MATIU 26

26
Àwọn Juu dìtẹ̀ láti pa Jesu
(Mak 14:1-2; Luk 22:1-2; Joh 11:45-53)
1Nígbà tí Jesu parí gbogbo ọ̀rọ̀ wọnyi, ó sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, 2“Ẹ mọ̀ pé lẹ́yìn ọjọ́ meji ni Àjọ̀dún Ìrékọjá, a óo fi Ọmọ-Eniyan lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́ láti kàn mọ́ agbelebu.”#Eks 12:1-27
3Nígbà náà ni àwọn olórí alufaa ati àwọn àgbà ìlú péjọ sí àgbàlá Olórí Alufaa tí ó ń jẹ́ Kayafa. 4Wọ́n ń gbèrò ọ̀nà bí wọn yóo ti ṣe lè fi ẹ̀tàn mú Jesu kí wọ́n lè pa á. 5Ṣugbọn wọ́n ń sọ pé, “Kí á má ṣe é ní àkókò àjọ̀dún, bí bẹ́ẹ̀ kọ́ ìlú yóo dàrú.”
Obinrin kan Fi Òróró Kun Jesu ní Bẹtani
(Mak 14:3-9; Joh 12:1-8)
6Nígbà tí Jesu wà ní Bẹtani, ninu ilé Simoni tí ó dẹ́tẹ̀ nígbà kan rí, 7obinrin kan wọlé tọ̀ ọ́ wá tí ó ní ìgò òróró iyebíye olóòórùn dídùn, ni ó bá bẹ̀rẹ̀ sí tú u sí orí Jesu níbi tí ó ti ń jẹun.#Luk 7:37-38 8Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu rí i, inú bí wọn. Wọ́n ní, “Kí ni ìdí irú òfò báyìí? 9Nítorí títà ni à bá ta òróró yìí ní owó iyebíye tí à bá fi fún àwọn talaka.”
10Jesu mọ ohun tí wọn ń sọ, nítorí náà, ó wí fún wọn pé, “Kí ni ẹ̀ ń da obinrin yìí láàmú sí? Nítorí iṣẹ́ rere ni ó ṣe sí mi lára. 11Nígbà gbogbo ni ẹ ní àwọn talaka láàrin yín, ṣugbọn ẹ kò ní máa rí mi láàrin yín nígbà gbogbo.#Diut 15:11 12Nítorí nígbà tí obinrin yìí da òróró yìí sí mi lára, ó ṣe é fún ìsìnkú mi ni. 13Mò ń sọ fun yín dájúdájú, níbikíbi tí a bá ń waasu ìyìn rere ní gbogbo ayé, a óo máa sọ nǹkan tí obinrin yìí ṣe ní ìrántí rẹ̀.”
Judasi Gbà láti Fi Jesu fún Àwọn Ọ̀tá
(Mak 14:10-11; Luk 22:3-6)
14Nígbà náà ni ọ̀kan ninu àwọn mejila, tí ó ń jẹ́ Judasi Iskariotu, jáde lọ sọ́dọ̀ àwọn olórí alufaa. 15Ó bi wọ́n pé, “Kí ni ẹ óo fún mi bí mo bá fi Jesu le yín lọ́wọ́?” Wọ́n bá ka ọgbọ̀n owó fadaka fún un.#Sak 11:12. 16Láti ìgbà náà ni ó ti ń wá ọ̀nà láti fà á lé wọn lọ́wọ́.
Jesu Jẹ Àsè Ìrékọjá pẹlu Àwọn Ọmọ-ẹ̀yìn
(Mak 14:12-21; Luk 22:7-14, 21-23; Joh 13:21-30)
17Ní ọjọ́ kinni Àjọ̀dún Àìwúkàrà, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn wá sọ́dọ̀ Jesu, wọ́n bi í pé, “Níbo ni o fẹ́ kí á tọ́jú fún ọ láti jẹ àsè Ìrékọjá?”
18Ó bá dáhùn pé, “Ẹ lọ sí ọ̀dọ̀ ọkunrin kan báyìí nígboro kí ẹ sọ fún un pé, ‘Olùkọ́ni ní: Àkókò mi súnmọ́ tòsí; ní ilé rẹ ni èmi ati àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mi yóo ti jẹ àsè Ìrékọjá.’ ”
19Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn náà ṣe bí Jesu ti pàṣẹ fún wọn. Wọ́n sì tọ́jú gbogbo nǹkan fún àsè Ìrékọjá.
20Nígbà tí ó di ìrọ̀lẹ́, ó jókòó láti jẹun pẹlu àwọn mejila.
21Bí wọ́n ti ń jẹun, ó wí fún wọn pé, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé ọ̀kan ninu yín yóo fi mí fún àwọn ọ̀tá.”
22Ọkàn wọn dàrú pupọ; ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn ń bèèrè pé, “Kò sá lè jẹ́ èmi ni, Oluwa?”
23Ó dá wọn lóhùn pé, “Ẹni tí ó ń fi òkèlè run ọbẹ̀ ninu àwo kan náà pẹlu mi ni ẹni náà tí yóo fi mí fún àwọn ọ̀tá.#O. Daf 41:9 24Ọmọ-Eniyan ń lọ gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ nípa rẹ̀. Ṣugbọn ẹni tí ó fi Ọmọ-Eniyan lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́ gbé! Ìbá sàn fún un bí a kò bá bí i.”
25Nígbà náà ni Judasi, ẹni tí ó fi í fún àwọn ọ̀tá, bi í pé, “Àbí èmi ni, Olùkọ́ni?”
Jesu dá a lóhùn pé, “O ti fi ẹnu ara rẹ sọ ọ́.”
Oúnjẹ Alẹ́ Oluwa
(Mak 14:22-26; Luk 22:1-20; 1 Kọr 11:23-25)
26Nígbà tí wọn ń jẹun, Jesu mú burẹdi, ó gbadura sí i, ó bù ú, ó bá fi fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀; ó ní, “Ẹ gbà, ẹ jẹ ẹ́, èyí ni ara mi.”
27Nígbà tí ó mú ife, ó dúpẹ́, ó fi fún wọn, ó ní “Gbogbo yín ẹ mu ninu rẹ̀. 28Èyí ni ẹ̀jẹ̀ mi tí a fi dá majẹmu, ẹ̀jẹ̀ tí a ta sílẹ̀ fún ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ ọpọlọpọ eniyan.#a Eks 24:8; b Jer 31:31-34 29Mo sọ fun yín, n kò ní mu ọtí èso àjàrà mọ́ títí di ọjọ́ náà tí n óo mu ún pẹlu yín ní ọ̀tun ní ìjọba Baba mi.”
30Lẹ́yìn náà, wọ́n kọ orin kan, wọ́n bá jáde lọ sórí Òkè Olifi.
Jesu Sọtẹ́lẹ̀ pé Peteru Yóo Sẹ́ Òun
(Mak 14:27-31; Luk 22:31-34; Joh 13:36-38)
31Nígbà náà Jesu sọ fún wọn pé, “Gbogbo yín ni ẹ óo pada lẹ́yìn mi ní alẹ́ yìí, gẹ́gẹ́ bí ó ti wà ní àkọsílẹ̀ pé,
‘Ọwọ́ yóo tẹ olùṣọ́-aguntan,
gbogbo agbo aguntan ni a óo fọ́nká!’#Sak 13:7
32“Ṣugbọn lẹ́yìn tí a bá ti jí mi dìde, n óo ṣiwaju yín lọ sí Galili.”#Mat 28:16
33Peteru dá a lóhùn pé, “Bí gbogbo àwọn yòókù bá tilẹ̀ pada lẹ́yìn rẹ, bíi tèmi kọ́!”
34Jesu wí fún un pé, “Mo fẹ́ kí o mọ̀ dájúdájú pé ní alẹ́ yìí, kí àkùkọ tó kọ, ìwọ yóo sẹ́ mi ní ẹẹmẹta.”
35Peteru sọ fún un pé, “Bí mo bá tilẹ̀ níláti bá ọ kú, n kò ní sẹ́ ọ.”
Bákan náà ni gbogbo àwọn ọmọ-ẹ̀yìn yòókù sọ.
Adura Jesu ní Gẹtisemani
(Mak 14:32-42; Luk 22:39-46)
36Jesu ati àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ lọ sí ibìkan tí ó ń jẹ́ Gẹtisemani. Ó sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn pé, “Ẹ jókòó níhìn-ín, èmi ń lọ gbadura lọ́hùn-ún nì.” 37Ó bá mú Peteru ati àwọn ọmọ Sebede mejeeji lọ́wọ́, inú rẹ̀ bàjẹ́, ó sì dààmú. 38Ó wá sọ fún wọn pé, “Mo ní ìbànújẹ́ ọkàn tóbẹ́ẹ̀ tí mo fẹ́rẹ̀ kú. Ẹ dúró níhìn-ín kí ẹ máa bá mi ṣọ́nà.”
39Ó wá tún lọ siwaju díẹ̀ síi, ó dojúbolẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí gbadura pé, “Baba mi, bí ó bá ṣeéṣe, mú kí ife kíkorò yìí fò mí ru. Ṣugbọn kì í ṣe ohun tí mo fẹ́ ni ṣíṣe, bíkòṣe ohun tí ìwọ fẹ́.”
40Ó bá lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó bá wọn tí wọn ń sùn. Ó sọ fún Peteru pé, “Èyí ni pé ẹ kò lè bá mi ṣọ́nà fún wakati kan? 41Ẹ máa ṣọ́nà, kí ẹ máa gbadura, kí ẹ má baà bọ́ sinu ìdánwò. Ẹ̀mí fẹ́ ṣe é, ṣugbọn ara kò lágbára.”
42Ó tún lọ gbadura lẹẹkeji. Ó ní, “Baba mi, bí kò bá ṣeéṣe pé kí ife kíkorò yìí fò mí ru, tí ó jẹ́ ohun tí ó níláti ṣẹlẹ̀ sí mi, ìfẹ́ tìrẹ ni ṣíṣe.” 43Ó tún wá, ó tún bá àwọn ọmọ-ẹ̀yìn tí wọn ń sùn, nítorí oorun ń kùn wọ́n pupọ.
44Ó bá fi wọ́n sílẹ̀, ó pada lọ gbadura ní ẹẹkẹta; ó tún sọ nǹkankan náà. 45Lẹ́yìn náà ó wá lọ sọ́dọ̀ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó sọ fún wọn pé, “Ẹ tún wà níbi tí ẹ̀ ń sùn, tí ẹ̀ ń sinmi! Ẹ wò ó! Àkókò náà súnmọ́ tòsí tí a óo fi Ọmọ-Eniyan lé àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ lọ́wọ́. 46Ẹ dìde. Ẹ jẹ́ kí á máa lọ. Ẹni tí yóo fi mí fún àwọn ọ̀tá súnmọ́ tòsí.”
Judasi Fi Jesu fún Àwọn Ọ̀tá
(Mak 14:43-50; Luk 22:47-53; Joh 18:3-12)
47Bí Jesu ti ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, bẹ́ẹ̀ ni Judasi, ọ̀kan ninu àwọn mejila yọ, pẹlu ọ̀pọ̀ eniyan tí wọ́n mú idà ati kùmọ̀ lọ́wọ́. Wọ́n ń bọ̀ láti ọ̀dọ̀ àwọn olórí alufaa ati àwọn àgbà ìlú. 48Ẹni tí ó fi í fún àwọn ọ̀tá ti fi àmì fún wọn pé, “Ẹni tí mo bá kí, tí mo fi ẹnu kàn ní ẹ̀rẹ̀kẹ́ ni ẹni náà. Ẹ mú un.”
49Lẹsẹkẹsẹ bí ó ti dé ọ̀dọ̀ Jesu, ó ní, “Ẹ pẹ̀lẹ́ o, Olùkọ́ni.” Ni ó bá da ẹnu dé e ní ẹ̀rẹ̀kẹ́.
50Jesu sọ fún un pé, “Ọ̀rẹ́ kí ló dé o?”
Nígbà náà ni àwọn eniyan wá, wọ́n ṣùrù mọ́ Jesu, wọ́n mú un. 51Ọ̀kan ninu àwọn tí ó wà pẹlu Jesu bá na ọwọ́, ó fa idà yọ, ó sì fi ṣá ẹrú Olórí Alufaa kan, ó gé e létí. 52Ṣugbọn Jesu sọ fún un pé, “Ti idà rẹ bọ inú akọ rẹ̀ pada, nítorí gbogbo àwọn tí ó bá ń fa idà yọ, idà ni a óo fi pa wọ́n. 53Tabi o kò mọ̀ pé mo lè ké pe Baba mi, kí ó fún mi ní ẹgbaagbeje angẹli nisinsinyii? 54Ṣugbọn bí mo bá ṣe bẹ́ẹ̀ báwo ni Ìwé Mímọ́ yóo ti ṣe ṣẹ pé bẹ́ẹ̀ ni ó gbọdọ̀ rí?”
55Jesu bá sọ fún àwọn eniyan náà pé, “Ẹ jáde wá mú mi pẹlu idà ati kùmọ̀ bí ìgbà tí ẹ wá mú olè. Ojoojumọ ni mò ń jókòó ninu Tẹmpili láti kọ́ àwọn eniyan. Ẹ kò mú mi nígbà náà!#Luk 19:47; 21:37 56Ṣugbọn gbogbo èyí ṣẹlẹ̀ kí ọ̀rọ̀ àwọn wolii lè ṣẹ ni.”
Gbogbo àwọn ọmọ-ẹ̀yìn bá fi í sílẹ̀, wọ́n sálọ.
A Mú Jesu Lọ siwaju Ìgbìmọ̀
(Mak 14:53-65; Luk 22:54-55, 63-71; Joh 18:13-14, 19-24)
57Àwọn tí wọ́n mú Jesu fà á lọ sọ́dọ̀ Kayafa Olórí Alufaa, níbi tí àwọn amòfin ati àwọn àgbà ti pé jọ sí. 58Peteru ń tẹ̀lé Jesu, ó ń bọ̀ lẹ́yìn patapata, títí ó fi dé àgbàlá Olórí Alufaa. Ó wọlé, ó jókòó pẹlu àwọn ẹ̀ṣọ́ láti rí ibi tí gbogbo rẹ̀ yóo yọrí sí. 59Àwọn olórí alufaa ati gbogbo ìgbìmọ̀ ń wá ẹ̀rí èké tí ó lè kóbá Jesu kí wọn baà lè pa á. 60Ṣugbọn wọn kò rí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọpọlọpọ ni àwọn ẹlẹ́rìí-èké tí wọ́n yọjú. Ní ìgbẹ̀yìn àwọn meji kan wá. 61Wọ́n ní, “Ọkunrin yìí sọ pé, ‘Mo lè wó Tẹmpili Ọlọrun yìí, kí n sì tún un kọ́ ní ọjọ́ mẹta.’ ”#Joh 2:19
62Olórí Alufaa bá dìde, ó ní, “O kò fèsì rárá? Àbí o kò gbọ́ ohun tí wọ́n sọ pé o wí?” 63Ṣugbọn Jesu kò fọhùn. Olórí Alufaa wá sọ fún un pé, “Mo fi Ọlọrun alààyè bẹ̀ ọ́, sọ fún wa bí ìwọ ni Mesaya, Ọmọ Ọlọrun.”
64Jesu dá a lóhùn pé, “Ẹnu ara rẹ ni o fi sọ ọ́; ṣugbọn mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ pé láti ìsinsìnyìí lọ, ẹ óo rí Ọmọ-Eniyan tí ó jókòó lórí ìtẹ́ pẹlu agbára Ọlọrun, tí ìkùukùu yóo sì máa gbé e bọ̀ wá.”#Dan 7:13
65Olórí Alufaa bá fa aṣọ rẹ̀ ya, ó ní, “O sọ̀rọ̀ àfojúdi sí Ọlọrun. Ẹlẹ́rìí wo ni a tún ń wá? Ẹ ti gbọ́ ọ̀rọ̀ àfojúdi tí ó sọ sí Ọlọrun nisinsinyii. 66Kí ni ẹ rò?”
Wọ́n dáhùn pé, “Ikú ni ó tọ́ sí i.”#Lef 24:16
67Wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí tutọ́ sí i lójú, wọ́n ń sọ ọ́ lẹ́ṣẹ̀ẹ́, wọ́n ń gbá a létí.#Ais 50:6 68Wọ́n ń sọ pé, “Ìwọ, Mesaya, sọ ẹni tí ó lù ọ́ fún wa!”
Peteru Sẹ́ Jesu
(Mak 14:66-72; Luk 22:56-62; Joh 18:15-18, 25-27)
69Peteru jókòó lóde ní àgbàlá. Ọ̀kan ninu àwọn iranṣẹbinrin wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó ní, “Ìwọ náà wà pẹlu Jesu ará Galili.”
70Ṣugbọn Peteru sẹ́ níwájú gbogbo wọn, ó ní, “N kò mọ ohun tí ò ń sọ.” 71Bí ó ti ń lọ sí ẹnu ọ̀nà, iranṣẹbinrin mìíràn tún rí i, ó bá sọ fún àwọn tí ó wà níbẹ̀ pé, “Ọkunrin yìí wà pẹlu Jesu ará Nasarẹti.”
72Peteru tún sẹ́, ó búra pé, “N kò mọ ọkunrin náà.”
73Ó ṣe díẹ̀ si, àwọn tí ó dúró níbẹ̀ tọ Peteru lọ, wọ́n sọ fún un pé, “Òtítọ́ ni pé ọ̀kan ninu wọn ni ìwọ náà í ṣe nítorí ọ̀rọ̀ rẹ fihàn bẹ́ẹ̀!”
74Nígbà náà ni Peteru bẹ̀rẹ̀ sí ṣépè, ó tún ń búra pé, “N kò mọ ọkunrin náà.”
Lẹsẹkẹsẹ àkùkọ kọ. 75Peteru wá ranti ọ̀rọ̀ tí Jesu sọ, pé, “Kí àkùkọ tó kọ, ìwọ yóo sẹ́ mi ní ẹẹmẹta.” Ó bá bọ́ sóde, ó sọkún gidigidi.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

MATIU 26: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀