ÀWỌN ADÁJỌ́ 17

17
Ère Mika
1Ọkunrin kan wà ní agbègbè olókè ti Efuraimu tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Mika. 2Ó sọ fún ìyá rẹ̀ pé, “Wọ́n gbé ẹẹdẹgbẹfa (1,100) owó fadaka mọ́ ọ lọ́wọ́ nígbà kan, mo sì gbọ́ tí ò ń gbé ẹni tí ó gbé owó náà ṣépè, ọwọ́ mi ni owó náà wà, èmi ni mo gbé e.”
Ìyá rẹ̀ dá a lóhùn pé, “OLUWA yóo bukun ọ, ọmọ mi.” 3Mika gbé ẹẹdẹgbẹfa (1,100) owó fadaka náà pada fún ìyá rẹ̀.
Ìyá rẹ̀ bá dáhùn pé, “Mo ya fadaka náà sí mímọ́ fún OLUWA, kí ọmọ mi yá ère fínfín kan kí ó sì yọ́ fadaka náà lé e lórí. Nítorí náà, n óo dá a pada fún ọ.” 4Nígbà tí Mika kó owó náà fún ìyá rẹ̀, ìyá rẹ̀ mú igba owó fadaka ninu rẹ̀, ó kó o fún alágbẹ̀dẹ fadaka láti yọ́ ọ sórí ère náà, wọ́n sì gbé ère náà sí ilé Mika.
5Mika ní ojúbọ kan fún ara rẹ̀, ó dá ẹ̀wù funfun kan, ó sì ṣe àwọn ère kéékèèké. Ó fi ọ̀kan ninu àwọn ọmọ rẹ̀ ṣe alufaa oriṣa rẹ̀. 6Kò sí ọba ní ilẹ̀ Israẹli ní gbogbo àkókò náà, nítorí náà ohun tí ó bá tọ́ lójú olukuluku ni olukuluku ń ṣe.#A. Ada 21:25
7Ọdọmọkunrin kan wà ní Juda, ará Bẹtilẹhẹmu, tí ó jẹ́ ọmọ Lefi láti inú ìdílé Juda, ó ń gbé ibẹ̀. 8Ọdọmọkunrin náà kó kúrò ní Bẹtilẹhẹmu ní ilẹ̀ Juda, láti lọ máa gbé ibikíbi tí ó bá ti rí ààyè. Bí ó ti ń lọ, ó dé ilé Mika ní agbègbè olókè ti Efuraimu. 9Mika bá bi í pé, “Níbo ni o ti ń bọ̀?”
Ó dá a lóhùn pé, “Ọmọ Lefi, láti Bẹtilẹhẹmu ní ilẹ̀ Juda ni mí, ibi tí n óo máa gbé ni mò ń wá kiri.”
10Mika bá sọ fún un pè, “Máa gbé ọ̀dọ̀ mi, kí o sì jẹ́ baba ati alufaa fún mi, n óo máa san owó fadaka mẹ́wàá fún ọ lọ́dún. N óo máa dáṣọ fún ọ, n óo sì máa bọ́ ọ.” 11Ọdọmọkunrin ọmọ Lefi náà gbà, láti máa gbé ọ̀dọ̀ Mika. Mika sì mú un gẹ́gẹ́ bí ọmọ. 12Mika fi ọdọmọkunrin náà jẹ alufaa, ó sì ń gbé ilé Mika. 13Mika bá dáhùn pé, “Mo mọ̀ nisinsinyii pé OLUWA yóo bukun mi, nítorí pé, ọmọ Lefi gan-an ni mo gbà gẹ́gẹ́ bí alufaa.”

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

ÀWỌN ADÁJỌ́ 17: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀