JOBU 29
29
Ìparí Ọ̀rọ̀ Jobu
1Jobu tún ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ báyìí pé,
2“Ìbá jẹ́ tún rí fún mi, bí ìgbà àtijọ́,
nígbà tí Ọlọrun ń tọ́jú mi;
3nígbà tí ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ ń tàn sí mi lórí,
tí mo kọjá ninu òkùnkùn pẹlu ìmọ́lẹ̀ rẹ̀;
4kí ó tún rí fún mi bí ìgbà tí ara dẹ̀ mí,
nígbà tí ìrẹ́pọ̀ wà láàrin Ọlọrun ati ìdílé mi;
5tí Olodumare wà pẹlu mi,
tí gbogbo àwọn ọmọ mi yí mi ká;
6tí mò ń rí ọpọlọpọ wàrà lára àwọn ẹran ọ̀sìn mi,
ati ọpọlọpọ òróró lára igi olifi tí ń dàgbà láàrin òkúta!
7Nígbà tí mo lọ sí ẹnubodè ìlú,
tí mo jókòó ní gbàgede,
8tí àwọn ọdọmọkunrin bá rí mi, wọn á bìlà sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan,
àwọn àgbà á sì dìde dúró;
9àwọn ìjòyè á dákẹ́ rọ́rọ́,
wọn á fi ọwọ́ bo ẹnu wọn.
10Àwọn olórí á panumọ́,
ahọ́n wọn á lẹ̀ mọ́ wọn lẹ́nu.
11Àwọn tí wọ́n gbọ́ nípa mi, ń pè mí ní ẹni ibukun,
àwọn tí wọ́n rí mi ń kan sáárá sí mi.
12Nítorí pé mò ń ran àwọn aláìní tí ń ké lọ́wọ́,
ati àwọn aláìníbaba tí wọn kò ní olùrànlọ́wọ́.
13Ìre àwọn tí ń kú lọ mọ́ mi,
mo sì mú kí opó kọrin ayọ̀.
14Mo fi òdodo bora bí aṣọ,
ìdájọ́ òtítọ́ dàbí ẹ̀wù ati adé mi.
15Mo jẹ́ ojú fún afọ́jú,
ati ẹsẹ̀ fún arọ.
16Mo jẹ́ baba fún talaka,
mo gba ẹjọ́ àlejò rò.
17Mo ṣẹ́ ẹni ibi lápá,
mo gba ẹni tí ó mú sílẹ̀.
18“Nígbà náà, mo rò pé, n óo gbòó, n óo tọ̀ọ́ láyé,
ati pé inú ilé mi ni n óo sì kú sí.
19Mo ta gbòǹgbò lọ síbi omi,
ìrì sì ń sẹ̀ sí ẹ̀ka mi ní alaalẹ́.
20Ọlá hàn lára mi,
agbára mi sì ń di titun nígbà gbogbo.
21Àwọn eniyan á dákẹ́ jẹ́ẹ́, wọn á farabalẹ̀ gbọ́ tèmi,
wọ́n sì ń gba ìmọ̀ràn mi pẹlu.
22Lẹ́yìn tí mo bá ti sọ̀rọ̀ tán,
ẹnikẹ́ni kì í tún sọ̀rọ̀ mọ́,
ọ̀rọ̀ mi a máa wọ̀ wọ́n lára.
23Wọ́n ń retí mi,
bí ẹni retí òjò àkọ́rọ̀.
24Mo rẹ́rìn-ín sí wọn nígbà tí wọn ń ṣiyèméjì,
wọn kò sì lè kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá mi.
25Mo jókòó bí ọba, mò ń tọ́ wọn sọ́nà,
mo dàbí ọba láàrin àwọn ọmọ ogun rẹ̀,
bí olùtùnú fún oníròbìnújẹ́.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
JOBU 29: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010