AISAYA 9

9
Ọba Lọ́la
1Ṣugbọn kò ní sí ìṣúdudu fún ẹni tí ó wà ninu ìnira. Ní ìgbà àtijọ́, ó sọ ilẹ̀ Sebuluni ati ilẹ̀ Nafutali di yẹpẹrẹ, ṣugbọn nígbà ìkẹyìn yóo ṣe ilẹ̀ àwọn tí ó ń gbé apá ọ̀nà òkun lógo, títí lọ dé òdìkejì odò Jọdani, ati Galili níbi tí àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè mìíràn ń gbé.#Mat 4:15
2Àwọn tí ń rìn ninu òkùnkùn ti rí ìmọ́lẹ̀ ńlá.#Mat 4:16
Ìmọ́lẹ̀ sì ti tàn sí àwọn tí ń gbé ninu òkùnkùn biribiri.
3Ó ti bukun orílẹ̀-èdè náà.
Ó ti fi kún ayọ̀ wọn;
wọ́n ń yọ̀ níwájú rẹ̀, bí ayọ̀ ìgbà ìkórè.
Bí inú àwọn eniyan ti máa ń dùn nígbà tí wọ́n bá ń pín ìkógun.
4Nítorí pé ó ti ṣẹ́ àjàgà tí ó wọ̀ wọ́n lọ́rùn,
ati ọ̀pá tí wọn fí ń ru ẹrù sí èjìká,
ati kùmọ̀ àwọn tí ń fìyà jẹ wọ́n.
Ó ti ṣẹ́ wọn, bí ìgbà tí ó ṣẹ́ ti àwọn ará Midiani.
5Gbogbo bàtà àwọn ológun, tí ń kilẹ̀ lójú ogun,
ati gbogbo ẹ̀wù tí wọ́n ti yí mọ́lẹ̀ ninu ẹ̀jẹ̀ ni a óo dáná sun,
iná yóo sì jó wọn run.
6Nítorí a bí ọmọ kan fún wa,
a fún wa ní ọmọkunrin kan.
Òun ni yóo jọba lórí wa.
A óo máa pè é ní Ìyanu, Olùdámọ̀ràn,
Ọlọrun alágbára, Baba ayérayé,
Ọmọ-Aládé alaafia.
7Ìjọba rẹ̀ yóo máa tóbi sí i,#Luk 1:32-33
alaafia kò sì ní lópin ní ìjọba rẹ̀ lórí ìtẹ́ Dafidi.
Yóo fìdí rẹ̀ múlẹ̀,
yóo sì gbé e ró pẹlu ẹ̀tọ́ ati òdodo,
láti ìgbà yìí lọ, títí ayérayé.
Ìtara OLUWA àwọn ọmọ ogun ni yóo ṣe èyí
OLUWA yóo Jẹ Israẹli Níyà
8OLUWA ranṣẹ ìdájọ́ sí Jakọbu,
àní, sórí àwọn ọmọ Israẹli.
9Gbogbo eniyan ni yóo mọ̀,
àwọn ará Efuraimu ati àwọn ará Samaria,
àwọn tí wọn ń fọ́nnu pẹlu ìgbéraga pé:
10Ṣé bíríkì ni wọ́n fi kọ́ àwọn ilé tí ó wó lulẹ̀?
Òkúta gbígbẹ́ ni a óo fi tún wọn kọ́.
Igi sikamore ni a fi kọ́ èyí tí wọ́n dà wó,
ṣugbọn igi kedari dáradára ni a óo lò dípò wọn.
11Nítorí náà OLUWA ti gbé ọ̀tá dìde sí wọn:
Ó ti rú àwọn ọ̀tá wọn sókè sí wọn:
12Àwọn ará Siria láti ìhà ìlà oòrùn,
ati àwọn ará Filistia láti ìhà ìwọ̀ oòrùn;
wọn óo gbé Israẹli mì.
Sibẹsibẹ inú OLUWA kò rọ̀,
bẹ́ẹ̀ ni kò dá ọwọ́ ìjà rẹ̀ dúró.
13Sibẹsibẹ àwọn ọmọ Israẹli kò pada sí ọ̀dọ̀ ẹni tí ó jẹ wọ́n níyà,
bẹ́ẹ̀ ni wọn kò wá OLUWA àwọn ọmọ-ogun.
14Nítorí náà, OLUWA yóo fi ìyà jẹ Israẹli.
Ní ọjọ́ kan ṣoṣo, yóo gé Israẹli lórí ati nírù.
15Àwọn àgbààgbà ati àwọn ọlọ́lá wọn ni orí,
àwọn wolii tí ń kọ́ àwọn eniyan ní ẹ̀kọ́ èké sì ni ìrù
16Àwọn tí ń darí àwọn eniyan wọnyi ń ṣì wọ́n lọ́nà ni,
àwọn tí wọn ń tọ́ sọ́nà sì ń já sinu ìparun.
17Nítorí náà, OLUWA kò láyọ̀ lórí àwọn ọdọmọkunrin wọn,
àánú àwọn aláìníbaba ati àwọn opó wọn kò sì ṣe é
nítorí pé aṣebi ni gbogbo wọn, wọn kò sì mọ Ọlọrun,
ọ̀rọ̀ burúkú ni wọ́n sì ń fi ẹnu wọn sọ.
Sibẹsibẹ inú OLUWA kò rọ̀,
bẹ́ẹ̀ ni kò dá ọwọ́ ìjà rẹ̀ dúró.
18Ìwà burúkú wọn ń jó bí iná,
tí ń jó ẹ̀gún wẹ́wẹ́ ati ẹ̀gún ọ̀gàn.
Ó ń jó bíi igbó ńlá, ó sì ń yọ èéfín sókè lálá.
19Nítorí ibinu OLUWA àwọn ọmọ ogun, ilẹ̀ náà jóná,
àwọn eniyan ibẹ̀ dàbí èpò tí a dà sinu iná
ẹnikẹ́ni kò sì dá ẹnìkejì rẹ̀ sí.
20Wọ́n ń já nǹkan gbà lọ́tùn-ún, wọ́n ń jẹ ẹ́,
sibẹ ebi ń pa wọ́n.
Wọ́n ń jẹ àjẹrun lósì,
sibẹ wọn kò yó,
àwọn eniyan sì ń pa ara wọn jẹ.
21Àwọn ará Manase ń bá àwọn ará Efuraimu jà,
bẹ́ẹ̀ ni àwọn ará Efuraimu náà ń bá àwọn ará Manase jà.
Àwọn mejeeji wá dojú ìjà kọ Juda.
Sibẹsibẹ inú OLUWA kò rọ̀,
bẹ́ẹ̀ ni kò dáwọ́ ìjà rẹ̀ dúró.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

AISAYA 9: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀