MALAKI 3

3
1OLUWA ní, “Wò ó! Mo rán òjíṣẹ́ mi ṣiwaju mi láti tún ọ̀nà ṣe fún mi. OLUWA tí ẹ sì ń retí yóo yọ lójijì sinu tẹmpili rẹ̀; iranṣẹ mi, tí ẹ sì tí ń retí pé kí ó wá kéde majẹmu mi, yóo wá.”#Mat 11:10; Mak 1:2; Luk 1:76; 7:27
2Ṣugbọn, ta ló lè farada ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ tí ó bá dé? Àwọn wo ni wọn yóo lè dúró ní ọjọ́ tí ó bá yọ?#Joẹl 2:11; Ifi 6:17
Nítorí pé ó dàbí iná alágbẹ̀dẹ tí ń yọ́ irin, ati bí ọṣẹ alágbàfọ̀ tí ń fọ nǹkan mọ́. 3Yóo jókòó bí ẹni tí ń yọ́ fadaka, yóo fọ àwọn ọmọ Lefi mọ́ bíi wúrà ati fadaka, títí tí wọn yóo fi mú ẹbọ tí ó tọ́ wá fún OLUWA. 4Inú OLUWA yóo wá dùn sí ẹbọ Juda ati ti Jerusalẹmu nígbà náà bíi ti àtẹ̀yìnwá.
5OLUWA ní, “N óo wá ba yín láti ṣe ìdájọ́; n óo wá jẹ́rìí mọ́ àwọn oṣó ati àwọn alágbèrè, àwọn tí wọn ń búra èké ati àwọn tí wọn kì í san owó ọ̀yà pé, àwọn tí wọn ń ni àwọn opó ati àwọn aláìníbaba lára, ati àwọn tí wọn ń ṣi àwọn àlejò lọ́nà, tí wọn kò sì bẹ̀rù mi.”
Sísan ìdámẹ́wàá
6OLUWA àwọn ọmọ ogun ní, “Nítorí pé èmi OLUWA kì í yipada, ni a kò fi tíì run ẹ̀yin ọmọ Jakọbu patapata.#Sir 48:10 7Láti ayé àwọn baba ńlá yín ni ẹ ti yapa kúrò ninu ìlànà mi, tí ẹ kò sì tẹ̀lé wọn mọ́. Ẹ̀yin ẹ yipada sí mi, èmi náà óo sì yipada si yín. 8Ṣugbọn ẹ̀ ń bèèrè pé, ‘Báwo ni a ti ṣe lè yipada?’ Ǹjẹ́ ó ṣeéṣe fún eniyan láti ja Ọlọrun lólè? Ṣugbọn ẹ̀ ń jà mí lólè. Ẹ sì ń bèèrè pé, ‘Ọ̀nà wo ni à ń gbà jà ọ́ lólè?’ Nípa ìdámẹ́wàá ati ọrẹ yín ni. 9Ègún wà lórí gbogbo yín nítorí pé gbogbo orílẹ̀-èdè yín ní ń jà mí lólè. 10Ẹ mú gbogbo ìdámẹ́wàá yín wá sí ilé ìṣúra, kí oúnjẹ baà lè wà ninu ilé mi. Ẹ ṣe bẹ́ẹ̀ kí ẹ fi dán mi wò, bí n kò bá ní ṣí fèrèsé ọ̀run sílẹ̀, kí n sì tú ibukun jáde fun yín lọpọlọpọ, tóbẹ́ẹ̀ tí kò ní sí ààyè tó láti gbà á.#Lef 27:30; Nọm 18:21-24; Diut 12:6; 14:22-29; Neh 13:12 11N kò ní jẹ́ kí kòkòrò ajẹnirun jẹ ohun ọ̀gbìn yín lóko, ọgbà àjàrà yín yóo sì so jìnwìnnì. 12Nígbà náà ni àwọn orílẹ̀-èdè yóo máa pè yín ní ẹni ibukun, ilẹ̀ yín yóo sì jẹ́ ilẹ̀ ayọ̀. Bẹ́ẹ̀ ni èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun wí!”
Ìlérí Àánú Tí Ọlọrun Ṣe
13OLUWA ní, “Ẹ ti fi ẹnu yín sọ ọ̀rọ̀ burúkú sí mi. Sibẹsibẹ ẹ̀ ń wí pé, ‘Irú ọ̀rọ̀ burúkú wo ni a sọ sí ọ?’ 14Ẹ sọ pé, ‘Kí eniyan máa sin Ọlọrun kò jámọ́ nǹkankan. Kò sì sí èrè ninu pípa òfin rẹ̀ mọ́ tabi ninu rírẹ ara wa sílẹ̀ níwájú OLUWA àwọn ọmọ ogun. 15Ohun tí ń ṣẹlẹ̀ nisinsinyii ni pé: ó ń dára fún àwọn agbéraga; kì í sì í ṣe pé ó ń dára fún àwọn eniyan burúkú nìkan, ṣugbọn nígbà tí wọ́n bá fi ìwà burúkú wọn dán Ọlọrun wò, kò sí nǹkankan tí ń ṣẹlẹ̀ sí wọn.’ ”
16Nígbà tí àwọn tí wọ́n bẹ̀rù OLUWA bá ń bá ara wọn sọ̀rọ̀, OLUWA a máa tẹ́tí sí wọn, yóo sì gbọ́ ọ̀rọ̀ wọn. Ó ní ìwé kan níwájú rẹ̀ ninu èyí tí àkọsílẹ̀ àwọn tí wọ́n bẹ̀rù OLUWA, tí wọ́n sì ń bọ̀wọ̀ fún orúkọ rẹ̀ wà. 17OLUWA àwọn ọmọ ogun ní, “Wọn yóo jẹ́ eniyan mi, ní ọjọ́ tí mo bá fi agbára mi hàn, wọn yóo jẹ́ ohun ìní mi pataki. N óo ṣàánú fún wọn bí baba tií ṣàánú fún ọmọ rẹ̀ tí ń sìn ín. 18Lẹ́ẹ̀kan sí i, ẹ óo tún rí ìyàtọ̀ láàrin àwọn eniyan rere tí wọn ń sin Ọlọrun, ati àwọn ẹni ibi tí wọn kì í sìn ín.”

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

MALAKI 3: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀