JOBU 16
16
1Jobu bá dáhùn pé,
2“Èmi náà ti gbọ́ irú nǹkan wọnyi rí,
ọlọ́rọ̀ ìtùnú kòbákùngbé ni gbogbo yín.
3Ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ asán tí ẹ̀ ń sọ yìí tilẹ̀ lópin?
Àbí, kí ní ń fa gbogbo àríyànjiyàn yìí?
4Bí ẹ bá wà ní ipò mi,
èmi náà lè sọ̀rọ̀ bí ẹ tí ń sọ̀rọ̀ yìí,
kí n da ọ̀rọ̀ bò yín,
kí n sì máa mi orí si yín.
5Mo lè fi ọ̀rọ̀ ẹnu mi fun yín lókun,
kí ọ̀rọ̀ ìtùnú mi sì mú kí ara tù yín.
6“Bí mo sọ̀rọ̀, ọ̀rọ̀ kò mú kí ara tù mí,
bí mo bá sì dákẹ́, ṣé dídákẹ́ lè tán ìrora mi?
7Dájúdájú Ọlọrun ti dá mi lágara,
ó ti sọ gbogbo ilé mi di ahoro.
8Híhunjọ tí ara mi hunjọ, jẹ́ ẹ̀rí láti ta kò mí;
rírù tí mo rù ta àbùkù mi,
ó sì hàn lójú mi.
9Ó ti fi ibinu fà mí ya,
ó sì kórìíra mi;
ó pa eyín keke sí mi;
ọ̀tá mi sì ń fojú burúkú wò mí.
10Àwọn eniyan ń fi mí ṣe ẹlẹ́yà,
wọ́n ń gbá mi létí,
wọ́n kó ara wọn jọ sí mi.
11Ọlọrun fà mí lé eniyan burúkú lọ́wọ́,
ó mú kí n ṣubú sí ọwọ́ àwọn ìkà.
12Nígbà tí ó dára fún mi,
ó fi ẹ̀yìn mi wọ́nlẹ̀,
ó fún mi lọ́rùn, ó gbé mi ṣánlẹ̀,
ó sì gbọ̀n mí yẹ́bẹ́yẹ́bẹ́;
ó yàn mí sọjú bí àmì ìtafà sí.
13Àwọn tafàtafà rẹ̀ yí mi ká,
ó la kíndìnrín mi láìṣàánú mi,
ó sì tú òróòro mi jáde.
14Ó ń gbógun tì mí nígbà gbogbo,
ó pakuuru sí mi bí ọmọ ogun.
15“Mo fi aṣọ ọ̀fọ̀ bo ara,
mo sùn gbalaja sinu erùpẹ̀.
16Mo sọkún títí ojú mi fi pọ́n,
omijé sì mú kí ojú mi ṣókùnkùn,
17bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé n kò ṣe ibi,
adura mi sì mọ́.
18“Ìwọ ilẹ̀, má ṣe bo ẹ̀jẹ̀ mi mọ́lẹ̀,
má sì jẹ́ kí igbe mi já sí òfo.
19Nisinsinyii, ẹlẹ́rìí mi ń bẹ lọ́run,
alágbàwí mi sì ń bẹ lókè.
20Àwọn ọ̀rẹ́ mi ń fi mí ṣe ẹlẹ́yà,
mo sì ń sọkún sí Ọlọrun,
21ìbá ṣe pé ẹnìkan lè ṣe alágbàwí fún ẹnìkejì lọ́dọ̀ Ọlọrun,
bí eniyan ti lè ṣe alágbàwí fún ẹnìkejì rẹ̀ níwájú eniyan.
22Lẹ́yìn ọdún díẹ̀ sí i,
n óo lọ àjò àrèmabọ̀.#Job 19:25
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
JOBU 16: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010