JOBU 7
7
1“Ìgbésí ayé eniyan le koko,
ọjọ́ ayé rẹ̀ sì dàbí ti alágbàṣe.
2Ó dàbí ẹrú tí ń wá ìbòòji kiri
ati bí alágbàṣe tí ń dúró de owó iṣẹ́ rẹ̀.
3Òfo ni ọ̀rọ̀ mi látoṣù-dóṣù,
ìbànújẹ́ ní sì ń dé bá mi láti ọjọ́ dé ọjọ́
4Bí mo bá sùn lóru,
n óo máa ronú pé,
‘Ìgbà wo ni ilẹ̀ óo mọ́ tí n óo dìde?’
Òru a gùn bí ẹni pé ojúmọ́ kò ní mọ́ mọ́,
ma wá máa yí síhìn-ín, sọ́hùn-ún,
títí ilẹ̀ yóo fi mọ́.
5Gbogbo ara mi kún fún kòkòrò, ati ìdọ̀tí,
gbogbo ara mi yi, ó sì di egbò.
6Ọjọ́ ayé mi ń sáré ju ọ̀kọ̀ ìhunṣọ lọ,
Ó sì ń lọ sópin láìní ìrètí.
7“Ọlọrun, ranti pé afẹ́fẹ́ lásán ni mo jẹ́,
ati pé ojú mi kò ní rí ohun rere mọ́.
8Ojú ẹni tí ó rí mi nisinsinyii kò ní rí mi mọ́;
níṣojú yín báyìí ni n óo fi parẹ́.
9Bí ìkùukùu tíí parẹ́ tí a kì í rí i mọ́,
bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀mí tí ó lọ sí ipò òkú rí,
kò ní pada mọ́.
10Kò ní pada sí ilé rẹ̀ mọ́,
bẹ́ẹ̀ ni ibùjókòó rẹ̀ kò ní mọ̀ ọ́n mọ́.#Ọgb 2:1-4
11“Nítorí náà, n kò ní dákẹ́;
n óo sọ ìrora ọkàn mi;
n óo tú ìbànújẹ́ mi jáde.
12Ṣé òkun ni mí ni, tabi erinmi,
tí ẹ fi yan olùṣọ́ tì mí?
13Nígbà tí mo wí pé,
‘Ibùsùn mi yóo tù mí lára,
ìjókòó mi yóo sì mú kí ara tù mí ninu ìráhùn mi’.
14Nígbà náà ni ẹ̀yin tún wá fi àlá yín dẹ́rù bà mí,
tí ẹ sì fi ìran pá mi láyà,
15kí n lè fara mọ́ ọn pé
ó sàn kí á lọ́ mi lọ́rùn pa,
kí n sì lè yan ikú
dípò pé kí n wà láàyè.
16Ayé sú mi,
n kò ní wà láàyè títí lae.
Ẹ fi mí sílẹ̀,
nítorí ọjọ́ ayé mi dàbí èémí lásán.
17Kí ni eniyan jẹ́, tí o fi gbé e ga,
tí o sì fi ń náání rẹ̀;
18tí ò ń bẹ̀ ẹ́ wò láràárọ̀,
tí o sì ń dán an wò nígbà gbogbo?
19Yóo ti pẹ́ tó kí ẹ tó mójú kúrò lára mi?
Kí ẹ tó fi mí lọ́rùn sílẹ̀
kí n rí ààyè dá itọ́ mì?
20Bí mo bá ṣẹ̀, kí ni ẹ̀ṣẹ̀ tí mo ṣẹ̀ yín,
ẹ̀yin tí ẹ̀ ń ṣọ́ mi?
Kí ló dé tí ẹ fi dójú lé mi,
tí mo di ẹrù lọ́rùn yín?
21Kí ló dé tí ẹ kò lè dárí ẹ̀ṣẹ̀ mi jì mí
kí ẹ sì fojú fo àìdára mi?
Láìpẹ́ n óo lọ sinu ibojì.
Ẹ óo wá mi,
ṣugbọn n kò ní sí mọ́.”#O. Daf 8:4; 144:3
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
JOBU 7: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010

:
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010