JOBU 37

37
1“Nígbà tí mo gbọ́, ọkàn mi wárìrì,
ó sì fò sókè ní ipò rẹ̀.
2Gbọ́ ohùn rẹ̀ tí ń dún bí ààrá,
ati ariwo tí ń ti ẹnu rẹ̀ jáde.
3Ó rán mànàmáná rẹ̀ sí wọn jákèjádò ojú ọ̀run,
títí dé òpin ilẹ̀ ayé.
4Lẹ́yìn náà, a gbọ́ ìró ohùn rẹ̀,
ó sọ̀rọ̀ ninu ọlá ńlá rẹ̀,
bí ìgbà tí ààrá bá sán,
sibẹsibẹ kò dá mànàmáná dúró
bí àwọn eniyan ti ń gbóhùn rẹ̀.
5Ohùn Ọlọrun dún bí ààrá tìyanu-tìyanu,
a kò lè rí ìdí iṣẹ́ ìyanu rẹ̀.
6Ó pàṣẹ pé kí yìnyín rọ̀ sórí ilẹ̀,
bẹ́ẹ̀ náà ni òjò wẹliwẹli,
ati ọ̀wààrà òjò.
7Ó ká gbogbo eniyan lọ́wọ́ iṣẹ́ kò,
kí wọ́n lè mọ iṣẹ́ rẹ̀.
8Àwọn ẹranko wọ ihò wọn lọ,
wọ́n dákẹ́ sibẹ, wọ́n sá pamọ́.
9Ìjì líle fẹ́ jáde láti inú yàrá rẹ̀,
òtútù sì mú wá láti inú afẹ́fẹ́ tí ń fẹ́.
10Yìnyín ti inú èémí Ọlọrun wá,
gbogbo omi inú odò sì dì.
11Ó fi omi kún inú ìkùukùu,
ìkùukùu sì fọ́n mànàmáná rẹ̀ ká.
12Wọ́n ń yípo lábẹ́ ìtọ́ni rẹ̀,
láti mú gbogbo àṣẹ tí ó pa ṣẹ, lórí ilẹ̀ alààyè.
13Ó mú kí àwọn nǹkan wọnyi ṣẹlẹ̀,
bóyá fún àtúnṣe ni, tabi nítorí ilẹ̀ rẹ̀,
tabi láti fi ìfẹ́ rẹ̀ hàn.
14“Fetí sílẹ̀, ìwọ Jobu,
dúró kí o sì ronú nípa àwọn iṣẹ́ ìyanu Ọlọrun.
15Ǹjẹ́ o mọ bí Ọlọrun ṣe pàṣẹ,
tí ó sì mú kí mànàmáná awọsanma tàn?
16Ǹjẹ́ o mọ̀ bí ó ṣe so awọsanma rọ̀,
iṣẹ́ ìyanu ẹni tí ó pé ní ìmọ̀ ni;
17ìwọ tí ooru mú nígbà tí ayé dákẹ́ rọ́rọ́
nítorí pé afẹ́fẹ́ ìhà gúsù kò fẹ́?
18Ṣé o lè tẹ́ ojú ọ̀run bí ó ti tẹ́ ẹ,
kí ó le, kí ó sì dàbí dígí tí ń dán?
19Kọ́ wa ní ohun tí a lè bá Ọlọrun sọ,
a kò lè kó àròyé wa jọ siwaju rẹ̀,
nítorí àìmọ̀kan wa.
20Ṣé kí n sọ fún Ọlọrun pé n ó bá a sọ̀rọ̀ ni?
Ta ni yóo fẹ́ kí á gbé òun mì?
21“Ẹnikẹ́ni kò lè wo ìmọ́lẹ̀ ojú ọ̀run
nígbà tí ó bá ń tàn ní awọsanma,
nígbà tí afẹ́fẹ́ bá fẹ́ tí ó sì gbá wọn lọ.
22Láti ìhà àríwá ni Ọlọrun ti yọ,
ó fi ọlá ńlá, tí ó bani lẹ́rù, bora bí aṣọ.
23Àwámárìídìí ni Olodumare–
agbára ati ìdájọ́ òtítọ́ rẹ̀ pọ̀,
bẹ́ẹ̀ ni kì í kọ òdodo sílẹ̀.
24Nítorí náà, gbogbo eniyan bẹ̀rù rẹ̀,
kò sì náání àwọn tí wọ́n gbọ́n lójú ara wọn.”

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

JOBU 37: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀