JOBU 8
8
1Bilidadi ará Ṣuha dáhùn pé,
2“O óo ti sọ irú ọ̀rọ̀ wọnyi pẹ́ tó,
tí ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ yóo sì dàbí afẹ́fẹ́ líle?
3Ṣé Ọlọrun a máa yí ìdájọ́ po?
Ṣé Olodumare a máa yí òdodo pada?
4Bí ó bá jẹ́ pé àwọn ọmọ rẹ dẹ́ṣẹ̀ ni,
ó ti jẹ wọ́n níyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn.
5Ṣugbọn bí o bá wá Ọlọrun,
tí o sì sọ ẹ̀dùn ọkàn rẹ fún Olodumare;
6tí o bá jẹ́ ẹni mímọ́ ati olóòótọ́,
dájúdájú OLUWA yóo dìde, yóo ràn ọ́ lọ́wọ́,
yóo sì fi ibùgbé rere san ẹ̀san fún ọ.
7Díẹ̀ ni ọrọ̀ tí o ní tẹ́lẹ̀ yóo jẹ́
lára ohun tí Ọlọrun yóo fún ọ ní ọjọ́ iwájú.
8“Mo bẹ̀ ọ́, lọ wádìí nípa ìgbà àtijọ́,
kí o ṣe akiyesi ìrírí àwọn baba wa.
9Nítorí ọmọde ni wá,
a kò mọ nǹkankan,
ọjọ́ ayé wa sì dàbí òjìji.
10Àwọn ni wọn óo kọ́ ọ,
tí wọn óo bá ọ sọ̀rọ̀,
tí wọn óo sì fún ọ ní ìmọ̀ràn ninu òye wọn. #Sir 8:9
11“Ṣé koríko etídò le hù níbi tí kò sí àbàtà?
Tabi kí èèsún hù níbi tí kò sí omi?
12Bí bẹ́ẹ̀ kọ́ nígbà tí ó bá ń tanná lọ́wọ́,
yóo rọ ṣáájú gbogbo ewéko,
láìjẹ́ pé ẹnikẹ́ni gé e lulẹ̀
13Bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ ẹni tí
ó gbàgbé Ọlọrun rí;
ìrètí ẹni tí kò mọ Ọlọrun yóo parun.
14Igbẹkẹle rẹ̀ já sí asán,
ìmúlẹ̀mófo ni, bí òwú aláǹtakùn.
15Ó farati ilé rẹ̀,
ṣugbọn kò le gbà á dúró.
Ó dì í mú,
ṣugbọn kò lè mú un dúró.
16Kí oòrùn tó yọ, ẹni ibi a máa tutù yọ̀yọ̀,
àwọn ẹ̀ka rẹ̀ a sì gbilẹ̀ káàkiri inú ọgbà rẹ̀.
17Ṣugbọn ara òkúta ni gbòǹgbò rẹ̀ rọ̀ mọ́,
òun gan-an sì ń gbé ààrin àpáta.
18Bí wọ́n bá fà á tu kúrò ní ààyè rẹ̀,
kò sí ẹni tí yóo mọ̀ pé ó wà níbẹ̀ rí.
19Ayọ̀ ọrọ̀ rẹ̀ kò jù báyìí lọ,
àwọn mìíràn óo dìde,
wọn yóo sì gba ipò rẹ̀.
20“Ṣugbọn Ọlọrun kò jẹ́ fi àwọn olóòótọ́ sílẹ̀,
bẹ́ẹ̀ ni kò jẹ́ ran ẹni ibi lọ́wọ́.
21Yóo tún fi ẹ̀rín kún ọ ní ẹ̀rẹ̀kẹ́,
ẹnu rẹ yóo kún fún ìhó ayọ̀.
22Ojú yóo ti àwọn ọ̀tá rẹ,
ilé àwọn eniyan burúkú yóo sì parẹ́.”
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
JOBU 8: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010
JOBU 8
8
1Bilidadi ará Ṣuha dáhùn pé,
2“O óo ti sọ irú ọ̀rọ̀ wọnyi pẹ́ tó,
tí ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ yóo sì dàbí afẹ́fẹ́ líle?
3Ṣé Ọlọrun a máa yí ìdájọ́ po?
Ṣé Olodumare a máa yí òdodo pada?
4Bí ó bá jẹ́ pé àwọn ọmọ rẹ dẹ́ṣẹ̀ ni,
ó ti jẹ wọ́n níyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn.
5Ṣugbọn bí o bá wá Ọlọrun,
tí o sì sọ ẹ̀dùn ọkàn rẹ fún Olodumare;
6tí o bá jẹ́ ẹni mímọ́ ati olóòótọ́,
dájúdájú OLUWA yóo dìde, yóo ràn ọ́ lọ́wọ́,
yóo sì fi ibùgbé rere san ẹ̀san fún ọ.
7Díẹ̀ ni ọrọ̀ tí o ní tẹ́lẹ̀ yóo jẹ́
lára ohun tí Ọlọrun yóo fún ọ ní ọjọ́ iwájú.
8“Mo bẹ̀ ọ́, lọ wádìí nípa ìgbà àtijọ́,
kí o ṣe akiyesi ìrírí àwọn baba wa.
9Nítorí ọmọde ni wá,
a kò mọ nǹkankan,
ọjọ́ ayé wa sì dàbí òjìji.
10Àwọn ni wọn óo kọ́ ọ,
tí wọn óo bá ọ sọ̀rọ̀,
tí wọn óo sì fún ọ ní ìmọ̀ràn ninu òye wọn. #Sir 8:9
11“Ṣé koríko etídò le hù níbi tí kò sí àbàtà?
Tabi kí èèsún hù níbi tí kò sí omi?
12Bí bẹ́ẹ̀ kọ́ nígbà tí ó bá ń tanná lọ́wọ́,
yóo rọ ṣáájú gbogbo ewéko,
láìjẹ́ pé ẹnikẹ́ni gé e lulẹ̀
13Bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ ẹni tí
ó gbàgbé Ọlọrun rí;
ìrètí ẹni tí kò mọ Ọlọrun yóo parun.
14Igbẹkẹle rẹ̀ já sí asán,
ìmúlẹ̀mófo ni, bí òwú aláǹtakùn.
15Ó farati ilé rẹ̀,
ṣugbọn kò le gbà á dúró.
Ó dì í mú,
ṣugbọn kò lè mú un dúró.
16Kí oòrùn tó yọ, ẹni ibi a máa tutù yọ̀yọ̀,
àwọn ẹ̀ka rẹ̀ a sì gbilẹ̀ káàkiri inú ọgbà rẹ̀.
17Ṣugbọn ara òkúta ni gbòǹgbò rẹ̀ rọ̀ mọ́,
òun gan-an sì ń gbé ààrin àpáta.
18Bí wọ́n bá fà á tu kúrò ní ààyè rẹ̀,
kò sí ẹni tí yóo mọ̀ pé ó wà níbẹ̀ rí.
19Ayọ̀ ọrọ̀ rẹ̀ kò jù báyìí lọ,
àwọn mìíràn óo dìde,
wọn yóo sì gba ipò rẹ̀.
20“Ṣugbọn Ọlọrun kò jẹ́ fi àwọn olóòótọ́ sílẹ̀,
bẹ́ẹ̀ ni kò jẹ́ ran ẹni ibi lọ́wọ́.
21Yóo tún fi ẹ̀rín kún ọ ní ẹ̀rẹ̀kẹ́,
ẹnu rẹ yóo kún fún ìhó ayọ̀.
22Ojú yóo ti àwọn ọ̀tá rẹ,
ilé àwọn eniyan burúkú yóo sì parẹ́.”
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
:
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010