JOBU 38

38
OLUWA dá Jobu Lóhùn
1Nígbà náà ni OLUWA dá Jobu lóhùn láti inú ìjì líle. 2Ó bi í pé,
“Ta ni ẹni tí ń bu ẹnu àtẹ́ lu ìmọ̀ràn,
tí ń sọ̀rọ̀ tí kò ní ìmọ̀?
3Nisinsinyii, múra gírí bí ọkunrin,
mo ní ìbéèrè kan láti bí ọ, o óo sì dá mi lóhùn.
4Níbo lo wà, nígbà tí mo fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀?
Bí o bá mọ ìgbà náà, sọ fún mi.
5Ta ló ṣe ìdíwọ̀n rẹ̀–
ṣebí o mọ̀ ọ́n, dá mi lóhùn!
Àbí ta ló ta okùn ìwọ̀n sórí rẹ̀?
6Orí kí ni a gbé ìpìlẹ̀ rẹ̀ lé,
àbí ta ló fi òkúta igun rẹ̀ sọlẹ̀;
7tí àwọn ìràwọ̀ òwúrọ̀ ń jùmọ̀ kọrin,
tí gbogbo àwọn ọmọ Ọlọrun sì búsáyọ̀?#Bar 3:34
8Ta ló tìlẹ̀kùn mọ́ òkun,
nígbà tí ó ń ru jáde,
9tí mo fi awọsanma ṣe ẹ̀wù rẹ̀,
tí òkùnkùn biribiri sì jẹ́ ọ̀já ìgbànú rẹ̀,
10tí mo sì pa ààlà fún un,
tí mo sé ìlẹ̀kùn mọ́ ọn,
11tí mo wí pé, ‘Dúró níhìn-ín, o kò gbọdọ̀ kọjá ibẹ̀,
ibí ni ìgbì líle rẹ ti gbọdọ̀ dáwọ́ dúró?’
12Jobu, láti ọjọ́ tí o ti dé ayé,
ǹjẹ́ o ti pàṣẹ pé kí ilẹ̀ mọ́ rí,
tabi pé kí àfẹ̀mọ́jú mọ́ àkókò rẹ̀,
13kí ìmọ́lẹ̀ lè tàn sí gbogbo ayé,
kí ó sì lè gbọn àwọn ẹni ibi dànù,
kúrò ní ibi ìsápamọ́sí wọn?
14A ti yí ayé pada bí amọ̀ tí a fi òǹtẹ̀ tẹ̀,
ati bí aṣọ tí a pa láró.
15A mú ìmọ́lẹ̀ kúrò lọ́dọ̀ àwọn ẹni ibi,
a sì ká wọn lápá kò.#Jer 5:22
16“Ṣé o ti wọ orísun òkun lọ rí,
tabi o ti rìn nísàlẹ̀ ibú rí?
17Ṣé a ti fi ìlẹ̀kùn ikú hàn ọ́ rí,
tabi o ti rí ìlẹ̀kùn òkùnkùn biribiri rí?
18Ṣé o mọ̀ bí ayé ti tóbi tó?
Dá mi lóhùn, bí o bá mọ àwọn nǹkan wọnyi.
19“Níbo ni ọ̀nà ilé ìmọ́lẹ̀,
ibo sì ni ibùgbé òkùnkùn,
20tí o óo fi lè mú un lọ sí ààyè rẹ̀,
tí o fi lè mọ ọ̀nà tí ó lọ sí ilé rẹ̀?
21Dájúdájú o mọ̀, nítorí pé wọ́n ti bí ọ nígbà náà,
o sá ti dàgbà!
22“Ṣé o ti wọ àwọn ilé ìkẹ́rùsí, tí mò ń kó yìnyín pamọ́ sí rí,
tabi ibi tí mò ń kó òjò dídì sí,
23àní, àwọn tí mo ti pamọ́ de àkókò ìyọnu,
fún ọjọ́ ogun ati ọjọ́ ìjà?
24Ṣé o mọ ibi tí ìmọ́lẹ̀ ti ń tàn wá,
tabi ibi tí afẹ́fẹ́ ìlà oòrùn ti ń fẹ́ wá sórí ayé?
25“Ta ló lànà fún ọ̀wààrà òjò,
ati fún ààrá,
26láti rọ òjò sí orí ilẹ̀ níbi tí kò sí eniyan,
ati ní aṣálẹ̀, níbi tí kò sí ẹnikẹ́ni?
27Láti tẹ́ aṣálẹ̀ lọ́rùn,
ati láti mú kí ilẹ̀ hu koríko?
28Ṣé òjò ní baba; àbí, baba wo ló sì bí ìrì?
29Ìyá wo ló bí yìnyín,
inú ta ni òjò dídì sì ti jáde?
30Ó sọ omi odò di líle bí òkúta,
ojú ibú sì dì bíi yìnyín.
31“Ṣé o lè fokùn so ìràwọ̀ Pileiadesi,
tabi kí o tú okùn ìràwọ̀ Orioni?
32Ṣé o lè darí àkójọpọ̀ àwọn ìràwọ̀, ní àkókò wọn,
tabi kí o ṣe atọ́nà ìràwọ̀ Beari ati àwọn ọmọ rẹ̀?
33Ṣé o mọ àwọn òfin tí ó de ojú ọ̀run?
Tabi o lè fìdí wọn múlẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé?
34“Ǹjẹ́ o lè pàṣẹ fún ìkùukùu pé,
kí ó rọ òjò lé ọ lórí?
35Ṣé o lè pe mànàmáná pé kí ó wá kí o rán an níṣẹ́
kí ó wá bá ọ kí ó wí pé, ‘Èmi nìyí?’
36Ta ló fi ọgbọ́n sinu ìkùukùu
ati ìmọ̀ sinu ìrì?
37Ta ló lè fi ọgbọ́n ká ìkùukùu,
tabi tí ó lè tú omi inú ìkùukùu dà sílẹ̀,
38nígbà tí ilẹ̀ bá gbẹ,
tóbẹ́ẹ̀ tí ó dì, tí ó sì le koko?
39“Ṣé o lè wá oúnjẹ fún kinniun,
tabi kí o fi oúnjẹ tẹ́ àwọn ọ̀dọ́ kinniun lọ́rùn,
40nígbà tí wọ́n bá dùbúlẹ̀ ninu ihò wọn,
tabi tí wọ́n ba ní ibùba wọn?
41Ta ní ń wá oúnjẹ fún àwọn ẹyẹ ìwò,
nígbà tí àwọn ọmọ wọn bá kígbe sí Ọlọrun,
tí wọ́n sì ń káàkiri tí wọn ń wá oúnjẹ?

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

JOBU 38: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀