LUKU 2:1-40

LUKU 2:1-40 YCE

Ní àkókò náà, àṣẹ kan jáde láti ọ̀dọ̀ Kesari Augustu pé kí gbogbo ayé lọ kọ orúkọ wọn sinu ìwé ìjọba. Èyí ni àkọsílẹ̀ ekinni tí wọ́n ṣe nígbà tí Kureniu jẹ́ gomina Siria. Gbogbo àwọn eniyan bá lọ kọ orúkọ wọn sílẹ̀, ẹnìkọ̀ọ̀kan lọ sí ìlú ara rẹ̀. Josẹfu náà gbéra láti Nasarẹti ìlú kan ní ilẹ̀ Galili, ó lọ sí ìlú Dafidi tí ó ń jẹ́ Bẹtilẹhẹmu, ní ilẹ̀ Judia, nítorí ẹbí Dafidi ni. Ó lọ kọ orúkọ sílẹ̀ pẹlu Maria iyawo àfẹ́sọ́nà rẹ̀, tí ó lóyún, tí ó sì fẹ́rẹ̀ bímọ. Ó wá yá nígbà tí wọ́n wà ní Bẹtilẹhẹmu, àkókò tó fún Maria láti bímọ. Ó bá bí àkọ́bí rẹ̀ ọmọkunrin, ó fi ọ̀já wé e, ó tẹ́ ẹ sí ibùjẹ ẹran, nítorí kò sí àyè fún wọn ninu ilé èrò. Ní àkókò náà, àwọn olùṣọ́-aguntan wà ní pápá, níbi tí wọn ń ṣọ́ aguntan wọn ní òru. Angẹli Oluwa kan bá yọ sí wọn, ògo Oluwa tan ìmọ́lẹ̀ yí wọn ká. Ẹ̀rù bà wọ́n gan-an. Ṣugbọn angẹli náà wí fún wọn pé, “Ẹ má bẹ̀rù mọ́, nítorí mo mú ìròyìn ayọ̀ ńlá fun yín wá, ayọ̀ tí yóo jẹ́ ti gbogbo eniyan. Nítorí a bí Olùgbàlà fun yín lónìí, ní ìlú Dafidi, tíí ṣe Oluwa ati Mesaya. Àmì tí ẹ óo fi mọ̀ ọ́n nìyí: ẹ óo rí ọmọ-ọwọ́ náà tí wọ́n fi ọ̀já wé, tí wọ́n tẹ́ sí ibùjẹ ẹran.” Lójijì ọpọlọpọ àwọn ogun ọ̀run yọ pẹlu angẹli náà, wọ́n ń yin Ọlọrun pé, “Ògo fún Ọlọrun lókè ọ̀run, alaafia ní ayé fún àwọn tí inú Ọlọrun dùn sí.” Lẹ́yìn tí àwọn angẹli náà ti pada kúrò lọ́dọ̀ wọn lọ sí ọ̀run, àwọn olùṣọ́-aguntan ń sọ láàrin ara wọn pé, “Ẹ jẹ́ kí á lọ sí Bẹtilẹhẹmu tààrà, kí á lè rí ohun tí ó ṣẹlẹ̀, tí Oluwa bùn wá gbọ́.” Wọ́n bá yára lọ. Wọ́n wá Maria kàn ati Josẹfu ati ọmọ-ọwọ́ náà tí a tẹ́ sí ibùjẹ ẹran. Nígbà tí wọ́n rí i, wọ́n sọ ohun gbogbo tí a ti sọ fún wọn nípa ọmọ náà. Ẹnu sì ya gbogbo àwọn tí ó gbọ́ ohun tí àwọn olùṣọ́-aguntan náà sọ fún wọn. Ṣugbọn Maria ń ṣe akiyesi gbogbo ọ̀rọ̀ wọnyi, ó ń dà wọ́n rò ní ọkàn rẹ̀. Àwọn olùṣọ́-aguntan náà pada síbi iṣẹ́ wọn, wọ́n ń fi ògo ati ìyìn fún Ọlọrun fún gbogbo nǹkan tí wọ́n gbọ́, ati àwọn nǹkan tí wọ́n rí gẹ́gẹ́ bí angẹli náà ti sọ fún wọn. Nígbà tí ọjọ́ kẹjọ pé láti kọ ọmọ náà ní ilà-abẹ́, wọ́n sọ orúkọ rẹ̀ ní Jesu, gẹ́gẹ́ bí angẹli ti wí, kí ìyá rẹ̀ tó lóyún rẹ̀. Nígbà tí ó tó àkókò fún àwọn òbí rẹ̀ láti ṣe àṣà ìwẹ̀mọ́ gẹ́gẹ́ bí òfin Mose, wọ́n gbé ọmọ náà lọ sí Jerusalẹmu láti fi í fún Oluwa. Nítorí ó wà ní àkọsílẹ̀ ninu òfin Oluwa pé, “Gbogbo àkọ́bí lọkunrin ni a óo pè ní mímọ́ fún Oluwa.” Wọ́n tún lọ láti rú ẹbọ gẹ́gẹ́ bí ó ṣe wà ninu òfin Oluwa: pẹlu àdàbà meji, tabi ọmọ ẹyẹlé meji. Ọkunrin kan wà ní Jerusalẹmu tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Simeoni. Ó jẹ́ olódodo eniyan ati olùfọkànsìn, ó ń retí àkókò tí Ọlọrun yóo tu Israẹli ninu. Ẹ̀mí Mímọ́ wà pẹlu rẹ̀. Ẹ̀mí Mímọ́ ti fihàn án pé kò ní tíì kú tí yóo fi rí Mesaya tí Oluwa ti ṣe ìlérí. Ẹ̀mí wá darí rẹ̀ sí Tẹmpili ní àkókò tí àwọn òbí ọmọ náà gbé e wá, láti ṣe gbogbo ètò tí ó yẹ gẹ́gẹ́ bí òfin. Ni Simeoni bá gbé ọmọ náà lọ́wọ́, ó yin Ọlọrun lógo, ó ní, “Nisinsinyii, Oluwa, dá ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ sílẹ̀ ní alaafia, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ. Nítorí ojú mi ti rí ìgbàlà rẹ, tí o ti pèsè níwájú gbogbo eniyan; ìmọ́lẹ̀ láti fi ọ̀nà han àwọn kèfèrí ati ògo fún Israẹli, eniyan rẹ.” Ẹnu ya baba ati ìyá Jesu nítorí ohun tí ó sọ nípa rẹ̀. Simeoni wá súre fún wọn. Ó sọ fún Maria ìyá rẹ̀ pé, “A gbé ọmọ yìí dìde fún ìṣubú ati ìdìde ọpọlọpọ ní Israẹli ati bí àmì tí àwọn eniyan yóo kọ̀. Nítorí yóo mú kí àṣírí èrò ọkàn ọpọlọpọ di ohun tí gbogbo eniyan yóo mọ̀. Ìbànújẹ́ yóo sì gún ọ ní ọkàn bí idà.” Wolii obinrin kan wà tí ń jẹ́ Ana, ọmọ Fanuẹli, ẹ̀yà Aṣeri. Arúgbó kùjọ́kùjọ́ ni. Ọdún meje péré ni ó ṣe ní ilé ọkọ, tí ọkọ rẹ̀ fi kú. Láti ìgbà náà ni ó ti di opó, ó sì tó ẹni ọdún mẹrinlelọgọrin ní àkókò yìí. Kì í fi ìgbà kan kúrò ninu Tẹmpili. Ó ń sìn pẹlu ààwẹ̀ ati ẹ̀bẹ̀ tọ̀sán-tòru. Ní àkókò náà gan-an ni ó dé, ó ń fi ìyìn fún Ọlọrun, ó ń sọ nípa ọmọ yìí fún gbogbo àwọn tí wọn ń retí àkókò ìdásílẹ̀ Jerusalẹmu. Lẹ́yìn tí wọ́n ti parí gbogbo nǹkan wọnyi tán gẹ́gẹ́ bí òfin Oluwa, wọ́n pada lọ sí Nasarẹti ìlú wọn ní ilẹ̀ Galili. Ọmọ náà ń dàgbà, ó ń lágbára, ó kún fún ọgbọ́n, ojurere Ọlọrun sì wà pẹlu rẹ̀.