JONA 4
4
Ibinu Jona ati Àánú Ọlọrun
1Ṣugbọn bí Ọlọrun ti ṣe yìí kò dùn mọ́ Jona ninu rárá, inú bí i. 2Ó bá gbadura sí OLUWA, ó ní: “OLUWA, ṣebí ohun tí mo sọ láti ìbẹ̀rẹ̀ nìyí, nígbà tí mo wà ní orílẹ̀-èdè mi? Nítorí náà ni mo ṣe sa gbogbo ipá mi láti sálọ sí Taṣiṣi; nítorí mo mọ̀ pé Ọlọrun onífẹ̀ẹ́ ati aláàánú ni ọ́, o ní sùúrù, o kún fún ìfẹ́ tí kì í yẹ̀, ò sì máa yí ibi tí o bá ti pinnu láti ṣe pada.#Eks 34:6 3Ǹjẹ́ nisinsinyii, OLUWA, mo bẹ̀ ọ́, gba ẹ̀mí mi, nítorí pé, ó sàn fún mi láti kú ju pé kí n wà láàyè lọ.”#1A. Ọba 19:4
4OLUWA bá dá Jona lóhùn pé, “Ǹjẹ́ ó yẹ kí o bínú?”
5Jona bá jáde kúrò láàrin ìlú náà, ó sì lọ jókòó sí ìhà ìlà oòrùn ìlú náà. Ó pa àtíbàbà kan sibẹ, ó jókòó ní ìbòòji lábẹ́ rẹ̀, ó ń retí ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ sí ìlú náà.
6OLUWA bá rán ìtàkùn kan, ó fà á bo ibẹ̀, o sì ṣíji bo orí ibi tí Jona wà kí ó lè fún un ní ìtura ninu ìnira rẹ̀. Inú Jona dùn gidigidi nítorí ìtàkùn yìí. 7Ṣugbọn Ọlọrun rán kòkòrò kan ní àárọ̀ ọjọ́ keji, ó jẹ ìtàkùn náà, ó sì rọ. 8Nígbà tí oòrùn yọ, Ọlọrun mú kí afẹ́fẹ́ ìhà ìlà oòrùn fẹ́, oòrùn sì pa Jona tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi fẹ́rẹ̀ dákú. Ó sọ fún Ọlọrun pé kí ó gba ẹ̀mí òun. Ó ní, “Ó sàn kí n kú ju pé kí n wà láàyè lọ.”
9Ọlọrun bá bi Jona pé, “Ǹjẹ́ o lẹ́tọ̀ọ́ láti bínú nítorí ìtàkùn yìí?” Jona dáhùn, ó ní: “Ó tọ́ kí n bínú títí dé ojú ikú.”
10Nígbà náà ni OLUWA dá a lóhùn pé, “ìwọ ń káàánú ìtàkùn lásánlàsàn, tí o kò ṣiṣẹ́ fún, tí kì í sìí ṣe ìwọ ni o mú un dàgbà, àní ìtàkùn tí ó hù ní òru ọjọ́ kan, tí ó sì gbẹ ní ọjọ́ keji. 11Ṣé kò yẹ kí èmi foríji Ninefe, ìlú ńlá nì, tí àwọn ọmọde inú rẹ̀ ju ọ̀kẹ́ mẹfa (120,000) lọ, tí wọn kò mọ ọwọ́ ọ̀tún yàtọ̀ sí tòsì, pẹlu ọpọlọpọ ẹran ọ̀sìn tí ó wà ninu ìlú náà?”
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
JONA 4: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010