JOBU 22
22
ÌFỌ̀RỌ̀WÉRỌ̀ KẸTA
(22:1–27:23)
1Elifasi ará Temani bá dáhùn pé,
2“Ǹjẹ́ eniyan lè wúlò fún Ọlọrun?
Nítòótọ́, bí eniyan tilẹ̀ jẹ́ ọlọ́gbọ́n, ara rẹ̀ ni ó wúlò fún.
3Ǹjẹ́ jíjẹ́ olódodo rẹ̀ ṣe ohun rere kan fún Olodumare,
tabi kí ni èrè rẹ̀ bí ó bá jẹ́ ẹni pípé?
4Ṣé nítorí pé o bẹ̀rù rẹ̀ ni ó ṣe bá ọ wí,
tí ó sì ń dá ọ lẹ́jọ́?
5Ṣebí ìwà ibi rẹ ló pọ̀;
tí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ kò sì lópin?
6O gba nǹkan ìdógò lọ́wọ́ àwọn arakunrin rẹ láìnídìí,
O bọ́ wọn sí ìhòòhò goloto.
7O kò fún aláàárẹ̀ ní omi mu,
o kọ̀ láti fún ẹni tí ebi ń pa ní oúnjẹ.
8Ẹni tí ó lágbára gba ilẹ̀,
ẹni tí ó lọ́lá sì ń gbé inú rẹ̀.
9O lé àwọn opó jáde lọ́wọ́ òfo,
o sì ṣẹ́ aláìní baba lápá.
10Nítorí náà ni okùn dídẹ fi yí ọ ká,
tí jìnnìjìnnì sì bò ọ́ lójijì.
11Ìmọ́lẹ̀ rẹ ti di òkùnkùn, o kò ríran,
ìgbì omi sì bò ọ́ mọ́lẹ̀.#Job 35:6-8
12“Ṣebí Ọlọrun wà lókè ọ̀run
Ó ń wo àwọn ìràwọ̀ nísàlẹ̀
àní àwọn tí wọ́n ga jùlọ,
bí ó ti wù kí wọ́n ga tó!
13Sibẹsibẹ ò ń bèèrè pé, ‘Kí ni Ọlọrun mọ̀?’
Ṣé ó lè ṣe ìdájọ́ láti inú òkùnkùn biribiri?
14Ìkùukùu tí ó nípọn yí i ká,
tóbẹ́ẹ̀ tí kò lè ríran,
ó sì ń rìn ní òfuurufú ojú ọ̀run.
15“Ṣé ọ̀nà àtijọ́ ni ìwọ óo máa tẹ̀lé;
ọ̀nà tí àwọn ẹni ibi rìn?
16A gbá wọn dànù, kí àkókò wọn tó tó,
a ti gbá ìpìlẹ̀ wọn lọ.
17Wọ́n sọ fún Ọlọrun pé,
‘Fi wá sílẹ̀, kí ni ìwọ Olodumare lè fi wá ṣe?’
18Sibẹsibẹ ó fi ìṣúra dáradára kún ilé wọn–
ṣugbọn ìmọ̀ràn ẹni ibi jìnnà sí mi.
19Àwọn olódodo rí i, inú wọn dùn,
àwọn aláìlẹ́bi fi wọ́n rẹ́rìn-ín ẹlẹ́yà,
20wọ́n ń wí pé, ‘Dájúdájú, àwọn ọ̀tá wa ti parun,
iná sì ti jó gbogbo ohun tí wọ́n fi sílẹ̀.’
21“Nisinsinyii gba ti Ọlọrun,
kí o sì wà ní alaafia;
kí ó lè dára fún ọ.
22Gba ìtọ́ni rẹ̀,
kí o sì kó ọ̀rọ̀ rẹ̀ lékàn.
23Bí o bá yipada sí Olodumare, tí o sì rẹ ara rẹ sílẹ̀,
tí o bá mú ìwà aiṣododo kúrò ní ibùgbé rẹ,
24bí o bá ri wúrà mọ́ inú erùpẹ̀,
tí o fi wúrà Ofiri sí ààrin àwọn òkúta ìsàlẹ̀ odò,
25bí Olodumare bá sì jẹ́ wúrà rẹ,
ati fadaka olówó iyebíye rẹ,
26nígbà náà ni o óo láyọ̀ ninu Olodumare,
o óo sì lè dúró níwájú Ọlọrun.
27Nígbà náà, o óo gbadura sí i, yóo sì gbọ́,
o óo sì san ẹ̀jẹ́ rẹ.
28Ohunkohun tí o bá pinnu láti mú ṣe,
yóo ṣeéṣe fún ọ,
ìmọ́lẹ̀ yóo sì tàn sí ọ̀nà rẹ.
29Nítorí Ọlọrun a máa rẹ onigbeeraga sílẹ̀,
a sì máa gba onírẹ̀lẹ̀.
30A máa gba àwọn aláìṣẹ̀,
yóo sì gbà ọ́ là,
nípa ìwà mímọ́ rẹ.”
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
JOBU 22: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010