MATIU 27

27
Wọ́n fa Jesu lọ sọ́dọ̀ Pilatu
(Mak 15:1; Luk 23:1-2; Joh 18:28-32)
1Nígbà tí ilẹ̀ mọ́, gbogbo àwọn olórí alufaa ati àwọn àgbà ìlú jọ forí-korí nípa ọ̀ràn Jesu, kí wọ́n lè pa á. 2Wọ́n dè é, wọ́n bá fà á lọ láti fi lé Pilatu, gomina, lọ́wọ́.
Ikú Judasi
(A. Apo 1:18-19)
3Nígbà tí Judasi, ẹni tí ó fi Jesu fún àwọn ọ̀tá rí i pé a dá Jesu lẹ́bi, ó ronupiwada. Ó bá lọ dá ọgbọ̀n owó fadaka pada fún àwọn olórí alufaa ati àwọn àgbà. 4Ó ní, “Mo ṣẹ̀ ní ti pé mo ṣe ikú pa aláìṣẹ̀.”
Wọ́n bá dá a lóhùn pé, “Èwo ló kàn wá ninu rẹ̀? Ẹjọ́ tìrẹ ni.”
5Judasi bá da owó náà sílẹ̀ ninu Tẹmpili, ó jáde, ó bá lọ pokùnso.
6Àwọn olórí alufaa mú owó fadaka náà, wọ́n ní, “Kò tọ́ fún wa láti fi í sinu àpò ìṣúra Tẹmpili mọ́ nítorí owó ẹ̀jẹ̀ ni.” 7Lẹ́yìn tí wọ́n ti forí-korí, wọ́n fi owó náà ra ilẹ̀ amọ̀kòkò fún ìsìnkú àwọn àlejò. 8Ìdí nìyí ti a fi ń pe ilẹ̀ náà ní, “Ilẹ̀ ẹ̀jẹ̀” títí di òní olónìí.#A. Apo 1:18-19
9Báyìí ni ohun tí wolii Jeremaya, wí ṣẹ, nígbà tí ó sọ pé, “Wọ́n mú ọgbọ̀n owó fadaka náà, iye tí a dá lé orí ẹ̀mí náà, nítorí iye tí àwọn ọmọ Israẹli ń dá lé eniyan lórí nìyí, 10wọ́n lo owó náà fún ilẹ̀ amọ̀kòkò, gẹ́gẹ́ bí Oluwa ti pàṣẹ fún mi.”#Sak 11:12-13
Pilatu Fi Ọ̀rọ̀ Wá Jesu Lẹ́nu Wò
(Mak 15:2-5; Luk 23:3-5; Joh 18:33-38)
11Jesu bá dúró siwaju gomina. Gomina bi í pé, “Ìwọ ni ọba àwọn Juu bí?”
Jesu ní, “O ti fi ẹnu ara rẹ sọ ọ́.” 12Ṣugbọn bí àwọn olórí alufaa ati àwọn àgbà ti ń fi ẹ̀sùn kàn án tó, kò fèsì rárá. 13Nígbà náà ni Pilatu sọ fún un pé, “O kò gbọ́ irú ẹ̀sùn tí wọn ń fi kàn ọ́ ni?”
14Ṣugbọn Jesu kò dá a lóhùn gbolohun kan ṣoṣo, tí ó fi jẹ́ pé ẹnu ya gomina pupọ.
A Dá Jesu Lẹ́bi Ikú
(Mak 15:6-15; Luk 23:13-25; Joh 18:39–19:16)
15Gẹ́gẹ́ bí àṣà, ní àkókò àjọ̀dún, gomina a máa dá ẹlẹ́wọ̀n kan sílẹ̀ fún àwọn eniyan, ẹnikẹ́ni tí wọn bá fẹ́. 16Ní àkókó náà, ẹlẹ́wọ̀n olókìkí kan wà tí ó ń jẹ́ Jesu Baraba.#27:16 Dípò Jesu Baraba ọpọlọpọ ninu àwọn Bibeli àtijọ́ pè é ní Baraba. 17Nígbà tí àwọn Juu pésẹ̀, Pilatu bi wọ́n pé, “Ta ni kí n dá sílẹ̀ fun yín, Jesu Baraba ni tabi Jesu tí ó ń jẹ́ Mesaya?” 18Pilatu ti mọ̀ pé nítorí ìlara ni wọ́n fi mú un wá sọ́dọ̀ òun.
19Nígbà tí Pilatu jókòó lórí pèpéle ìdájọ́, iyawo rẹ̀ ranṣẹ sí i, ó ní, “Má ṣe lọ́wọ́ ninu ọ̀ràn ọkunrin olódodo yìí. Nítorí pé mọ́jú òní, ojú mi rí nǹkan lójú àlá nípa rẹ̀.”
20Àwọn olórí alufaa ati àwọn àgbà ti rọ àwọn eniyan láti bèèrè fún Baraba, kí wọ́n pa Jesu. 21Gomina bi wọ́n pé, “Ta ni ninu àwọn meji yìí ni ẹ fẹ́ kí n dá sílẹ̀ fun yín?”
Wọ́n sọ pé, “Baraba ni.”
22Pilatu wá bi wọ́n pé, “Kí ni ẹ fẹ́ kí n ṣe sí Jesu tí ó ń jẹ́ Mesaya?”
Gbogbo wọn dáhùn pé, “Kàn án mọ́ agbelebu.”
23Pilatu bi wọ́n pé, “Ohun burúkú wo ni ó ṣe?”
Ṣugbọn wọ́n túbọ̀ kígbe pé, “Kàn án mọ́ agbelebu.”
24Nígbà tí Pilatu rí i pé òun kò lè yí wọn lọ́kàn pada, ati pé rògbòdìyàn fẹ́ bẹ́ sílẹ̀, ó mú omi, ó fọ ọwọ́ rẹ̀ níwájú wọn. Ó ní, “N kò lọ́wọ́ ninu ikú ọkunrin yìí. Ẹ̀yin ni kí ẹ mójútó ọ̀ràn náà.”#Diut 21:6-9
25Gbogbo àwọn eniyan náà dáhùn pé, “Kí ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ wà lórí àwa ati àwọn ọmọ wa!”
26Pilatu bá dá Baraba sílẹ̀ fún wọn. Lẹ́yìn tí ó ti pàṣẹ pé kí wọ́n na Jesu ní pàṣán, ó fi í lé wọn lọ́wọ́ láti kàn mọ̀ agbelebu.
Àwọn Ọmọ-ogun fi Jesu Ṣẹ̀sín
(Mak 15:16-20; Joh 19:2-3)
27Àwọn ọmọ-ogun gomina bá mú Jesu lọ sí ibùdó wọn, gbogbo wọn bá péjọ lé e lórí. 28Wọ́n bọ́ ẹ̀wù rẹ̀, wọ́n wá fi aṣọ àlàárì bò ó lára. 29Wọ́n fi ẹ̀gún hun adé, wọ́n fi dé e lórí. Wọ́n fi ọ̀pá sí ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀. Wọ́n wá ń kúnlẹ̀ níwájú rẹ̀, wọ́n ń fi ṣe yẹ̀yẹ́; wọ́n ń wí pé, “Kabiyesi, ọba àwọn Juu.” 30Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń tutọ́ sí i lára. Wọ́n mú ọ̀pá, wọ́n ń kán an mọ́ ọn lórí. 31Nígbà tí wọn ti fi ṣe ẹlẹ́yà tẹ́rùn, wọ́n bọ́ aṣọ àlàárì náà kúrò lára rẹ̀, wọ́n fi tirẹ̀ wọ̀ ọ́. Wọ́n bá mú un lọ láti kàn án mọ́ agbelebu.
A Kan Jesu Mọ́ Agbelebu
(Mak 15:21-32; Luk 23:26-43; Joh 19:17-27)
32Nígbà tí wọn ń jáde lọ, wọ́n rí ọkunrin kan ará Kirene tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Simoni. Wọ́n bá fi ipá mú un láti ru agbelebu Jesu. 33Nígbà tí wọ́n dé ibi tí wọn ń pè ní Gọlgọta (ìtumọ̀ èyí tíí ṣe “Ibi Agbárí”), 34wọ́n fún un ní ọtí kíkorò mu. Nígbà tí ó tọ́ ọ wò, ó kọ̀, kò mu ún.#O. Daf 69:21
35Nígbà tí wọ́n kàn án mọ́ agbelebu tán, wọ́n pín aṣọ rẹ̀ mọ́ ara wọn lọ́wọ́, wọ́n ṣẹ́ gègé láti mọ èyí tí yóo kan ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn.#O. Daf 22:18 36Wọ́n bá jókòó níbẹ̀, wọ́n ń ṣọ́ ọ. 37Wọ́n fi àkọlé kan kọ́ sí òkè orí rẹ̀, wọ́n kọ ẹ̀sùn tí a fi kàn án sibẹ pé, “Eléyìí ni Jesu ọba àwọn Juu.” 38Wọ́n tún kan àwọn ọlọ́ṣà meji mọ́ agbelebu pẹlu rẹ̀, ọ̀kan ní ọwọ́ ọ̀tún, ekeji ní ọwọ́ òsì rẹ̀.
39Àwọn tí ó ń kọjá lọ ń sọ ìsọkúsọ sí i. Wọ́n ń já apá mọ́nú,#O. Daf 22:7; 109:25; Sir 12:17-18; 13:7 40wọ́n ń sọ pé, “Ìwọ tí yóo wó Tẹmpili, tí yóo tún un kọ́ ní ọjọ́ mẹta, gba ara rẹ là. Bí Ọmọ Ọlọrun bá ni ọ́, sọ̀kalẹ̀ kúrò lórí agbelebu.”#Mat 26:61; Joh 2:19
41Bákan náà ni àwọn olórí alufaa ati àwọn amòfin ati àwọn àgbà, àwọn náà ń fi í ṣe ẹlẹ́yà. Wọ́n ń sọ pé, 42“Àwọn ẹlòmíràn ni ó rí gbà là, kò lè gba ara rẹ̀ là. Ṣé ọba Israẹli ni! Kí ó sọ̀kalẹ̀ nisinsinyii láti orí agbelebu, a óo gbà á gbọ́. 43Ṣé ó gbẹ́kẹ̀lé Ọlọrun ni! Kí Ọlọrun gbà á sílẹ̀ nisinsinyii bí ó bá fẹ́ ẹ! Ṣebí ó sọ pé ọmọ Ọlọrun ni òun.”#O. Daf 22:8; Ọgb 2:18-20
44Bákan náà ni àwọn ọlọ́ṣà tí wọ́n kàn mọ́ agbelebu pẹlu rẹ̀ fi ń ṣe ẹlẹ́yà.
Ikú Jesu
(Mak 15:33-41; Luk 23:44-49; Joh 19:28-30)
45Láti agogo mejila ọ̀sán ni òkùnkùn ti bo gbogbo ilẹ̀ títí di agogo mẹta ọ̀sán. 46Nígbà tí ó tó nǹkan bí agogo mẹta ọ̀sán, Jesu kígbe ní ohùn rara pé, “Eli, Eli, lema sabakitani?” Ìtumọ̀ èyí ni, “Ọlọrun mi! Ọlọrun mi! Kí ló dé tí o fi kọ̀ mí sílẹ̀?”#O. Daf 22:1
47Nígbà tí àwọn kan tí ó dúró níbẹ̀ gbọ́, wọ́n ní, “Ọkunrin yìí ń pe Elija.” 48Lẹsẹkẹsẹ ọ̀kan ninu wọn sáré, ó ti nǹkankan bíi kànìnkànìn bọ inú ọtí kíkan, ó fi sórí ọ̀pá láti fi fún un mu.#O. Daf 69:21
49Ṣugbọn àwọn yòókù ń sọ pé, “Fi í sílẹ̀! Jẹ́ kí a wò bí Elija yóo wá gbà á là.”
50Jesu bá tún kígbe tòò, ó mí kanlẹ̀, ó bá dákẹ́.
51Aṣọ ìkélé tí ó wà ninu Tẹmpili ya sí meji láti òkè dé ilẹ̀. Ilẹ̀ mì tìtì. Àwọn òkè sán.#Eks 26:31-33 52Òkúta ẹnu ibojì ṣí, a sì jí ọ̀pọ̀ òkú àwọn olódodo dìde. 53Wọ́n jáde kúrò ninu ibojì lẹ́yìn tí Jesu ti jí dìde, wọ́n wọ Jerusalẹmu lọ, ọpọlọpọ eniyan ni ó rí wọn.
54Nígbà tí ọ̀gágun ati àwọn tí ó wà pẹlu rẹ̀ tí wọn ń ṣọ́ Jesu rí ilẹ̀ tí ó mì ati gbogbo ohun tí ó ṣẹlẹ̀, ẹ̀rù bà wọ́n pupọ. Wọ́n ní, “Nítòótọ́ Ọmọ Ọlọrun ni ọkunrin yìí.”
55Ọ̀pọ̀ àwọn obinrin wà níbẹ̀ tí wọ́n dúró ní òkèèrè réré, tí wọn ń wo ohun tí ó ṣẹlẹ̀. Àwọn ni wọ́n tí ń tẹ̀lé Jesu láti Galili, tí wọn ń ṣe iranṣẹ fún un. 56Maria Magidaleni wà lára wọn, ati Maria ìyá Jakọbu ati ti Josẹfu ati ìyá àwọn ọmọ Sebede.#Luk 8:2-3
Ìsìnkú Jesu
(Mak 15:42-47; Luk 23:50-56; Joh 19:38-42)
57Nígbà tí ó di ìrọ̀lẹ́, ọkunrin ọlọ́rọ̀ kan, ará Arimatia tí ó ń jẹ́ Josẹfu wá. Òun náà jẹ́ ọmọ-ẹ̀yìn Jesu. 58Ó tọ Pilatu lọ láti bèèrè òkú Jesu. Pilatu bá pàṣẹ pé kí wọ́n fún un. 59Nígbà tí Josẹfu ti gba òkú náà, ó fi aṣọ funfun tí ó mọ́ wé e. 60Ó tẹ́ ẹ sí inú ibojì rẹ̀ titun tí òun tìkalárarẹ̀ ti gbẹ́ sí inú àpáta. Ó yí òkúta ńlá kan dí ẹnu ọ̀nà ibojì náà. Ó bá kúrò níbẹ̀. 61Maria Magidaleni ati Maria keji wà níbẹ̀, wọ́n jókòó ní iwájú ibojì náà.
A Fi Àwọn Ọmọ-ogun Ṣọ́ Ibojì Jesu
62Ní ọjọ́ keji, ọjọ́ tí ó tẹ̀lé ọjọ́ ìpalẹ̀mọ́ àjọ̀dún, àwọn olórí alufaa ati àwọn Farisi wá sọ́dọ̀ Pilatu. 63Wọ́n ní, “Alàgbà, a ranti pé ẹlẹ́tàn nì sọ nígbà tí ó wà láàyè pé lẹ́yìn ọjọ́ mẹta òun óo jí dìde.#Mat 16:21; 17:23; 20:19; Mak 8:31; 9:31; 10:33-34; Luk 9:22; 18:31-33 64Nítorí náà, pàṣẹ kí wọ́n ṣọ́ ibojì náà títí di ọjọ́ kẹta. Bí a kò bá ṣe bẹ́ẹ̀, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ lè wá jí òkú rẹ̀ lọ, wọn yóo wá wí fún àwọn eniyan pé, ‘Ó ti jinde kúrò ninu òkú.’ Ìtànjẹ ẹẹkeji yóo wá burú ju ti àkọ́kọ́ lọ.”
65Pilatu bá dá wọn lóhùn pé, “Ṣebí ẹ ní olùṣọ́. Ẹ lọ fi wọ́n ṣọ́ ibojì náà bí ó ti tọ́ lójú yín.”
66Wọ́n bá lọ, wọ́n sé ẹnu ibojì náà, wọ́n fi èdìdì sí ara òkúta tí wọ́n gbé dí i. Wọ́n sì fi àwọn olùṣọ́ sibẹ pẹlu.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

MATIU 27: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀