JOBU 6
6
1Jobu bá dáhùn pé,
2“Bí ó bá ṣeéṣe láti wọn ìbànújẹ́ mi,
tí a bá sì le gbé ìdààmú mi lé orí ìwọ̀n,
3ìbá wúwo ju yanrìn etí òkun lọ.
Ìdí nìyí tí mo fi ń fi ìtara sọ̀rọ̀.
4Ọfà Olodumare wọ̀ mí lára,
oró rẹ̀ sì mú mi.
Ọlọrun kó ìpayà bá mi.
5Ǹjẹ́ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ igbó a máa ké
tí ó bá rí koríko jẹ?
Àbí mààlúù a máa dún
tí ó bá ń wo oúnjẹ rẹ̀ nílẹ̀?
6Ǹjẹ́ ohun tí kò dùn ṣe é jẹ
láì fi iyọ̀ sí i?
Tabi, adùn wo ní ń bẹ ninu funfun ẹyin?
7Irú oúnjẹ bẹ́ẹ̀ kì í wù mí í jẹ,
Ìríra ni jíjẹ rẹ̀ jẹ́ fún mi.
8“Ìbá ti dára tó, kí Ọlọrun mú ìbéèrè mi ṣẹ,
kí ó fún mi ní ohun tí ọkàn mi ń fẹ́.
9Àní, kí ó wó mi mọ́lẹ̀,
kí ó mú mi, kí ó pa mí dànù.
10Yóo jẹ́ ìtùnú fún mi;
n óo sì láyọ̀ ninu ọpọlọpọ ìrora,
nítorí pé n kò sẹ́ ọ̀rọ̀ Ẹni Mímọ́.
11Agbára wo ni mo ní,
tí mo fi lè tún máa wà láàyè?
Kí sì ni ìrètí mi, tí n óo fi tún máa ní sùúrù?
12Agbára mi ha rí bí ti òkúta bí?
Àbí ẹran ara mi jẹ́ idẹ?
13Nítòótọ́, n kò ní agbára mọ́,
bẹ́ẹ̀ ni n kò sì ní olùrànlọ́wọ́.
14“Ẹni tí ó bá kọ̀
tí kò ṣàánú ọ̀rẹ́ rẹ̀
kò ní ìbẹ̀rù Olodumare.
15Ṣugbọn, ẹ̀yin arakunrin mi,
ẹlẹ́tàn ni yín, bíi odò àgbàrá
tí ó yára kún,
tí ó sì tún yára gbẹ,
16tí yìnyín bo odò náà tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi ṣókùnkùn,
tí yìnyín ńláńlá sì farapamọ́ sibẹ,
17ṣugbọn ní àkókò ooru, wọn a yọ́,
bí ilẹ̀ bá ti gbóná,
wọn a sì gbẹ.
18Àwọn oníṣòwò tí ń lo ràkúnmí
yà kúrò ní ọ̀nà wọn, wọ́n ń wá omi kiri
wọ́n kiri títí wọ́n fi ṣègbé ninu aṣálẹ̀.
19Àwọn oníṣòwò Temani ń wò rá rà rá,
àwọn ọ̀wọ́ èrò Ṣeba sì dúró pẹlu ìrètí.
20Ìrètí wọn di òfo
nítorí wọ́n ní ìdánilójú.
Wọ́n dé ibi tí odò wà tẹ́lẹ̀,
ṣugbọn òfo ni wọ́n bá.
21Bẹ́ẹ̀ ni ẹ rí sí mi nisinsinyii.
Ẹ rí ìdààmú mi, ẹ̀rù bà yín.
22Ǹjẹ́ mo tọrọ ẹ̀bùn lọ́wọ́ yín?
Tabi mo bẹ̀ yín pé kí ẹ mú ninu owó yín,
kí ẹ fi san àbẹ̀tẹ́lẹ̀ nítorí mi?
23Ǹjẹ́ mo bẹ̀ yín pé kí ẹ gbà mí lọ́wọ́ ọ̀tá;
tabi pé kí ẹ rà mí pada kúrò lọ́wọ́ aninilára?
24“Ó dára, mo gbọ́, ẹ wá kọ́ mi,
ẹ ṣàlàyé ẹ̀ṣẹ̀ tí mo ṣẹ̀ fún mi;
n óo sì dákẹ́ n óo tẹ́tí sílẹ̀.
25Lóòótọ́ ọ̀rọ̀ òtítọ́ ní agbára,
ṣugbọn kí ni ẹ̀ ń bá mi wí lé lórí.
26Ẹ rò pé mò ń fi ọ̀rọ̀ ṣòfò lásán ni?
Kí ni ẹ̀ ń dásí ọ̀rọ̀ èmi onírora sí?
27Ẹ tilẹ̀ lè ṣẹ́ gègé lórí ọmọ òrukàn,
ẹ sì lè díye lé ọ̀rẹ́ yín.
28“Ẹ gbọ́, ẹ wò mí dáradára,
nítorí n kò ní purọ́ níwájú yín.
29Mo bẹ̀ yín, ẹ dúró bẹ́ẹ̀,
kí ẹ má baà ṣẹ̀.
Ẹ dúró bẹ́ẹ̀, nítorí n kò lẹ́bi.
30Ṣé ẹ rò pé mò ń parọ́ ni?
Àbí n kò mọ nǹkan burúkú yàtọ̀?
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
JOBU 6: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010
JOBU 6
6
1Jobu bá dáhùn pé,
2“Bí ó bá ṣeéṣe láti wọn ìbànújẹ́ mi,
tí a bá sì le gbé ìdààmú mi lé orí ìwọ̀n,
3ìbá wúwo ju yanrìn etí òkun lọ.
Ìdí nìyí tí mo fi ń fi ìtara sọ̀rọ̀.
4Ọfà Olodumare wọ̀ mí lára,
oró rẹ̀ sì mú mi.
Ọlọrun kó ìpayà bá mi.
5Ǹjẹ́ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ igbó a máa ké
tí ó bá rí koríko jẹ?
Àbí mààlúù a máa dún
tí ó bá ń wo oúnjẹ rẹ̀ nílẹ̀?
6Ǹjẹ́ ohun tí kò dùn ṣe é jẹ
láì fi iyọ̀ sí i?
Tabi, adùn wo ní ń bẹ ninu funfun ẹyin?
7Irú oúnjẹ bẹ́ẹ̀ kì í wù mí í jẹ,
Ìríra ni jíjẹ rẹ̀ jẹ́ fún mi.
8“Ìbá ti dára tó, kí Ọlọrun mú ìbéèrè mi ṣẹ,
kí ó fún mi ní ohun tí ọkàn mi ń fẹ́.
9Àní, kí ó wó mi mọ́lẹ̀,
kí ó mú mi, kí ó pa mí dànù.
10Yóo jẹ́ ìtùnú fún mi;
n óo sì láyọ̀ ninu ọpọlọpọ ìrora,
nítorí pé n kò sẹ́ ọ̀rọ̀ Ẹni Mímọ́.
11Agbára wo ni mo ní,
tí mo fi lè tún máa wà láàyè?
Kí sì ni ìrètí mi, tí n óo fi tún máa ní sùúrù?
12Agbára mi ha rí bí ti òkúta bí?
Àbí ẹran ara mi jẹ́ idẹ?
13Nítòótọ́, n kò ní agbára mọ́,
bẹ́ẹ̀ ni n kò sì ní olùrànlọ́wọ́.
14“Ẹni tí ó bá kọ̀
tí kò ṣàánú ọ̀rẹ́ rẹ̀
kò ní ìbẹ̀rù Olodumare.
15Ṣugbọn, ẹ̀yin arakunrin mi,
ẹlẹ́tàn ni yín, bíi odò àgbàrá
tí ó yára kún,
tí ó sì tún yára gbẹ,
16tí yìnyín bo odò náà tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi ṣókùnkùn,
tí yìnyín ńláńlá sì farapamọ́ sibẹ,
17ṣugbọn ní àkókò ooru, wọn a yọ́,
bí ilẹ̀ bá ti gbóná,
wọn a sì gbẹ.
18Àwọn oníṣòwò tí ń lo ràkúnmí
yà kúrò ní ọ̀nà wọn, wọ́n ń wá omi kiri
wọ́n kiri títí wọ́n fi ṣègbé ninu aṣálẹ̀.
19Àwọn oníṣòwò Temani ń wò rá rà rá,
àwọn ọ̀wọ́ èrò Ṣeba sì dúró pẹlu ìrètí.
20Ìrètí wọn di òfo
nítorí wọ́n ní ìdánilójú.
Wọ́n dé ibi tí odò wà tẹ́lẹ̀,
ṣugbọn òfo ni wọ́n bá.
21Bẹ́ẹ̀ ni ẹ rí sí mi nisinsinyii.
Ẹ rí ìdààmú mi, ẹ̀rù bà yín.
22Ǹjẹ́ mo tọrọ ẹ̀bùn lọ́wọ́ yín?
Tabi mo bẹ̀ yín pé kí ẹ mú ninu owó yín,
kí ẹ fi san àbẹ̀tẹ́lẹ̀ nítorí mi?
23Ǹjẹ́ mo bẹ̀ yín pé kí ẹ gbà mí lọ́wọ́ ọ̀tá;
tabi pé kí ẹ rà mí pada kúrò lọ́wọ́ aninilára?
24“Ó dára, mo gbọ́, ẹ wá kọ́ mi,
ẹ ṣàlàyé ẹ̀ṣẹ̀ tí mo ṣẹ̀ fún mi;
n óo sì dákẹ́ n óo tẹ́tí sílẹ̀.
25Lóòótọ́ ọ̀rọ̀ òtítọ́ ní agbára,
ṣugbọn kí ni ẹ̀ ń bá mi wí lé lórí.
26Ẹ rò pé mò ń fi ọ̀rọ̀ ṣòfò lásán ni?
Kí ni ẹ̀ ń dásí ọ̀rọ̀ èmi onírora sí?
27Ẹ tilẹ̀ lè ṣẹ́ gègé lórí ọmọ òrukàn,
ẹ sì lè díye lé ọ̀rẹ́ yín.
28“Ẹ gbọ́, ẹ wò mí dáradára,
nítorí n kò ní purọ́ níwájú yín.
29Mo bẹ̀ yín, ẹ dúró bẹ́ẹ̀,
kí ẹ má baà ṣẹ̀.
Ẹ dúró bẹ́ẹ̀, nítorí n kò lẹ́bi.
30Ṣé ẹ rò pé mò ń parọ́ ni?
Àbí n kò mọ nǹkan burúkú yàtọ̀?
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
:
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010