JOṢUA 1
1
Ọlọrun Pàṣẹ fún Joṣua pé Kí Ó Fi Ogun Kó Ilẹ̀ Kenaani
1Lẹ́yìn ikú Mose, iranṣẹ OLUWA, OLUWA sọ fún Joṣua, ọmọ Nuni, olùrànlọ́wọ́ Mose pé, 2“Mose iranṣẹ mi ti kú, nítorí náà, ìwọ ati gbogbo àwọn ọmọ Israẹli, ẹ múra kí ẹ la odò Jọdani kọjá, kí ẹ sì wọ ilẹ̀ tí n óo fun yín. 3Gbogbo ibi tí ẹsẹ̀ yín bá tẹ̀ ni mo ti fun yín, gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣèlérí fún Mose. 4Láti inú aṣálẹ̀ ati òkè Lẹbanoni yìí lọ, títí dé odò ńlá náà, odò Yufurate, gbogbo ilẹ̀ àwọn ará Hiti, títí dé Òkun Mẹditarenia ní apá ìwọ̀ oòrùn, ni yóo jẹ́ ilẹ̀ yín. 5Kò ní sí ẹni tí yóo lè borí rẹ ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ. Bí mo ti wà pẹlu Mose ni n óo wà pẹlu rẹ. N kò ní já ọ kulẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni n kò ní kọ̀ ọ́ sílẹ̀ lae.#Diut 11:24-25 #Diut 31:6,8; Heb 13:5. 6Múra, kí o sì ṣe ọkàn gírí, nítorí ìwọ ni o óo jẹ́ kí àwọn eniyan wọnyi gba ilẹ̀ tí mo ti búra fún àwọn baba wọn, pé n óo fún wọn. 7Ìwọ ṣá ti múra, kí o ṣe ọkàn gírí, kí o sì rí i dájú pé o pa gbogbo òfin tí Mose, iranṣẹ mi, fún ọ mọ́. Má ṣe yẹsẹ̀ kúrò ninu rẹ̀ sí ọ̀tún, tabi sí òsì, kí gbogbo ohun tí o bá dáwọ́ lé níbikíbi tí o bá lọ lè máa yọrí sí rere. 8Máa ka ìwé òfin yìí nígbà gbogbo, kí o sì máa ṣe àṣàrò ninu rẹ̀, tọ̀sán-tòru; rí i dájú pé o pa gbogbo ohun tí wọ́n kọ sinu rẹ̀ mọ́. Nígbà náà ni yóo dára fún ọ, gbogbo ohun tí o bá dáwọ́ lé yóo sì máa yọrí sí rere. 9Ranti pé mo ti pàṣẹ fún ọ pé kí o múra, kí o sì ṣe ọkàn gírí. Má bẹ̀rù, má sì jẹ́ kí ìrẹ̀wẹ̀sì bá ọkàn rẹ, nítorí pé èmi, OLUWA Ọlọrun rẹ wà pẹlu rẹ níbikíbi tí o bá ń lọ.”#Diut 31:6,7,23
Joṣua Pàṣẹ fún Àwọn Eniyan Náà
10Lẹ́yìn náà, Joṣua pàṣẹ fún gbogbo àwọn olórí àwọn eniyan náà, ó ní, 11“Ẹ lọ káàkiri ibùdó, kí ẹ sì pàṣẹ fún àwọn eniyan náà, pé kí wọn máa pèsè oúnjẹ sílẹ̀, nítorí pé láàrin ọjọ́ mẹta wọn óo la odò Jọdani kọjá láti lọ gba ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun wọn fún wọn.”
12Joṣua sọ fún àwọn ẹ̀yà Reubẹni, ati ti Gadi, ati ìdajì ẹ̀yà Manase pé, 13“Ẹ ranti àṣẹ tí Mose, iranṣẹ OLUWA, pa fun yín pé, ‘OLUWA Ọlọrun yín ń pèsè ibi ìsinmi fun yín, yóo sì fi ilẹ̀ yìí fun yín.’ 14Àwọn aya yín, àwọn ọmọ yín kéékèèké, ati àwọn ẹran ọ̀sìn yín ni yóo kù lẹ́yìn lórí ilẹ̀ tí Mose fun yín ní òdìkejì odò Jọdani; ṣugbọn gbogbo àwọn akọni láàrin yín yóo rékọjá sí òdìkejì odò náà pẹlu ihamọra ogun níwájú àwọn arakunrin yín, wọn yóo máa ràn wọ́n lọ́wọ́ 15títí tí OLUWA yóo fi fún àwọn arakunrin yín ní ìsinmi gẹ́gẹ́ bí ó ti fun yín, tí wọn yóo sì fi gba ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun yín yóo fún wọn. Nígbà náà ni ẹ óo tó pada sí orí ilẹ̀ yín, tí Mose, iranṣẹ OLUWA, fun yín ní ìhà ìlà oòrùn odò Jọdani, ẹ óo sì máa gbé ibẹ̀.”#Nọm 32:28-32; Diut 3:18-20; Joṣ 22:1-6
16Wọ́n dá Joṣua lóhùn pé, “Gbogbo ohun tí o pa láṣẹ fún wa ni a óo ṣe, ibikíbi tí o bá sì rán wa ni a óo lọ. 17Bí a ti gbọ́ ti Mose, bẹ́ẹ̀ ni a óo máa gbọ́ tìrẹ náà. Kí OLUWA Ọlọrun rẹ ṣá ti wà pẹlu rẹ gẹ́gẹ́ bí ó ti wà pẹlu Mose. 18Ẹnikẹ́ni tí ó bá tàpá sí àṣẹ rẹ, tí ó sì kọ̀ láti ṣe ohunkohun tí o bá sọ fún un, pípa ni a óo pa á. Ìwọ ṣá ti múra, kí o sì ṣe ọkàn gírí.”
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
JOṢUA 1: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010