ẸKÚN JEREMAYA 5

5
Adura fún Àánú
1OLUWA, ranti ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí wa,
Ṣe akiyesi ẹ̀sín wa.
2Àwọn ilẹ̀ àjogúnbá ẹni ẹlẹ́ni,
ilé wa sì ti di ti àwọn àjèjì.
3A ti di aláìníbaba, ọmọ òrukàn
àwọn ìyá wa kò yàtọ̀ sí opó.
4Owó ni a fi ń ra omi tí à ń mu,
rírà ni a sì ń ra igi tí a fi ń dáná.
5Àwọn tí wọn ń lépa wa ti bá wa,
ó ti rẹ̀ wá, a kò sì ní ìsinmi.
6A ti fa ara wa kalẹ̀ fún àwọn ará Ijipti ati àwọn ará Asiria
nítorí oúnjẹ tí a óo jẹ.
7Àwọn baba wa ni wọ́n dẹ́ṣẹ̀, àwọn sì ti kú,
ṣugbọn àwa ni à ń jìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn.
8Àwọn ẹrú ní ń jọba lé wa lórí,
kò sì sí ẹni tí yóo gbà wá lọ́wọ́ wọn.
9Ẹ̀mí wa ni à ń fi wéwu, kí á tó rí oúnjẹ,
nítorí ogun tí ó wà ninu aṣálẹ̀.
10Awọ ara wa gbóná bí iná ààrò,
nítorí ìyàn tí ó mú lọpọlọpọ.
11Tipátipá ni wọ́n fi ń bá àwọn obinrin lòpọ̀ ní Sioni,
ati àwọn ọmọbinrin tí wọn kò tíì mọ ọkunrin ní Juda.
12Wọ́n fi okùn so ọwọ́ àwọn olórí rọ̀,
wọn kò sì bọ̀wọ̀ fún àwọn àgbààgbà.
13Wọ́n fi ipá mú àwọn ọdọmọkunrin pé kí wọn máa lọ ọlọ,
àwọn ọmọde ru igi títí àárẹ̀ mú wọn!
14Àwọn àgbààgbà ti sá kúrò ní ẹnubodè;
àwọn ọdọmọkunrin sì ti dákẹ́ orin kíkọ.
15Inú wa kò dùn mọ́;
ijó wa ti yipada, ó ti di ọ̀fọ̀.
16Adé ti ṣíbọ́ lórí wa!
A gbé! Nítorí pé a ti dẹ́ṣẹ̀,
17nítorí náà, ọkàn wa ti rẹ̀wẹ̀sì;
ojú wa sì ti di bàìbàì.
18Nítorí òkè Sioni tí ó di ahoro;
tí àwọn ọ̀fàfà sì ń ké lórí rẹ̀.
19Ṣugbọn ìwọ OLUWA ni ó jọba títí ayé,
ìtẹ́ rẹ sì wà láti ìrandíran.
20Kí ló dé tí o fi gbàgbé wa patapata?
Tí o sì kọ̀ wá sílẹ̀ fún ìgbà pípẹ́?
21Mú wa pada sọ́dọ̀ ara rẹ, OLUWA,
kí á lè pada sí ipò wa.
Mú àwọn ọjọ́ àtijọ́ wa pada.
22Ṣé o ti kọ̀ wá sílẹ̀ patapata ni?
Àbí o sì tún ń bínú sí wa, inú rẹ kò tíì rọ̀?

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

ẸKÚN JEREMAYA 5: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀