AISAYA 57

57
OLUWA Dá Ìwà Ìbọ̀rìṣà Israẹli lẹ́bi
1Olódodo ń ṣègbé,
kò sí ẹni tí ó fi ọkàn sí i.
A mú àwọn olótìítọ́ kúrò, kò sì sí ẹni tí ó yé,
pé à ń yọ olódodo kúrò ninu ìdààmú ni.
2Àwọn tí ń rìn ní ọ̀nà òtítọ́, wọn óo wà ní alaafia,
wọn óo máa sinmi lórí ibùsùn wọn.
3Ẹ̀yin ọmọ oṣó wọnyi,
ẹ súnmọ́bí fún ìdájọ́,
ẹ̀yin ọmọ alágbèrè ati panṣaga.
4Ta ni ẹ̀ ń fi ṣe ẹlẹ́yà?
Ta ni ẹ̀ ń ya ẹnu ní ìyàkuyà sí
tí ẹ yọ ṣùtì sí?
Ṣebí ọmọ ẹ̀ṣẹ̀ ni yín
irú ọmọ ẹ̀tàn;
5ẹ̀yin tí ẹ kún fún ìṣekúṣe lábẹ́ igi Oaku,
ati lábẹ́ gbogbo igi eléwé tútù.
Ẹ̀yin tí ẹ̀ ń pa àwọn ọmọ yín láàrin àfonífojì,
ati ní abẹ́ àpáta?
6Àwọn oriṣa láàrin àwọn òkúta ọ̀bọ̀rọ́, ninu àfonífojì,
àwọn ni ẹ̀ ń sìn,
àwọn ni ò ń da ẹbọ ohun mímu lé lórí,
àwọn ni ò ń fi nǹkan jíjẹ rúbọ sí.
Ṣé àwọn nǹkan wọnyi ni yóo mú kí inú mi yọ́?
7Lórí òkè gíga fíofío, ni o lọ tẹ́ ibùsùn rẹ sí
níbẹ̀ ni o tí ń lọ rú ẹbọ.
8O gbé ère oriṣa kalẹ̀ sí ẹ̀yìn ìlẹ̀kùn ati ẹ̀yìn òpó ìlẹ̀kùn.
O kọ̀ mí sílẹ̀, o bọ́ sórí ibùsùn, o tẹ́ ibùsùn tí ó fẹ̀.
O wá bá àwọn tí ó wù ọ́ da ọ̀rọ̀ pọ̀,
ẹ̀ ń bá ara yín lòpọ̀.
9O gbọ̀nà, o lọ gbé òróró fún oriṣa Moleki,
o kó ọpọlọpọ turari lọ,
o rán àwọn ikọ̀ lọ sí ilẹ̀ òkèèrè,
o sì ranṣẹ lọ sinu isà òkú pẹlu.
10Àárẹ̀ mú ọ nítorí ìrìn àjò rẹ jìnnà,
sibẹsibẹ o kò sọ fún ara rẹ pé, “Asán ni ìrìn àjò yìí.”
Ò ń wá agbára kún agbára,
nítorí náà àárẹ̀ kò mú ọ.
11Ta ni ń já ọ láyà,
tí ẹ̀rù rẹ̀ bà ọ́, tí o fi purọ́;
tí o kò ranti mi, tí o kò sì ronú nípa mi?
Ṣé nítorí mo ti dákẹ́ fún ìgbà pípẹ́,
ni o kò fi bẹ̀rù mi?
12N óo sọ nípa òdodo rẹ ati iṣẹ́ ọwọ́ rẹ,
ṣugbọn wọn kò ní lè ràn ọ́ lọ́wọ́.
13Nígbà tí o bá kígbe,
kí àwọn ère tí o kó jọ gbà ọ́.
Atẹ́gùn lásán ni yóo gbé gbogbo wọn lọ
Afẹ́fẹ́ ni yóo fẹ́ wọn lọ.
Ṣugbọn ẹni tí ó bá sá di mí,
ni yóo ni ilẹ̀ náà,
òun ni yóo sì jogún òkè mímọ́ mi.
Ọlọrun Ṣe Ìlérí Ìrànlọ́wọ́ ati Ìwòsàn
14OLUWA ní, “Ẹ la ọ̀nà, ẹ la ọ̀nà, ẹ tún ọ̀nà ṣe,
ẹ mú gbogbo ohun ìkọsẹ̀ kúrò lọ́nà àwọn eniyan mi.”
15Nítorí Ẹni Gíga, tí ó ga jùlọ,
ẹni tí ń gbé ninu ayérayé, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Mímọ́:
òun ni ó ní, “Ibi gíga ati mímọ́ ni mò ń gbé lóòótọ́,
ṣugbọn mo wà pẹlu àwọn oníròbìnújẹ́ ọkàn ati àwọn onírẹ̀lẹ̀.
Láti sọ ọkàn wọn jí.
16Nítorí n kò ní máa jà títí ayé,
tabi kí n máa bínú nígbà gbogbo:
nítorí láti ọ̀dọ̀ mi ni ẹ̀mí ti ń jáde,
Èmi ni mo dá èémí ìyè.
17Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ojúkòkòrò rẹ̀, inú bí mi,
mo jẹ ẹ́ níyà, mo fojú pamọ́, inú sì bí mi;
sibẹ ó túbọ̀ ń ṣìnà sí i ni, ó ń ṣe tinú rẹ̀.
18Mo ti rí bí ó ti ń ṣe,
ṣugbọn n óo ṣì wò ó sàn;
n óo máa darí rẹ̀, n óo tù ú ninu,
n óo sì fún àwọn tí ó bá ń ṣọ̀fọ̀ ní Israẹli ní orin ayọ̀.
19Alaafia ni, alaafia ni fún àwọn tí ó wà ní òkèèrè,#Efe 2:17
ati àwọn tí ó wà nítòsí;
n óo sì wò wọ́n sàn.
20Ṣugbọn àwọn eniyan burúkú dàbí ríru omi òkun,
nítorí òkun kò lè sinmi,
omi rẹ̀ a sì máa rú pàǹtí ati ẹrẹ̀ sókè.
21Kò sí alaafia fún àwọn eniyan burúkú.”#Ais 48:22
Ọlọrun mi ló sọ bẹ́ẹ̀.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

AISAYA 57: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀