AISAYA 58

58
Ààwẹ̀ Tòótọ́
1“Kígbe sókè, má dákẹ́,
ké sókè bíi fèrè ogun,
sọ ìrékọjá àwọn eniyan mi fún wọn ní àsọyé,
sọ ẹ̀ṣẹ̀ ilé Jakọbu fún wọn.
2Nítòótọ́ ni wọ́n ń wá mi lojoojumọ,
wọ́n sì fẹ́ mọ ìlànà mi,
wọ́n ṣe bí orílẹ̀-èdè tí ó mọ òdodo,
tí kò kọ òfin Ọlọrun wọn sílẹ̀.
Wọ́n ń bèèrè ìdájọ́ òdodo lọ́dọ̀ mi,
wọ́n ní ìfẹ́ ati súnmọ́ Ọlọrun.”
3Wọ́n ń bèèrè pé, “Kí ló dé tí à ń gbààwẹ̀, ṣugbọn tí OLUWA kò rí wa?
Tí à ń fìyà jẹ ara wa, ṣugbọn tí kò náání wa?”
OLUWA wí pé,
“Ìdí rẹ̀ ni pé,
nígbà tí ẹ bá ń gbààwẹ̀, ẹ̀ máa ṣe ìfẹ́ ọkàn yín.
Ẹ̀ sì máa ni gbogbo àwọn òṣìṣẹ́ yín lára.
4Ẹ̀ ń kún fún ìjà ati asọ̀ ní àkókò ààwẹ̀ yín,
ẹ̀ ń lu ara yín ní ìlù ìkà.
Irú ààwẹ̀ tí ẹ̀ ń gbà yìí kò ní jẹ́ kí Ọlọrun gbọ́ ohùn yín lọ́run.
5Ṣé irú ààwẹ̀ tí mo yàn nìyí, ọjọ́ tí eniyan yóo rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ lásán?
Ṣé kí eniyan lè doríkodò bíi koríko etí odò nìkan ni?
Tabi kí ó lè jókòó lórí aṣọ ọ̀fọ̀ ati eérú nìkan?
Ṣé èyí ni ẹ̀ ń pè ní ààwẹ̀, ati ọjọ́ tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ OLUWA?
6“Ṣebí irú ààwẹ̀ tí mo yàn ni pé:
kí á tú ìdè ìwà burúkú,
kí á yọ irin tí a fi di igi àjàgà;
kí á dá àwọn tí ìyà ń jẹ sílẹ̀ lọ́fẹ̀ẹ́,
kí á já gbogbo àjàgà?
7Àní kí ẹ fún ẹni tí ebi ń pa ní oúnjẹ,#Mat 25:34
kí ẹ mú àwọn òtòṣì aláìnílé wá sinu ilé yín,
bí ẹ bá rí ẹnikẹ́ni ní ìhòòhò, kí ẹ fi aṣọ bò ó,
kí ẹ má sì fojú pamọ́ fún ẹni tí ó jẹ́ ẹbí yín.
8“Nígbà náà ni ìmọ́lẹ̀ yín yóo tàn bí ìgbà tí ilẹ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ mọ́,
ara yín yóo sì tètè yá.
Òdodo yín yóo máa tàn níwájú yín.
Ògo mi yóo ṣe ààbò lẹ́yìn yín.
9Ẹ óo ké pè mí nígbà náà,
n óo sì da yín lóhùn.
Ẹ óo kígbe pè mí,
n óo sì dáhùn pé, ‘Èmi nìyí.’
“Bí ẹ bá mú àjàgà kúrò láàrin yín,
tí ẹ kò fi ìka gún ara yín nímú mọ́,
tí ẹ kò sì sọ ọ̀rọ̀ ibi mọ́.
10Bí ẹ bá ṣe làálàá láti fún ẹni tí ebi ń pa ní oúnjẹ,
tí ẹ sì wá ọ̀nà ìtẹ́lọ́rùn fún ẹni tí ìyà ń jẹ,
ìmọ́lẹ̀ yín yóo tàn ninu òkùnkùn,
òkùnkùn biribiri yín yóo dàbí ọ̀sán.
11N óo máa tọ yín sọ́nà nígbà gbogbo,
n óo fi nǹkan rere tẹ yín lọ́rùn;
n óo mú kí egungun yín ó le,
ẹ óo sì dàbí ọgbà tí à ń bomi rin,
ati bí orísun omi, tí omi rẹ̀ kì í gbẹ.
12Ẹ óo tún odi yín tí ó ti wó lulẹ̀ mọ,
ẹ óo sì gbé àwọn ìpilẹ̀ṣẹ̀ àtijọ́ dìde.
Àwọn eniyan yóo máa pè yín ní alátùn-únṣe ibi tí odi ti wó,
alátùn-únṣe òpópónà àdúgbò fún gbígbé.
Èrè Pípa Ọjọ́ Ìsinmi mọ́
13“Bí ẹ bá dẹ́kun láti máa ba ọjọ́ ìsinmi jẹ́,
tí ẹ kò sì máa ṣe ìfẹ́ inú yín lọ́jọ́ mímọ́ mi;
bí ẹ bá pe ọjọ́ ìsinmi ní ọjọ́ ìdùnnú,
tí ẹ pe ọjọ́ mímọ́ OLUWA ní ọjọ́ ológo;
bí ẹ bá yẹ́ ẹ sí, tí ẹ kò yà sí ọ̀nà tiyín,
tí ẹ kò máa ṣe ìfẹ́ inú ara yín,
tabi kí ẹ máa sọ̀rọ̀ àhesọ;
14nígbà náà ni inú yín yóo máa dùn láti sin èmi OLUWA,
n óo gbe yín gun orí òkè ilẹ̀ ayé,
n óo sì mu yín jogún Jakọbu, baba ńlá yín.
Èmi OLUWA ni ó sọ bẹ́ẹ̀.”

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

AISAYA 58: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀