JOHANU 18:25-27

JOHANU 18:25-27 YCE

Simoni Peteru wà níbi tí ó dúró, tí ó ń yáná. Wọ́n sọ fún un pé, “Ṣé kì í ṣe pé ọ̀kan ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ni ọ́?” Ó sẹ́, ó ní, “Rárá o!” Ọ̀kan ninu àwọn ẹrú Olórí Alufaa, tí ó jẹ́ ẹbí ẹni tí Peteru gé létí bi Peteru pé, “Ǹjẹ́ n kò rí ọ ninu ọgbà pẹlu rẹ̀?” Peteru tún sẹ́. Lẹsẹkẹsẹ àkùkọ kan bá kọ.