MALAKI 1
1
1Iṣẹ́ tí OLUWA rán wolii Malaki sí àwọn ọmọ Israẹli nìyí.
Ìfẹ́ OLUWA sí Israẹli
2OLUWA ní, “Mo fẹ́ràn yín pupọ.” Ṣugbọn ẹ̀ ń bèèrè pé, “Kí ló fihàn pé o fẹ́ràn wa?”
OLUWA dáhùn pé, “Ṣebí tẹ̀gbọ́n-tàbúrò ni Esau ati Jakọbu? 3Sibẹ mo fẹ́ràn Jakọbu, mo sì kórìíra Esau. Mo ti sọ gbogbo àwọn ìlú òkè Esau di ahoro, mo sì sọ ilẹ̀ ìní rẹ̀ di ilé ajáko tí ó wà ní aṣálẹ̀.”#Rom 9:13
4Bí Edomu bá sọ pé, “Ìlú wa ti di òkítì àlàpà, ṣugbọn a óo tún un kọ́.” Èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun yóo wá dáhùn pé, “Wọ́n lè máa kọ́ ọ, ṣugbọn n óo tún máa wó o lulẹ̀ títí tí àwọn eniyan yóo fi máa pè wọ́n ní orílẹ̀-èdè burúkú, àwọn ẹni tí OLUWA bínú sí títí lae.”
5Ẹ óo fi ojú ara yín rí i ẹ óo sì sọ pé, “OLUWA tóbi lọ́ba, kódà títí dé ilẹ̀ tí kì í ṣe ilẹ̀ Israẹli!”#Ais 34:5-17; 63:1-6; Jer 49:7-22; Isi 25:12-14; 35:1-15; Amos 1:11-12; Ọbad 1-14
OLUWA Bá Àwọn Alufaa Wí
6“Ọmọ a máa bọ̀wọ̀ fún baba rẹ̀, iranṣẹ a sì máa bẹ̀rù oluwa rẹ̀. Bí mo bá jẹ́ baba yín, ṣé ẹ̀ ń bọ̀wọ̀ fún mi? Bí mo bá sì jẹ́ oluwa yín, ṣé ẹ bẹ̀rù mi ni èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun ń bi ẹ̀yin alufaa tí ẹ̀ ń tàbùkù orúkọ mi? Sibẹsibẹ ẹ̀ ń bèèrè pé, ‘Ọ̀nà wo ni a fi ń tàbùkù orúkọ rẹ?’ 7Ìdí rẹ̀ tí mo fi ní ẹ̀ ń tàbùkù orúkọ mi ni pé, ẹ̀ ń fi oúnjẹ àìmọ́ rúbọ lórí pẹpẹ mi. Ẹ tún bèèrè pé, ‘Ọ̀nà wo ni a fi sọ pẹpẹ rẹ di àìmọ́?’ Ẹ ti tàbùkù pẹpẹ mi, nípa rírò pé ẹ lè tàbùkù rẹ̀. 8Nígbà tí ẹ bá mú ẹran tí ó fọ́jú, tabi ẹran tí ó múkùn-ún, tabi ẹran tí ń ṣàìsàn wá rúbọ sí mi, ǹjẹ́ kò burú? Ṣé ẹ lè fún gomina ní irú rẹ̀ kí inú rẹ̀ dùn si yín, tabi kí ẹ rí ojurere rẹ̀?”#Diut 15:21
9Nisinsinyii, ẹ̀yin alufaa, ẹ mú irú ọrẹ bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́, ẹ̀ ń gbadura sí Ọlọrun, pé kí ó lè fi ojurere wò yín; Ṣé ẹ rò pé OLUWA yóo fi ojurere wo ẹnikẹ́ni ninu yín? 10Ìbá ti dára tó kí ẹnìkan ninu yín ti ìlẹ̀kùn tẹmpili pa, kí ẹ má baà máa wá tanná mọ́, kí ẹ máa rú ẹbọ asán lórí pẹpẹ mi! Inú mi kò dùn si yín, n kò sì ní gba ọrẹ tí ẹ mú wá. 11Nítorí pé, jákèjádò gbogbo ayé, láti ìlà oòrùn títí dé ìwọ̀ rẹ̀ ni orúkọ mi ti tóbi láàrin àwọn orílẹ̀-èdè, ibi gbogbo ni wọ́n sì ti ń sun turari sí mi, tí wọ́n sì ń rú ẹbọ mímọ́ sí mi láàrin àwọn orílẹ̀-èdè. 12Ṣugbọn ẹ tàbùkù orúkọ mi nígbà tí ẹ sọ pé pẹpẹ OLUWA ti di àìmọ́, tí ẹ sì ń fi oúnjẹ tí ẹ pẹ̀gàn rúbọ lórí rẹ̀. 13Ẹ̀ ń sọ pé, “Èyí sú wa!” Ẹ̀ ń yínmú sí mi. Ẹran tí ẹ fi ipá gbà, tabi èyí tí ó yarọ, tabi èyí tí ń ṣàìsàn ni ẹ̀ ń mú wá láti fi rúbọ. Ṣé ẹ rò pé n óo gba irú ẹbọ bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́ yín? 14Ègún ni fún arẹ́nijẹ; tí ó jẹ́jẹ̀ẹ́ akọ ẹran láti inú agbo rẹ̀, ṣugbọn tí ó fi ẹran tí ó ní àbùkù rúbọ sí OLUWA. Ọba ńlá ni mí, gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ni wọ́n sì bẹ̀rù orúkọ mi.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
MALAKI 1: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010