,
tí ó mú, tí ó sì ní eyín,
ẹ óo tẹ àwọn òkè ńlá mọ́lẹ̀, ẹ óo rún wọn wómúwómú;
ẹ óo sì sọ àwọn òkè kéékèèké di fùlùfúlù.
16Ẹ óo fẹ́ wọn bí ọkà, atẹ́gùn yóo gbé wọn lọ,
ìjì yóo sì fọ́n wọn ká.
Ẹ̀yin óo yọ̀ ninu OLUWA
ẹ óo sì ṣògo ninu Ẹni Mímọ́ Israẹli.
17“Nígbà tí àwọn talaka ati àwọn aláìní bá ń wá omi, tí omi kò sí,
tí òùngbẹ ń gbẹ wọ́n, tí ọ̀nà ọ̀fun wọn gbẹ,
èmi OLUWA yóo dá wọn lóhùn,
èmi Ọlọrun Israẹli kò ní fi wọ́n sílẹ̀.
18N óo ṣí odò lórí àwọn òkè,
ati orísun láàrin àwọn àfonífojì;
n óo sọ aṣálẹ̀ di adágún odò,
ilẹ̀ gbígbẹ yóo sì di orísun omi.
19N óo gbin igi kedari sinu aṣálẹ̀,
pẹlu igi akasia ati igi mitili ati igi olifi.
N óo gbin igi sipirẹsi sinu aṣálẹ̀,
n óo gbin igi firi ati pine papọ̀.
20Kí àwọn eniyan lè rí i, kí wọn sì mọ̀,
kí wọ́n rò ó wò, kí òye lè yé wọn papọ̀,
pé ọwọ́ OLUWA ni ó ṣe èyí,
Ẹni Mímọ́ Israẹli ni ó ṣẹ̀dá rẹ̀.”
OLUWA Pe Àwọn Ọlọrun Èké níjà
21OLUWA, Ọba Jakọbu, ní:
“Ẹ̀yin oriṣa àwọn orílẹ̀-èdè, ẹ ro ẹjọ́ yín,
kí ẹ mú ẹ̀rí tí ó dájú wá lórí ohun tí ẹ bá ní sọ.
22Ẹ mú wọn wá,
kí ẹ sì sọ ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ fún wa;
kí ẹ sọ àwọn ohun àtijọ́ fún wa.
Kí á lè gbé wọn yẹ̀wò;
kí á lè mọ àyọrísí wọn,
tabi kí ẹ sọ àwọn ohun tí ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ fún wa.”
23OLUWA ní, “Ẹ sọ ohun tí ń bọ̀ lẹ́yìn ọ̀la fún wa,
kí á lè mọ̀ pé oriṣa ni yín;
ẹ ṣe nǹkan rere tabi nǹkan burúkú kan,
kí á rí i, kí ẹ̀rù sì bà wá.
24Ẹ wò ó! Òfo ni yín, òfo sì ni iṣẹ́ ọwọ́ yín,
ẹni ìríra ni ẹni tí ó bá yàn yín.
25Mo ti gbé ẹnìkan dìde láti ìhà àríwá,
ó sì ti dé.
Láti ìlà oòrùn ni yóo ti pe orúkọ mi;
yóo máa gún àwọn ọba mọ́lẹ̀ bì ìgbà tí wọ́n gún nǹkan ninu odó,
àní, bí ìgbà tí amọ̀kòkò bá ń gún amọ̀.
26Ta ló kéde rẹ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀ wá, kí á lè mọ̀,
ta ló sọ nípa rẹ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀
kí á lè sọ pé, ‘Olóòótọ́ ni?’
Kò sí ẹni tí ó sọ ọ́, kò sí ẹni tí ó kéde rẹ̀;
ẹnìkankan kò gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀.
27Èmi OLUWA ni mo ti kọ́kọ́ sọ fún Sioni,
tí mo sì ròyìn ayọ̀ náà fún Jerusalẹmu.
28Nígbà tí mo wo ààrin àwọn wọnyi, kò sí olùdámọ̀ràn kan,
tí ó lè dá mi lóhùn nígbà tí mo bá ní ìbéèrè.
29Wò ó! Ìtànjẹ lásán ni gbogbo wọn,
òfo ni iṣẹ́ ọwọ́ wọn:
Ẹ̀fúùfù lásán ni àwọn ère tí wọ́n gbẹ́.”
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
AISAYA 41: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010