ÀWỌN ADÁJỌ́ 12
12
Jẹfuta ati Àwọn Ará Efuraimu
1Àwọn ọmọ Efuraimu múra ogun, wọ́n ré odò Jọdani kọjá lọ sí Safoni. Wọ́n bi Jẹfuta léèrè pé, “Kí ló dé tí o fi rékọjá lọ sí òdìkejì láti bá àwọn ará Amoni jagun tí o kò sì pè wá pé kí á bá ọ lọ? Jíjó ni a óo jó ilé mọ́ ọ lórí.”
2Jẹfuta bá dá wọn lóhùn, ó ní, “Nígbà kan tí ogun bẹ́ sílẹ̀ láàrin àwọn ará Amoni ati èmi pẹlu àwọn eniyan mi, tí mo ranṣẹ pè yín, ẹ kò gbà wá sílẹ̀ lọ́wọ́ wọn. 3Mo sì ti mọ̀ pé ẹ kò tún ní gbà wá sílẹ̀, ni mo ṣe fi ẹ̀mí mi wéwu, tí mo sì kọjá sí òdìkejì lọ́dọ̀ àwọn ará Amoni; OLUWA sì fún mi ní ìṣẹ́gun lórí wọn. Kí ló wá dé tí ẹ fi dìde sí mi lónìí láti bá mi jà?” 4Jẹfuta bá kó gbogbo àwọn ọkunrin Gileadi jọ, wọ́n gbógun ti àwọn ará Efuraimu, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí pa wọ́n, nítorí pé àwọn ará Efuraimu pe àwọn ará Gileadi ní ìsáǹsá Efuraimu, tí ó wà láàrin ẹ̀yà Efuraimu ati ẹ̀yà Manase. 5Àwọn ará Gileadi gba àwọn ipadò odò Jọdani lọ́wọ́ àwọn ará Efuraimu. Nígbà tí ìsáǹsá ará Efuraimu kan bá ń sá bọ̀, tí ó bá sọ fún àwọn ará Gileadi pé, “Ẹ jẹ́ kí n rékọjá.” Àwọn ará Gileadi á bi í pé, “Ǹjẹ́ ará Efuraimu ni ọ́?” Bí ó bá sọ pé, “Rárá,” 6wọn á ní kí ó pe, “Ṣiboleti.” Tí kò bá le pè é dáradára, tí ó bá wí pé, “Siboleti,” wọn á kì í mọ́lẹ̀, wọn á sì pa á létí odò Jọdani náà. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe pa ọ̀kẹ́ meji ati ẹgbaa (42,000) eniyan, ninu àwọn ará Efuraimu ní ọjọ́ náà.
7Jẹfuta ṣe aṣiwaju ní ilẹ̀ Israẹli fún ọdún mẹfa. Nígbà tí ó ṣaláìsí, wọ́n sin ín sí Gileadi, ìlú rẹ̀.
Ibisani, Eloni ati Abidoni
8Lẹ́yìn Jẹfuta, Ibisani ará Bẹtilẹhẹmu ni aṣiwaju ní ilẹ̀ Israẹli. 9Ó bí ọmọkunrin mejilelọgbọn, ó sì ní ọgbọ̀n ọmọbinrin. Ó fi àwọn ọmọ rẹ̀ obinrin fọ́kọ láàrin àwọn tí wọn kì í ṣe ìbátan rẹ̀, ó sì fẹ́ ọgbọ̀n ọmọbinrin láti inú ẹ̀yà mìíràn wá fún àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin. Ó jẹ́ aṣiwaju ní Israẹli fún ọdún meje. 10Nígbà tí Ibisani ṣaláìsí, wọ́n sin ín sí Bẹtilẹhẹmu.
11Lẹ́yìn Ibisani, Eloni, láti inú ẹ̀yà Sebuluni, jẹ́ aṣiwaju ní ilẹ̀ Israẹli fún ọdún mẹ́wàá. 12Nígbà tí Eloni ṣaláìsí, wọ́n sin ín sí Aijaloni ní ilẹ̀ Sebuluni.
13Lẹ́yìn rẹ̀, Abidoni, ọmọ Hileli, ará Piratoni, jẹ́ aṣiwaju ní ilẹ̀ Israẹli. 14Ó ní ogoji ọmọkunrin ati ọgbọ̀n ọmọ ọmọ lọkunrin, tí wọn ń gun aadọrin kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́. Ó jẹ́ aṣiwaju ní ilẹ̀ Israẹli fún ọdún mẹjọ. 15Lẹ́yìn náà, Abidoni ọmọ Hileli ará Piratoni ṣaláìsí, wọ́n sì sin ín sí Piratoni, ní ilẹ̀ Efuraimu, ní agbègbè olókè àwọn ará Amaleki.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
ÀWỌN ADÁJỌ́ 12: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010