JOBU 32

32
Ọ̀rọ̀ Elihu
(32:1–37:24)
1Àwọn ọkunrin mẹtẹẹta náà kò dá Jobu lóhùn mọ́, nítorí pé ó jẹ́ olódodo lójú ara rẹ̀. 2Elihu, ọmọ Barakeli, ará Busi, ní ìdílé Ramu bá bínú sí Jobu, nítorí pé ó dá ara rẹ̀ láre dípò Ọlọrun. 3Ó bínú sí àwọn ọ̀rẹ́ Jobu mẹtẹẹta pẹlu, nítorí pé wọn kò mọ èsì tí wọ́n lè fún Jobu mọ́, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n dá a lẹ́bi. 4Elihu ti fẹ́ bá Jobu sọ̀rọ̀ tẹ́lẹ̀, ṣugbọn ó dákẹ́, nítorí àwọn àgbà tí wọ́n jù ú lọ ni wọ́n ń sọ̀rọ̀. 5Ṣugbọn nígbà tí Elihu rí i pé àwọn mẹtẹẹta kò lè fún Jobu lésì mọ́, inú bí i. 6Ó ní,
“Àgbàlagbà ni yín, ọmọde sì ni mí,
nítorí náà ni ojú fi ń tì mí,
tí ẹ̀rù sì ń bà mí láti sọ èrò ọkàn mi.
7Mo ní kí ẹ̀yin àgbà sọ̀rọ̀,
kí ọ̀rọ̀ yín sì fa ọgbọ́n yọ gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ orí yín.
8Ṣugbọn ẹ̀mí tí ó wà ninu eniyan,
tíí ṣe èémí Olodumare,
ni ó ń fún eniyan ní ìmọ̀.
9Kì í ṣe àwọn àgbà nìkan ni wọ́n gbọ́n,
tabi pé arúgbó nìkan ni ó mọ òye ohun tó tọ́, tó yẹ.
10Nítorí náà, ‘Ẹ fetí sílẹ̀,
kí èmi náà lè sọ èrò ọkàn mi.’
11“Mo farabalẹ̀ nígbà tí ẹ̀yin ń sọ̀rọ̀,
mo fetí sí ọ̀rọ̀ ọgbọ́n yín,
nígbà tí ẹ̀ ń ronú ohun tí ẹ fẹ́ sọ,
12Mo farabalẹ̀ fun yín,
ṣugbọn kò sí ẹnikẹ́ni ninu yín tí ó lè ko Jobu lójú,
kí ó sì fi àṣìṣe rẹ̀ hàn án,
tabi kí ó fún un lésì àwọn àwíjàre rẹ̀.
13Ẹ ṣọ́ra, kí ẹ má baà wí pé, ‘A ti di ọlọ́gbọ́n,
Ọlọrun ló lè ṣe ìdájọ́ rẹ̀, kì í ṣe eniyan.’
14Èmi kọ́ ni Jobu ń bá wí, ẹ̀yin ni,
n kò sì ní dá a lóhùn bí ẹ ṣe dá a lóhùn.
15“Ọkàn wọn dàrú, wọn kò sì lè fèsì mọ́,
bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ní ohun kan láti sọ.
16Ṣé kí n dúró,
nítorí pé wọ́n dúró láìfèsì?
17Èmi náà óo fèsì lé e,
n óo sì sọ èrò ọkàn tèmi.
18Mo ní ọ̀rọ̀ pupọ láti sọ,
Ṣugbọn ẹ̀mí tí ó wà ninu mi ló ń kó mi ní ìjánu.
19Ọ̀rọ̀ kún inú mi bí ọtí inú ìgò,
ó fẹ́ ru síta bí ọtí inú ìgò aláwọ.
20Mo níláti sọ̀rọ̀ kí ara lè rọ̀ mí,
mo gbọdọ̀ la ẹnu mi kí n sì dáhùn.
21N kò ní ṣe ojuṣaaju ẹnikẹ́ni,
bẹ́ẹ̀ ni n kò sì ní gbèjà eniyan.
22Nítorí n kò mọ bí wọ́n ṣe ń pọ́n eniyan,
kí Ẹlẹ́dàá mi má baà pa mí run ní kíá.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

JOBU 32: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀