JOBU 2
2
Satani Tún Dán Jobu Wò
1Nígbà tí ó tún yá tí àwọn ọmọ Ọlọrun wá farahàn níwájú OLUWA, Satani náà wà láàrin wọn. 2OLUWA tún bi Satani pé, “Níbo ni o ti ń bọ̀?”
Satani dá OLUWA lóhùn pé, “Mò ń lọ sókè sódò káàkiri gbogbo ayé.”
3Ọlọrun tún bi í pé, “Ǹjẹ́ o ṣàkíyèsí Jobu, iranṣẹ mi, pé kò sí olóòótọ́ ati eniyan rere bíi rẹ̀ ní gbogbo ayé. Ó bẹ̀rù OLUWA, ó sì kórìíra ìwà burúkú, ó dúró ṣinṣin ninu ìwà òtítọ́ rẹ̀ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé o dẹ mí sí i láti pa á run láìnídìí.”
4Satani dá OLUWA lóhùn pé, “Ohun gbogbo ni eniyan lè fi sílẹ̀ láti gba ẹ̀mí rẹ̀ là. 5Ìwọ fi ọwọ́ kan ara ati eegun rẹ̀ wò, bí kò bá ní sọ̀rọ̀ àfojúdi sí ọ lójú ara rẹ.”
6OLUWA bá ní, “Ó wà ní ìkáwọ́ rẹ, ṣugbọn o kò gbọdọ̀ fọwọ́ kan ẹ̀mí rẹ̀.”
7Satani bá lọ kúrò níwájú OLUWA, ó sì da oówo bo Jobu lára, láti àtẹ́lẹsẹ̀ títí dé orí. 8Jobu ń fi àpáàdì họ ara, ó sì jókòó sinu eérú. 9Iyawo Jobu bá sọ fún un pé, “Orí òtítọ́ inú rẹ ni o tún wà sibẹ? Fi Ọlọrun bú, kí o kú.”
10Ṣugbọn ó dáhùn pé, “Ò ń sọ̀rọ̀ bí ìgbà tí ọ̀kan ninu àwọn aláìmòye obinrin bá ń sọ̀rọ̀. Ǹjẹ́ eniyan lè gba ire lọ́wọ́ Ọlọrun kí ó má gba ibi?” Ninu gbogbo nǹkan wọnyi, Jobu kò dẹ́ṣẹ̀ rárá ninu ọ̀rọ̀ tí ó sọ.
Àwọn Ọ̀rẹ́ Jobu Wá
11Nígbà tí Elifasi ará Temani, Bilidadi ará Ṣuha ati Sofari ará Naama, àwọn ọ̀rẹ́ Jobu mẹta, gbọ́ nípa ìyọnu tí ó dé bá Jobu, wọ́n wá láti kí i, ati láti tù ú ninu. 12Nígbà tí wọ́n rí Jobu ní ọ̀ọ́kán, wọn kò mọ̀ ọ́n mọ́. Ṣugbọn nígbà tí wọ́n súnmọ́ ọn tí wọ́n mọ̀ pé òun ni, wọ́n bú sẹ́kún, wọ́n fa aṣọ wọn ya, wọ́n sì ku eruku sórí. 13Wọ́n jókòó ní ilẹ̀ẹ́lẹ̀ pẹlu rẹ̀ fún ọjọ́ meje, tọ̀sán-tòru, láìsọ nǹkankan, nítorí pé wọ́n rí i bí ìrora náà ti pọ̀ tó.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
JOBU 2: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010